Ìwé Sáàmù 97:1-12 BYB2014 - Bible AI

1OLÚWA jọba, jẹ́ kí ayé kí o yọ̀ jẹ́ kí inú ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù kí ó dùn

2Ojú ọ̀run àti òkùnkùn yí ká òdodo àti ìdájọ́ ni ó ṣe ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìtẹ́ Rẹ̀.

3Iná ń jó níwájú Rẹ̀. O sì ń jó àwọn ọ̀ta Rẹ̀ yíká kiri

4Ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀ tàn ó sí kárí ayé ayé rí i ó sì wárìrì

5Òkè gíga yọ́ gẹ́gẹ́ bí ìda níwájú OLÚWA, níwájú OLÚWA gbogbo ayé.

6Àwọn ọ̀run ròyìn òdodo Rẹ̀, gbogbo ènìyàn sì rí ògo Rẹ̀.

6

7ⓐ Gbogbo àwọn tí ń sin òrìṣà ni ojú yóò ti, àwọn ti n fi ère ṣe àfẹ́rí ara wọn Ẹsìn ín, ẹ̀yin òrìṣà;

8Síónì gbọ́, inú Rẹ̀ sì dùn ìnú àwọn ilé Júdà sì dùn Nítorí ìdájọ́ Rẹ, OLÚWA

9Nítorí pé ìwọ, OLÚWA, ní ó ga ju gbogbo ayé lọ ìwọ ni ó ga ju gbogbo òrìsà lọ.

9

10Jẹ kí gbogbo àwọn tí ó fẹ́ OLÚWA, kórira ibi, ó pa ọkan àwọn ènìyàn mímọ́ Rẹ̀ mọ́ ó gbà wọ́n ní ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú.

11Ìmọ́lẹ̀ tàn sórí àwọn olódodo àti ayọ̀ nínú àlàyé ọkàn

12Ẹ yọ̀ nínú OLÚWA, ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ olódodo, kí ẹ sì yin orúkọ Rẹ̀ mímọ́.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>