Ìwé Sáàmù 98:1-9 BYB2014 - Bible AI

1Ẹ kọrin túntún sí OLÚWA, nítorí tí ó ṣe ohun ìyanu; ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ àti apa mímọ́ Rẹ̀ o ṣe iṣẹ́ ìgbàlà fún un

2OLÚWA ti sọ ìgbàlà Rẹ̀ di mímọ̀ o fí òdodo Rẹ̀ han àwọn orílẹ̀ èdè.

3Ó rántí ìfẹ́ Rẹ̀ àti òtítọ́ Rẹ̀ fún àwọn ará ilé Ísírẹ́lì; gbogbo òpin ayé ni ó ti rí iṣẹ́ ìgbàlà Ọlọ́run wa.

3

4Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí OLÚWA, gbogbo ayé, ẹ bu sáyọ̀, ẹ kọrin ìyìn

5Ẹ fi dùùrù kọrin sí OLÚWA, pẹ̀lú dùùrù àti ìró ohùn orin mímọ́,

6Pẹ̀lú ìpè àti fèrè ẹ hó fún ayọ̀ níwájú OLÚWA Ọba.

6

7Jẹ́ kí òkun kí o hó pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó wà nínú Rẹ̀, Gbogbo ayé àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú Rẹ̀.

8Ẹ jẹ́ kí odo kí ó sápẹ́, ẹ jẹ́ kí òkè kí o kọrin pẹ̀lú ayọ̀;

9Ẹ jẹ́ kí wọn kọrin níwájú OLÚWA Nítorí tí yóò wá ṣè dájọ́ ayé bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè nínú òdodo àti àwọn ènìyàn ní àìṣègbè pẹ̀lú.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
>