1OLÚWA jọba; jẹ́ kí ayé kí ó wárìrì o jòkòó lórí ìtẹ́ kérúbù jẹ́ kí ayé kí ó wárìrì.
2OLÚWA tóbi ní Síónì; o sì ga jù gbogbo orílẹ̀ èdè lọ.
3Kí wọ́n sì yín orúkọ Rẹ̀ tí ó tóbi tí ó ni ẹ̀rù, Mímọ́ ni òun.
3
4OLÚWA tóbi lọba, ó fẹ́ òdodo ó dá ìdọ́gba sílẹ̀; ìwọ ṣe ohun tí ó tọ́ àti ohun tí o yẹ nínú Jákọ́bù.
5Gbígbé ga ní OLÚWA Ọlọ́run wa ẹ foríbalẹ̀ níbi ẹṣẹ̀ Rẹ̀; ó jẹ́ mímọ́.
6Mósè àti Árónì wà nínú àwọn àlùfáà Rẹ̀ Sámúẹ́lì wà nínú àwọn tí ó ń ké pe orúkọ Rẹ̀ wọ́n képe OLÚWA, ó sì dá wọn lóhùn.
6
7Ó sọ̀rọ̀ sí wọn nínú ọ̀wọ́n àwọsánmọ̀, wọ́n pa ẹrí Rẹ̀ mọ́ àti ìlànà tí ó fún wọn.
7
8OLÚWA Ọlọ́run wa, ó dá wọn lóhùn; ó jẹ́ Ọlọ́run tí ó ń dáríjìn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìwọ tí ó ń fi ìyà àìṣedédé wọn jẹ wọ́n
9Gbígbé ga ni OLÚWA Ọlọ́run wa kí a sìn ín ní òkè mímọ́ Rẹ̀ nítorí OLÚWA Ọlọ́run wa jẹ́ mímọ́.