Ìwé Sámúẹ́lì Kìn-ín-ní 15:1-35 BYB2014 - Bible AI

1Sámúẹ́lì wí fún Ṣọ́ọ̀lù pé, “Èmi ni OLÚWA rán láti fi àmì òróró yàn ọ́ ní ọba lórí àwọn ènìyàn rẹ̀ Ísírẹ́lì; fetí sílẹ̀ láti gbọ́ Iṣẹ́ tí OLÚWA rán mi sí ọ́.

2Èyí ni ohun tí OLÚWA alágbára wí: Èmi yóò jẹ àwọn Ámálékì níyà fún ohun tí wọ́n ti ṣe sí Ísírẹ́lì nígbà tí wọn dè wọn lọ́nà nígbà tí wọn ń bọ̀ láti Éjíbítì.

3Lọ nísinsìn yìí, kí o sì kọlu Ámálékì, kí o sì pa gbogbo ohun tí ó bá jẹ́ ti wọn ní àparun. Má ṣe dá wọn sí, pa ọkùnrin àti obìnrin wọn, ọmọ kékeré àti ọmọ ọmú, màlúù àti àgùntàn, ìbákasẹ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn.”

4Bẹ́ẹ̀ ni Ṣọ́ọ̀lù kó àwọn ènìyàn jọ, ó sì ka iye wọn ní Táláémù, wọ́n sì jẹ́ ogún ọ̀kẹ́ (200,000) àwọn ológun ẹlẹ́ṣẹ̀, pẹ̀lú ẹgbàárún àwọn ọkùnrin Júdà (10,000).

5Ṣọ́ọ̀lù sì lọ sí ìlú Ámálékì ó sì gọ dè wọ́n ní àfonífojì kan.

6Nígbà náà ni ó wí fún àwọn Kénáítì pé, “Ẹ lọ, kúrò ní Ámálékì kí èmi má ba à run yín pẹ̀lú wọn; nítorí ẹ̀yin fi àánú hàn fún gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n gòkè ti Éjíbítì wá.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn Kénáítì lọ kúrò láàrin àwọn Ámálékì.

7Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù kọlu àwọn Ámálékì láti Háfílà dé Súrì, tí ó fi dé ìlà oòrùn Éjíbítì.

8Ó sì mú Ágágì ọba Ámálékì láàyè, ó sì fi idà rẹ̀ kọlu gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀.

9Ṣùgbọ́n Ṣọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ dá Ágágì sí àti èyí tí ó dára jùlọ nínú àgùntàn àti màlúù àti ọ̀dọ́ àgùntàn àbọ́pa àti gbogbo nǹkan tó dára. Wọ́n kò sì fẹ́ pa àwọn wọ̀nyí run pátapáta ṣùgbọ́n gbogbo nǹkan tí kò dára tí kò sì ní láárí ni wọ́n parun pátapáta.

10Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ Sámúẹ́lì wá pé:

11“Èmi káànú gidigidi pé mo fi Ṣọ́ọ̀lù jọba, nítorí pé ó ti yípadà kúrò lẹ́yìn mi, kò sì pa ọ̀rọ̀ mi mọ́.” Inú Sámúẹ́lì sì bàjẹ́ gidigidi, ó sì képe OLÚWA ní gbogbo òru náà.

12Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù Sámúẹ́lì sì dìde láti lọ pàdé Ṣọ́ọ̀lù, ṣùgbọ́n wọ́n sọ fún un pé, “Ṣọ́ọ̀lù ti wá sí Kámẹ́lì. Ó ti kọ́ ibìkan fún ara rẹ̀ níbẹ̀, ó sì ti yípadà, ó sì ti sọ̀kalẹ̀ lọ sí Gílígálì.”

13Nígbà tí Sámúẹ́lì sì dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, Ṣọ́ọ̀lù sì wí fún un pé, “OLÚWA bùkún fún ọ, mo ti ṣe ohun tí OLÚWA pa láṣẹ.”

14Ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì wí pé, “Èwo wá ni igbe àgùntàn tí mo ń gbọ́ ní etí mi? Kí ni igbe màlúù ti mo ń gbọ́ yìí?”

15Ṣọ́ọ̀lù sì dáhùn pé, “Àwọn ọmọ ogun ní o mú wọn láti Ámálékì wá, wọ́n dá àwọn àgùntàn, àti màlúù tí ó dára jùlọ sí láti fi rúbọ sí OLÚWA Ọlọ́run rẹ, ṣùgbọ́n a pa àwọn tó kù run pátapáta.”

16Sámúẹ́lì sí wí fún Ṣọ́ọ̀lù pé, “Dákẹ́ ná, jẹ́ kí èmi kí ó sọ ohun tí OLÚWA wí fún mi ní alẹ́ àná fún ọ.” Sọ́ọ̀lù sì wí pé, “Sọ fún mi.”

17Sámúẹ́lì sì wí pé, “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ fi ìgbà kan kéré lójú ara rẹ, ǹjẹ́ ìwọ kò ha di olórí ẹ̀yà Ísírẹ́lì? OLÚWA fi àmì òróró yàn ọ́ ní ọba lórí Ísírẹ́lì.

18Ó sì rán ọ níṣẹ́ wí pé, ‘Lọ, kí o sì pa àwọn ènìyàn búburú ará Ámálékì run pátapáta; gbógun tì wọ́n títí ìwọ yóò fi run wọ́n.’

19Èéṣe tí ìwọ kò fi gbọ́ ti OLÚWA? Èéṣe tí ìwọ fi sáré sí ìkógun tí o sì ṣe búburú níwájú OLÚWA?”

20Ṣọ́ọ̀lù sì wí fún Sámúẹ́lì pé, “Ṣùgbọ́n èmi ti ṣe ìgbọ́rán sí OLÚWA, èmi sì ti lọ ní ọ̀nà tí OLÚWA rán mi. Mo sì ti pa àwọn ará Ámálékì run pátapáta, mo sì ti mú Ágágì ọba wọn padà wá.

21Àwọn ọmọ ogun ti mú àgùntàn àti màlúù lára ìkógùn èyí tí ó dára láti fi fún OLÚWA láti fi rúbọ sí OLÚWA Ọlọ́run rẹ ní Gílígálì.”

22ⓐ Ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì dáhùn pé, “Ǹjẹ́ OLÚWA ní inú dídùn sí ọrẹ sísun àti ẹbọ ju kí a ṣe ohun tí OLÚWA wí? Ìgbọ́ràn sàn ju ẹbọ lọ, ìfetísílẹ̀ sì sàn ju ọ̀rá àgbò lọ.

23Nítorí pé ìṣọ̀tẹ̀ dàbí ẹ̀ṣẹ̀ àfọ̀ṣẹ, àti ìgbéraga bí ẹ̀ṣẹ̀ ìbọ̀rìṣà. Nítorí tí ìwọ ti kọ ọ̀rọ̀ OLÚWA, Òun sì ti kọ̀ ọ́ ní ọba.”

24Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù wí fún Sámúẹ́lì pé, “Èmi ti ṣẹ̀. Mo ti rú òfin OLÚWA àti ọ̀rọ̀ rẹ̀. Èmi sì bẹ̀rù àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ni èmi sì gba ohùn wọn gbọ́.

25Mo bẹ̀ ọ́ nísinsìn yìí, dárí ẹ̀ṣẹ̀ mi jìn, kí ó sì yípadà pẹ̀lú mi, kí èmi kí ó lè sin OLÚWA.”

26Ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì wí fún un pé, “Èmi kò ní bá ọ padà. Ìwọ ti kọ ọ̀rọ̀ OLÚWA sílẹ̀, OLÚWA sì ti kọ̀ ọ́ ní ọba lórí Ísírẹ́lì!”

27Bí Sámúẹ́lì sì ti fẹ́ yípadà láti lọ, Ṣọ́ọ̀lù sì di ẹ̀wù ìlekè rẹ̀ mú, ó sì fàya;

28Sámúẹ́lì sì wí fún un pé, “OLÚWA ti fa ìjọba Ísírẹ́lì ya kúrò lọ́wọ́ ọ̀ rẹ lónìí, ó sì ti fi fún aládùúgbò rẹ kan tí ó sàn jù ọ́ lọ.

29Ẹni tí ó ń ṣe ògo Ísírẹ́lì, kì í purọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì í yí ọkàn rẹ̀ padà; nítorí kì í ṣe ènìyàn tí yóò yí ọkàn rẹ̀ padà.”

30Ṣọ́ọ̀lù sì wí pé, “Èmi ti ṣẹ̀, ṣùgbọ́n jọ̀wọ́ bu ọlá fún mi níwájú àwọn àgbààgbà ènìyàn mi, àti níwájú u Ísírẹ́lì, yípadà pẹ̀lú mi, kí èmi kí ó lè tẹríba fún OLÚWA Ọlọ́run rẹ.”

31Bẹ́ẹ̀ ni Sámúẹ́lì sì yípadà pẹ̀lú Ṣọ́ọ̀lù, Ṣọ́ọ̀lù sì sin OLÚWA.

32Nígbà náà ni Sámúẹ́lì wí pé, “Mú Ágágì ọba àwọn ará Ámálékì wá fún mi.” Ágágì sì tọ̀ ọ́ wá ní ìgboyà pẹ̀lú èrò pé, “Nítòótọ́ ìkorò ikú ti kọjá.”

33Ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì wí pé, “Bí idà rẹ ti sọ àwọn obìnrin di aláìní ọmọ bẹ́ẹ̀ ni ìyá rẹ yóò sì di aláìní ọmọ láàárin obìnrin.” Sámúẹ́lì sì pa Ágágì níwájú OLÚWA ni Gílígálì.

34Nígbà náà ni Sámúẹ́lì lọ sí Rámà, Ṣọ́ọ̀lù sì gòkè lọ sí ilé e rẹ̀ ní Gíbéà tí Ṣọ́ọ̀lù.

35Sámúẹ́lì kò sì padà wá mọ́ láti wo Ṣọ́ọ̀lù títí ó fi di ọjọ́ ikú u rẹ̀, ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì káànú fún Ṣọ́ọ̀lù. Ó sì dun OLÚWA pé ó fi Ṣọ́ọ̀lù jọba lórí Ísírẹ́lì.

/article>