1OLÚWA sọ fún Sámúẹ́lì pé, “Yóò ha ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa dárò Ṣọ́ọ̀lù, nígbà tí ó jẹ́ pé mo ti kọ̀ ọ́ ní ọba lórí Ísírẹ́lì? Rọ òróró kún inú ìwo rẹ, kí o sì mú ọ̀nà rẹ pọ̀n, Èmi rán ọ sí Jésè ará Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Èmi ti yan ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ láti jẹ ọba.”
2Sùgbọ́n Sámúẹ́lì wí pé; “Báwo ni èmi yóò ṣe lọ? Bí Ṣọ́ọ̀lù bá gbọ́ nípa rẹ̀, yóò pa mi.”
3Pe Jésè wá sí ibi ìrúbọ náà, Èmi yóò sì fi ohun tí ìwọ yóò ṣe hàn ọ́. Ìwọ yóò fi òróró yàn fún mi, ẹni tí èmi bá fi hàn ọ́.”
4Sámúẹ́lì ṣe ohun tí OLÚWA sọ. Nígbà tí ó dé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, àyà gbogbo àgbààgbà ìlú já, nígbà tí wọ́n pàdé rẹ̀. Wọ́n béèrè pé, “Ṣé àlàáfíà ní ìwọ bá wá?”
5Sámúẹ́lì sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni àlàáfíà ni; mo wá láti wá rúbọ sí OLÚWA. Ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì wá rúbọ pẹ̀lú ù mi.” Nígbà náà ni ó sì ya Jésè sí mímọ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀, ó sì pè wọ́n wá sí ibi ìrúbọ náà.
6Nígbà tí wọ́n dé, Sámúẹ́lì rí Élíábù, ó rò nínú ara rẹ̀ pé lóòótọ́ ẹni òróró OLÚWA dúró níbí níwájú OLÚWA.
7Ṣùgbọ́n OLÚWA sọ fún Sámúẹ́lì pé, “Má ṣe wo ti ìrísí rẹ̀ tàbí ti gíga rẹ̀, nítorí èmi ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀. OLÚWA kì í wo ohun tí ènìyàn máa ń wò. Ènìyàn máa ń wo òde ara ṣùgbọ́n OLÚWA máa ń wo ọkàn.”
8Nígbà náà ni Jésè pe Ábínádábù, ó sì jẹ́ kí ó rìn kọjá ní iwájú Sámúẹ́lì. Ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì wí pé, “OLÚWA kò yan ẹni yìí.”
9Jésè sì jẹ́ kí Sámà rìn kọjá ní iwájú Sámúẹ́lì, ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì wí pé, “OLÚWA kò yan ẹni yìí náà.”
10Jésè jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ̀ méje rìn kọjá ní iwájú Sámúẹ́lì ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì sọ fún un pé, “OLÚWA kò yan àwọn wọ̀nyí.”
11Nígbà náà ni ó béèrè lọ́wọ́ Jésè pé, “Ṣé èyí ni gbogbo àwọn ọmọ rẹ?”
12Ó sì ráńṣẹ́ sí i, wọ́n sì mú un wọlé wá, ó jẹ́ ẹni tó mọ́ra, àwọ̀ ara rẹ̀ dùn ún wò, ó jẹ́ arẹwà gidigidi.
13Nígbà náà ni Sámúẹ́lì mú ìwo òróró, ó sì ta á sí i ní orí ní iwájú àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀, láti ọjọ́ náà lọ, Ẹ̀mi mímọ́ OLÚWA wá sí orí Dáfídì nínú agbára. Sámúẹ́lì sì lọ sí Rámà.
14Nísinsìn yìí, ẹ̀mi OLÚWA ti kúrò lára Ṣọ́ọ̀lù, ẹ̀mi búburú láti ọ̀dọ̀ OLÚWA sì ń yọ ọ́ lẹ́nu.
15Àwọn ìránṣẹ́ Ṣọ́ọ̀lù sì wí fún un pé, “Wò ó, ẹ̀mi búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ń yọ ọ́ lẹ́nu.
16Jẹ́ kí OLÚWA wa pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó wà níhìn ín láti wa ẹnìkan tí ó lè fi dùùrù kọrin. Yóò sì ṣe é nígbà tí ẹ̀mi búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bá bà lé ọ, ìwọ yóò sì sàn.”
17Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ wá ẹnìkan tí ó lè kọrin dáradára kí ẹ sì mú u wá fún mi.”
18Ọ̀kan nínú ìránṣẹ́ náà dáhùn pé, “Èmi ti ri ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Jésè ti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tí ó mọ orin kọ, ó jẹ́ alágbára àti ológun. Ó ní ọgbọ́n ọ̀rọ̀ òun sì dára ní wíwò. OLÚWA sì wà pẹ̀lú u rẹ̀.”
19Ṣọ́ọ̀lù sì rán oníṣẹ́ sí Jésè wí pé, “Rán Dáfídì ọmọ rẹ sí mi, ẹni tí ó ń ṣọ́ àgùntàn.”
20Jésè sì mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ti a di ẹrù lé àti ìgò ọtí wáìnì àti ọmọ ewúrẹ́; ó sì rán wọn nípa ọwọ́ ọ Dáfídì ọmọ rẹ̀ sí Ṣọ́ọ̀lù.
21Dáfídì sì tọ Ṣọ́ọ̀lù lọ, ó sì dúró níwájú rẹ̀: òun sì fẹ́ ẹ gidigidi, Dáfídì sì wá di ẹni tí ń ru ìhámọ́ra rẹ̀.
22Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù ránṣẹ́ sí Jésè, pé, “Jẹ́ kí Dáfídì dúró níwájú mi, nítorí tí ó wù mí.”
23Ó sì ṣe, nígbà tí ẹ̀mi búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá bá dé sí Ṣọ́ọ̀lù, Dáfídì a sì fi ọwọ́ rẹ̀ kọrin lára dùùrù: a sì san fún Ṣọ́ọ̀lù, ara rẹ̀ a sì dá; ẹ̀mi búburú náà a sì fi sílẹ̀.