Ìwé Sámúẹ́lì Kìn-ín-ní 17:1-58 BYB2014 - Bible AI

1Fílístínì kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ fún ogun ní Síkọ̀ ti Júdà. Wọ́n pàgọ́ sí Efesidámímù, láàárin Síkọ̀ àti Ásékà,

2Ṣọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ́n kò ara wọ́n jọ pọ̀, wọ́n sì pàgọ́ ní àfonífojì ní Élà wọ́n sì gbé ogun wọn sókè ní ọ̀nà láti pàdé àwọn Fílístínì.

3Àwọn Fílístínì sì wà ní orí òkè kan àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì wà ní orí òkè mìíràn, àfonífojì sì wà láàrin wọn.

4Ọ̀gágun tí a ń pè ní Gòláyátì, tí ó jẹ́ ará Gátì, ó wá láti ibùdó Fílístínì. Ó ga ní ìwọ̀n mítà mẹ́ta.

5Ó ní àsíborí idẹ ní orí rẹ̀, ó sì wọ ẹ̀wù tí a fi idẹ pẹlẹbẹ ṣe, ìwọ̀n ẹ̀wù náà sì jẹ́ ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ṣékélì idẹ, (5,000) (kìlógírámù mẹ́tadínlọ́gọ́ta).

6Òun sì wọ ìhámọ́ra idẹ sí ẹsẹ̀ rẹ̀ àti àpáta idẹ kan láàrin ẹ̀yìn rẹ̀.

7Ọ̀pá rẹ̀ rí bí apása ìhunṣọ, orí ọ̀kọ̀ rẹ̀ sì wọn (600) kilogírámù méje irin, ẹni tí ó ru asà ogun rẹ̀ lọ ṣáájú u rẹ̀.

8Gòláyátì dìde, ó sì kígbe sí ogun Ísírẹ́lì pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi jáde wá, tí ẹ ṣe tò fún ogun? Ṣé èmi kì í ṣe Fílístínì ni, àbí ẹ̀yin kì í ṣe ìránṣẹ́ Ṣọ́ọ̀lù? Yan ọkùnrin kan kí o sì jẹ́ kí ó sọ̀kalẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ mi.

9Tí òhun bá sì le jà tí ó sì pa mí, àwa yóò di ẹrú u yín, ṣùgbọ́n tí èmi bá lè ṣẹ́gun rẹ̀ tí mo sì pa á, ẹ̀yin yóò di ẹrú u wa, ẹ̀yin yóò sì máa sìn wá.”

10Nígbà náà Fílístínì náà wí pé, “Èmi fi ìjà lọ ogun Ísírẹ́lì ní òní! Ẹ mú ọkùnrin kan wá kí ẹ sì jẹ́ kí a bá ara wa jà.”

11Nígbà tí Sáulù àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́ ọ̀rọ̀ Fílístínì, ìdààmú bá wọn

12Nísinsìn yìí Dáfídì jẹ́ ọmọ ará Éfúrátà kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jésè, tí ó wá látí Bétílẹ́hẹ́mù ní Júdà, Jésè ní ọmọ mẹ́jọ, ní àsìkò Sáulù ó ti darúgbó ẹni ọdún púpọ̀.

13Àwọn ọmọ Jésè mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí ó ti dàgbà bá Ṣọ́ọ̀lù lọ sí ojú ogun: Èyí àkọ́bí ni Élíábù: Èyí èkejì ni Ábínádábù, èyí ẹ̀kẹta sì ní Ṣámínà.

14Dáfídì ni ó kéré jù nínú wọn. Àwọn àgbà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sì tẹ̀lé Ṣọ́ọ̀lù,

15Ṣùgbọ́n Dáfídì padà lẹ́yìn Ṣọ́ọ̀lù, láti máa tọ́jú àgùntàn baba rẹ̀ ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.

16Fún ogójì ọjọ́, Fílístínì wá ṣíwájú ní àràárọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́ wọ́n sì fi ara wọn hàn.

17Nísinsìn yìí Jésè wí fún ọmọ rẹ̀ Dáfídì pé, “Mú ìwọ̀n éfà àti àgbàdo yíyan àti ìṣù àkàrà mẹ́wàá lọ fún àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ kí o sì ṣéré lọ sí ibùdó o wọn.

18Kí o sì mú wàrà mẹ́wàá yìí lọ́wọ́ fún adarí ogun ti wọn. Wo bí àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ ṣe wà kí o sì padà wá fún mi ní àmìn ìdánilójú láti ọ̀dọ̀ wọn.

19Wọ́n wà pẹ̀lú u Ṣọ́ọ̀lù àti gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì ní àfonífojì Élà, wọ́n bá àwọn Fílístínì jà.”

20Ní àárọ̀ kùtùkùtù Dáfídì fi agbo ẹran rẹ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn olùtọ́jú, ó di ẹrù, ó sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n gẹ́gẹ́ bí Jésè ti sọ fún un. Ó dé ibùdó bí àwọn ọmọ ogun ti ń lọ láti dúró ní ipò wọn ní ojú ogun, wọ́n hó ìhó ogun.

21Ísírẹ́lì àti Fílístínì lọ sí ojú ìjà wọ́n da ojú ìjà kọ ara wọn.

22Dáfídì sì kó ẹrù rẹ̀ ti àwọn olùtọ́jú ohun èlò, ó sì sá lọ sí ojú ogun ó sì kí àwọn ẹ̀gbọ́n ọn rẹ̀.

23Bí ó ṣe ń bá wọn sọ̀rọ̀, Gòláyátì akíkanjú Fílístínì tí ó wá láti Gátì yọra sí iwájú ní ojú ogun, ó sì kígbe fún ìpèníjà, Dáfídì sì gbọ́.

24Nígbà tí àwọn Ísírẹ́lì rí ọkùnrin náà, gbogbo wọn sì sá fún un ní ìbẹ̀rù-bojo.

25Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì wí pé, “Ǹjẹ́ ẹ̀yin kò ríi bí ọkùnrin yìí ṣe ń jáde wá? Ó jáde wá láti pe Ísírẹ́lì níjà. Ọba yóò fún ọkùnrin tí ó bá pa á ní ọrọ̀ púpọ̀. Yóò tún fi ọmọ rẹ̀ obìnrin fún un ní ìyàwó, yóò sì sọ ilé e baba rẹ̀ di òmìnira kúrò nínú sísan owó orí ní Ísírẹ́lì.”

26Dáfídì béèrè lọ́wọ́ ọkùnrin tí ó dúró ní ẹ̀gbẹ́ ẹ rẹ̀ pé, “Kí ni a ó ò ṣe fún ọkùnrin náà tí ó bá pa Fílístínì yìí, tí ó sì mú ẹ̀gàn kúrò lára Ísírẹ́lì? Ta ni aláìkọlà Fílístínì tí ó jẹ́ wí pé yóò máa gan ogun Ọlọ́run alààyè?”

27Wọ́n tún sọ fún un ohun tí wọ́n ti ń sọ, wọ́n sì wí pé, “Èyí ni ohun tí wọn yóò ṣe fún ọkùnrin tí ó bá pa á.”

28Nígbà tí Élíábù ẹ̀gbọ́n Dáfídì gbọ́ nígbà tí ó ń bá ọkùnrin yìí sọ̀rọ̀, ó bínú sí i, ó sì wí pé, “Kí ni ó dé tí ìwọ fi sọ̀kalẹ̀ wá síbí? Àti pé ta ni ìwọ fi àwọn àgùntàn kékeré tó kù ṣọ́ ní ihà? Èmi mọ ìgbéraga rẹ, àti búburú ọkàn rẹ: ìwọ sọ̀kalẹ̀ wá nìkan láti wòran ogun.”

29Dáfídì wí pé, “Kí ni mo ṣe nísinsìn yìí? Ǹjẹ́ mo lè sọ̀rọ̀ bí?”

30Ó sì yípadà sí ẹlòmíràn, ó sì ń sọ̀rọ̀ kán náà, ọkùnrin náà sì dáhùn bí ti ẹni ìṣáájú.

31Àwọn ènìyàn gbọ́ ohun tí Dáfídì sọ wọ́n sọ fún Ṣọ́ọ̀lù, Ṣọ́ọ̀lù sì ránṣẹ́ sí i.

32Dáfídì sọ fún Ṣọ́ọ̀lù pé, “Kí ẹnikẹ́ni má ṣe ba ọkàn jẹ́ nítorí Fílístínì yìí, ìránṣẹ́ rẹ yóò lọ láti bá a jà.”

33Ṣọ́ọ̀lù sì dáhùn pé, “Ìwọ kò tó láti jáde lọ pàdé ogun Fílístínì yìí àti láti bá a jà; ọmọdé ni iwọ́, òun sì ti ń jagun láti ìgbà èwe rẹ̀ wá.”

34Ṣùgbọ́n Dáfídì sọ fún Ṣọ́ọ̀lù pé, “Ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ ti ń tọ́jú agbo àgùntàn baba rẹ̀. Nígbà tí kìnìún tàbí àmọ̀tẹ́kùn bá wá láti wá gbé àgùntàn láti inú igbó.

35Mo sá tẹ̀lé e, mo lù ú, mo sì gba àgùntàn náà kúrò lẹ́nu rẹ̀. Nígbà tí ó kọjú sí mi, mo fi irun rẹ̀ gbá a mú, mo sì lù ú mo sì pa á.

36Ìránṣẹ́ rẹ ti pa kìnnìún àti àmọ̀tẹ́kùn, aláìkọlà Fílístínì yìí yóò jẹ́ ọ̀kan lára wọn, nítorí ó ti pe ogun Ọlọ́run alààyè ní ìjà.

37OLÚWA tí ó gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìhàlẹ̀ kìnnìún àti ti ìhàlẹ̀ àmọ̀tẹ́kùn yóò gbà mí kúrò lọ́wọ́ Fílístínì yìí.”

37Ṣọ́ọ̀lù wí fún Dáfídì pé, “Lọ kí OLÚWA wà pẹ̀lú ù rẹ.”

38Ṣọ́ọ̀lù fi aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀ wọ Dáfídì, ó wọ̀ ọ́ ní aṣọ ìhámọ́ra ogun, ó sì fi ìbòrí idẹ kan bò ó ní orí.

39Dáfídì si di idà rẹ̀ mọ́ àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní rìn káàkiri nítorí wí pé kò mọ́ ọ lára.

39Ó sọ fún Ṣọ́ọ̀lù pé, “Èmi kò le wọ èyí lọ, kò mọ́ mi lára.” Ó sì bọ́ wọn kúrò.

40Nígbà náà, ó sì mú ọ̀pá a rẹ̀ lọ́wọ́, ó ṣa òkúta dídán márùn ún létí odò, ó kó wọn sí àpò olùṣọ́ àgùntàn tí ó wà lọ́wọ́ ọ rẹ̀ pẹ̀lú kànnàkànnà.

41Lákòókò yìí, Fílístínì pẹ̀lú ẹni tí ń gbé ìhámọ́ra ààbò wà níwájú rẹ̀, ó ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ Dáfídì.

42Ó wo Dáfídì láti òkè délẹ̀, ó sì rí i wí pé ọmọ kékeré kùnrin ni, ó pọ́n ó sì lẹ́wà lójú, ó sì kẹ́gàn an rẹ̀.

43Ó sì wí fún Dáfídì pé, “Ṣé ajá ni mí ni? Tí o fi tọ̀ mí wá pẹ̀lú ọ̀pá?” Fílístínì sì gbé Dáfídì bú pẹ̀lú Ọlọ́run rẹ̀.

44Ó wí pé, “Wá níbí, èmi yóò fi ẹran ara rẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run jẹ àti fún àwọn ẹranko tí ó wà nínú igbó!”

45Dáfídì sì wí fún Fílístínì pé, “Ìwọ dojú ìjà kọ mí pẹ̀lú idà, ọ̀kọ̀ àti ọfà, ṣùgbọ́n èmi wá sí ọ̀dọ̀ rẹ pẹ̀lú orúkọ OLÚWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì tí ìwọ tí gàn.

46Lónìí yìí ni OLÚWA yóò fi ọ́ lé mi lọ́wọ́, èmi yóò sì pa ọ́, èmi yóò sì gé orí ì rẹ. Lónìí èmi yóò fi òkú ogun Fílístínì fún ẹyẹ ojú ọ̀run àti fún ẹranko ìgbó, gbogbo ayé yóò sì mọ̀ pé Ọlọ́run wà ní Ísírẹ́lì.

47Gbogbo àwọn tí ó péjọ níbí ni yóò mọ̀ pé kì í ṣe nípa ọ̀kọ̀ tàbí idà ni OLÚWA fi ń gbàlà; ogun náà ti OLÚWA ni, yóò sì fi gbogbo yín lé ọwọ́ ọ wa.”

48Bí Fílístínì ṣe súnmọ́ iwájú láti pàdé e rẹ̀. Dáfídì yára sáré sí oun náà láti pàdé e rẹ̀.

49Ó ti ọwọ́ sí àpò rẹ̀ ó sì mú òkúta jáde wá ó sì fì í, ó sì jù ú sí ọ̀kọ́kán iwájú orí Fílístínì. Òkúta náà sì wọ̀ ọ́ níwájú orí, ó sì ṣubú ó sì dojúbolẹ̀ ní orí ilẹ̀.

50Dáfídì yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí Fílístínì pẹ̀lú kànnàkànnà àti òkúta, láìsí idà ní ọwọ́ rẹ̀, ó lu Fílístínì ó sì pa á.

51Dáfídì sì sáré ó sì dúró lórí rẹ̀. Ó sì mú idà Fílístínì, ó sì fà á yọ nínú àkọ̀ ọ rẹ̀. Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti pa á tan, ó sì gé orí i rẹ̀ pẹ̀lú idà. Nígbà tí àwọn ará Fílístínì rí i wí pé akọni wọn ti kú, wọ́n yípadà wọ́n sì sálọ.

52Nígbà náà, àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì àti ti Júdà súnmọ́ iwájú pẹ̀lú ariwo, wọ́n sì lépa àwọn ará Fílístínì dé ẹnu ibodè Gátì àti títí dé ẹnu ibodè Ékírónì. Àwọn tí ó kú wà káàkiri ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà Ṣáráímù àti títí dé ọ̀nà Gátì àti Ékírónì.

53Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì padà láti máa lé àwọn ará Fílístínì, wọ́n sì ba ibùdó wọn jẹ́.

54Dáfídì gé orí Fílístínì ó sì gbé e wá sí Jérúsálẹ́mù, ó sì kó àwọn ohun ìjà Fílístínì sìnú àgọ́ tirẹ̀.

55Bí Ṣọ́ọ̀lù sì ti wo Dáfídì bí ó ṣe ń jáde lọ pàdé Fílístínì, ó wí fún Ábínérì, olórí àwọn ológun rẹ̀ pé, “Ábínérì, ọmọ ta ni ọmọdékùnrin yìí?” Ábínérì dáhùn pe, “Bí ọkàn rẹ̀ ti ń bẹ ní ààyè, ọba èmi kò mọ̀.”

56Ọba sì wí pé, “Wádìí ọmọ ẹni tí ọmọdékùnrin náà ń ṣe.”

57Gbàrà tí ó dé láti ibi tí ó ti lọ pa Fílístínì, Ábínérì sì mú u wá ṣíwájú u Ṣọ́ọ̀lù, orí Fílístínì sì wà ní ọwọ́ Dáfídì.

58Ṣọ́ọ̀lù béèrè pé, “Ọmọdékùnrin, ọmọ ta ni ọ́?” Dáfídì dáhùn pé, “Èmi ni ọmọ ìránṣẹ́ rẹ Jésè ti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.”

/article>