Ìwé Sámúẹ́lì Kìn-ín-ní 2:1-36 BYB2014 - Bible AI

1Hánà sì gbàdúrà pé: “Ọkàn mi yọ̀ sí OLÚWA; Ìwọ agbára mi ni a sì gbé sókè sí OLÚWA. Ẹnu mi sì gbòòrò lórí àwọn ọ̀ta mi, nítorí ti èmi yọ̀ ni igbala rẹ̀

2“Kò sí ẹni tí ó mọ́ bi OLÚWA; kò sí ẹlòmíràn bí kò se ìwọ; kò sì sí àpáta bi Ọlọ́run wa.

2

3“Má ṣe halẹ̀; má ṣe jẹ́ kí ìgbéraga ti ẹnu yín jáde nítorí pé Ọlọ́run olùmọ̀ ni OLÚWA, láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá ni a ti ń wọn ìwà.

3

4“Ọrun àwọn alágbára ti ṣẹ́, àwọn tí ó ṣe aláìlera ni a fi agbára dì ní àmùrè.

5Àwọn tí ó yọ̀ fún òunjẹ ti fi ara wọn ṣe alágbàṣe, àwọn tí ebi ń pa kò sì ṣe aláìní: tóbẹ́ẹ̀ ti àgàn fi bí méje. Ẹni tí ó bímọ púpọ̀ sì di aláìlágbára.

5

6“OLÚWA pa ó sì sọ di ààyè; ó mú sọ̀kalẹ̀ lọ sí isà-òkú, ó sì gbé dìde.

7OLÚWA sọ di talákà; ó sì sọ di ọlọ́rọ̀; ó rẹ̀ sílẹ̀, ó sì gbé sókè.

8Ó gbé tálákà sókè láti inú erùpẹ̀ wá, ó gbé alágbe sókè láti orí òkítì eérú wá, láti mú wọn jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé, láti mu wọn jogún ìtẹ́ ogo:

8“Nítorí pé ọ̀wọ̀n ayé ti OLÚWA ni, ó sì ti gbé ayé ka orí wọn

9Yóò pa ẹsẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ mọ́, àwọn ènìyàn búburú ni yóò dákẹ́ ní òkùnkùn.

9“Nípa agbára kò sí ọkùnrin tí yóò borí.

10A ó fọ àwọn ọ̀tá OLÚWA túútúú; láti ọrun wá ni yóò sánààrá sí wọn; OLÚWA yóò ṣe ìdájọ́ òpin ayé.

10“Yóò fi agbára fún ọba rẹ̀, yóò si gbé ìwo ẹni-àmì-òróró rẹ̀ sókè.”

11Elikánà sì lọ sí Rámà sí ilé rẹ̀, Ọmọ náà sì ń ṣe ìráńṣẹ́ fún OLÚWA níwájú Élì àlùfáà.

12Àwọn ọmọ Élì sì jẹ́ ọmọ Bélíálì; wọn kò mọ OLÚWA.

13Iṣẹ́ àwọn àlùfáà pẹ̀lú àwọn ènìyàn ni pé nígbà tí ẹnìkan bá ṣe ìrúbọ, ìráńṣẹ́ àlùfáà á dé, nígbà tí ẹran náà bá ń hó lórí iná, pẹ̀lú ọ̀pá-ẹran náà oníga mẹ́ta ní ọwọ́ rẹ̀.

14Òun a sì fi gún inú apẹ, tàbí Kẹ́tìlì tàbí òdù, tàbí ìkòkò, gbogbo èyí tí ọ̀pá-ẹran oníga náà bá mú wá sí òkè, àlùfáà á mú un fún ara rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ṣe sí gbogbo Ísírẹ́lì tí ó wá sí ibẹ̀ ní Ṣílò.

15Pẹ̀lú, kí wọn tó sun ọ̀rá náà, ìráńṣẹ́ àlùfáà á dé, á sì wí fún ọkùnrin tí ó ń ṣe ìrúbọ pé, “Fi ẹran fún mi láti sun fún àlùfàá; nítorí tí kì yóò gba ẹran sísè lọ́wọ́ rẹ, bí kò se tútù.”

16Bí ọkùnrin náà bá sì wí fún un pé, “Jẹ́ kí wọn ó sun ọ̀rá náà nísinsin yìí, kí o sì mú iyekíye tí ọkàn rẹ̀ bá fẹ́;” nígbà náà ni yóò dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n kí ìwọ ó fi í fún mi nísinsin yìí, bí kó ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ó fi agbára gbà á.”

17Ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọ̀dọ́mọkùrin náà sì tóbi gidigidi níwájú OLÚWA: nítorí tí ènìyàn kórìíra ẹbọ OLÚWA.

18Ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì ń ṣe ìráńṣẹ́ níwájú OLÚWA, ọmọdé, ti a wọ̀ ní éfódì ọ̀gbọ̀.

19Pẹ̀lúpẹ̀lú, ìyá rẹ̀ máa ń dá aṣọ ìlekè péńpé fún un, a sì máa mu wá fún un lọdọọdún, nígbà tí ó bá bá ọkọ rẹ̀ gòkè wá láti ṣe ìrúbọ ọdún.

20Élì súre fún Elikánà àti aya rẹ̀ pé, “Kí OLÚWA fún ọ ní irú-ọmọ láti ara obìnrin yìí wá, nítorí ẹ̀bùn tí ó béèrè tí ó sì tún fún OLÚWA.” Wọ́n sì lọ sí ilé wọn.

21OLÚWA si bojú wo Hánà, ó sì lóyún, ó bí ọmọkùnrin mẹ́ta àti ọmọbìnrin méjì. Sámúẹ́lì ọmọ náà sì ń dàgbà níwájú OLÚWA.

22Élì sì di arúgbó gidigidi, ó sì gbọ́ gbogbo èyí ti àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe sí gbogbo Ísírẹ́lì; àti bi wọ́n ti máa ń bá àwọn obìnrin sùn, tí wọ́n máa ń péjọ ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ.

23Ó sì wí fún wọn pé, kí ni ó ti ri “Èétirí tí èmi fi ń gbọ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ sí yín? Nítorí tí èmi ń gbọ́ iṣẹ́ búburú yín láti ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn.

24Bẹ́ẹ̀ kọ́ ẹ̀yin ọmọ mi, nítorí kì ṣe ìròyìn rere èmi gbọ́; ẹyin mú ènìyàn Ọlọ́run dẹ́ṣẹ̀.

25Bí ẹnìkan bá ṣẹ̀ sí ẹnìkejì, onídàájọ́ yóò ṣe ìdájọ́ rẹ̀: ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá ṣẹ̀ sí OLÚWA, tani yóò bẹ̀bẹ̀ fún un?” Wọn kò sì fi etí sí ohùn baba wọn, nítorí tí OLÚWA ń fẹ́ pa wọ́n.

26Ọmọ náà Sámúẹ́lì ń dàgbà, ó sì rí ojúrere lọ́dọ̀ OLÚWA, àti ènìyàn pẹ̀lú.

27Ènìyàn Ọlọ́run kan tọ Élì wá, ó sì wí fún un pé, “Báyìí ni OLÚWA wí, ‘Èmi fi ara mi hàn ní gbangba fún ilé baba rẹ̀, nígbà tí wọ́n ń bẹ nínú ilé Fáráò.

28Èmi Éjíbítì sì yàn án kúrò láàrin gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì láti jẹ́ àlùfáà mi, láti rúbọ lórí pẹpẹ mi, lati fi tùràrí jóná, láti wọ éfódì níwájú mi, èmi sì fi gbogbo ẹbọ tí ọmọ Ísírẹ́lì máa ń fi iná sun fún ìdílé baba rẹ̀.

29Èé ha ṣe tí ẹ̀yin fi tàpá sí ẹbọ àti ọrẹ mi, tí mo páṣẹ ní ibùjókòó mi: ìwọ sì bu ọlá fún àwọn ọmọ rẹ jú mí lọ, tí ẹ sì fi gbogbo àṣàyàn ẹbọ Ísírẹ́lì àwọn ènìyàn mi mú ara yín sanra.’

30“Nítorí náà OLÚWA Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí pé, ‘Èmi ti wí nítòótọ́ pé, ilé rẹ àti ilé baba rẹ, yóò máa rìn níwájú mi títí.’ Ṣùgbọ́n nísinsin yìí OLÚWA wí pé, ‘Kí á má rí i! Àwọn tí ó bú ọlá fún mi ni èmi yóò bu ọlá fún, àti àwọn tí kò kà mí sí ni a ó sì ṣe aláìkàsí.

31Kíyèsí i, àwọn ọjọ́ ń bọ̀ tí èmi ó gé agbára rẹ kúrò, àti agbára baba rẹ, tí kì yóò sí arúgbó kan nínú ilé rẹ.

32Nínú wàhálà ni ìwọ yóò fí ìlará wó gbogbo ọlá ti Ọlọ́run yóò fi fún Ísírẹ́lì; kì yóò sì sí arúgbó kan nínú ilé baba rẹ láéláé.

33Ọkùnrin tí ó jẹ́ tìrẹ, tí èmi kì yóò gé kúrò ni ibi pẹpẹ mi ni a ó dá sí láti sunkún yọ lójú àti láti banújẹ́: Ṣùgbọ́n gbogbo irú-ọmọ ilé rẹ̀ ni a ó fi idà pa ní ààbọ̀ ọjọ́ wọn.

34“ ‘Kí ni ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ ọkùnrin rẹ̀ méjèèjì, Hófínì àti Fínéhásì, yóò jẹ́ àmì fún ọ, àwọn méjèèjì yóò kú ní ọjọ́ kan náà.

35Èmi yóò dìde fún ara mi láti gbé àlùfáà olódodo dìde fún ara mi ẹni tí yóò ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó wà ní ọkàn mi àti inú mi: Èmi yóò fi ẹṣẹ̀ ilé rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in òun yóò sì ṣe òjíṣẹ́ níwájú ẹni òróró mi ní ọjọ́ gbogbo.

36Nígbà náà olúkúlùkù ẹnikẹ́ni tí ó bá kù ní ìdílé yín, yóò jáde wá yóò sì foríbalẹ̀ níwájú rẹ̀ nítorí ẹyọ fàdákà àti nítorí èépá àkàrà àti ẹ̀bẹ̀ pé, “Jọ̀wọ́ yàn mí sí ọ̀kan nínú iṣẹ́ àwọn àlùfáà, kí èmi kí ó le máa rí oúnjẹ jẹ.” ’ ”

article>