1OLÚWA sì rán Nátanì sí Dáfídì òun sì tọ̀ ọ́ wá, ó sì wí fún un pé, “Ọkùnrin méjì ń bẹ ní ìlú kan; ọ̀kan jẹ́ ọlọ́rọ̀, èkejì sì jẹ́ talákà.
2Ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà sì ní àgùntàn àti màlúù lọ́pọ̀lọpọ̀.
3Ṣùgbọ́n ọkùnrin talákà náà kò sì ní nǹkan bí kò ṣe àgùntàn kékeré kan èyí tí ó sì ń tọ́: ó sì dàgbà ní ọwọ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀; a máa jẹ nínú oúnjẹ rẹ̀, a sí máa mu nínú ago rẹ̀, a sì máa dúbúlẹ̀ ní àyà rẹ̀, ó sì dàbí ọmọbìnrin kan fún un.
4“Àlejò kan sì tọ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà wá, òun kò sì fẹ́ mú nínú àgùntàn rẹ̀, àti nínú màlúù rẹ̀: láti fi ṣe àlejò fún ẹni tí ó tọ̀ ọ́ wá: o sì mú àgùntàn ọkùnrin talákà náà fi ṣe àlejò fún ọkùnrin tí ó tọ̀ ọ́ wá.”
5Ìbínú Dáfídì sì fàru gidigidi sí ọkùnrin náà; ó sì wí fún Nátanì pé, “Bí OLÚWA ti ń bẹ láàyè: ọkùnrin náà tí ó ṣe nǹkán yìí, kíkú ni yóò kú.
6Òun yóò sì san àgùntàn náà padà ní mẹ́rinmẹ́rin, nítorí tí ó ṣe nǹkan yìí àti nítorí tí kò ní àánú.”
7Nátanì sì wí fún Dáfídì pé, “Ìwọ ni ọkùnrin náà Báyìí ni OLÚWA Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, ‘Èmi fi ọ́ jọba lórí Ísírẹ́lì, èmi sì gbà ọ́ lọ́wọ́ Ṣọ́ọ̀lù.
8Èmi sì fi ilé olúwa rẹ fún ọ, àti àwọn obìnrin olúwa rẹ sí àyà rẹ, èmi sì fi ìdílé Ísírẹ́lì àti ti Júdà fún ọ; tí àwọn wọ̀nyí bá sì kéré jù fún ọ èmi ìbá sì fún ọ sí i jù bẹ́ ẹ̀ lọ.
9Èéṣe tí ìwọ fi kẹ́gan ọ̀rọ̀ OLÚWA, tí ìwọ fi ṣe nǹkan tí ó burú lójú rẹ̀, àní tí ìwọ fi fi idà pa Ùráyà ará Hítì, àti tí ìwọ fi mú obìnrin rẹ̀ láti fi ṣe obìnrin rẹ, o sì fi idà àwọn ọmọ Ámónì pa á.
10Ǹjẹ́ nítorí náà idà kì yóò kúró ní ilé rẹ títí láé; nítorí pé ìwọ gàn mí, ìwọ sì mú aya Úráyà ará Hítì láti ṣe aya rẹ.’
11“Bàyìí ni OLÚWA wí, Kíyèsí i, ‘Èmi ó jẹ́ kí ibi kí ó dìde sí ọ láti inú ilé rẹ wá, èmi ó sì gba àwọn obìnrin rẹ lójú rẹ, èmi ó sì fi wọ́n fún aládúgbò rẹ, òun ó sì bá àwọn obìnrin rẹ sùn níwájú òòrun yìí.
12Àti pé ìwọ ṣe é ní ìkọ̀kọ̀: Ṣùgbọ́n èmi ó ṣe nǹkan yìí níwájú gbogbo Ísírẹ́lì, àti níwájú òòrun.’ ”
13Dáfídì sì wí fún Nátanì pé, “Èmi ṣẹ̀ sí OLÚWA!”
14Ṣùgbọ́n nítorí nípa ìwà yìí, ìwọ fi àyè sílẹ̀ fún àwọn ọ̀ta OLÚWA láti sọ ọ̀rọ̀ òdì, ọmọ náà tí a ó bí fún ọ, kíkú ní yóò kú.”
15Nátanì sì lọ sí ilé rẹ̀ OLÚWA sì fi àrùn kọlu ọmọ náà tí obìnrin Úráyà bí fún Dáfídì, ó sì ṣe àìsàn púpọ̀.
16Dáfídì sì bẹ Ọlọ́run nítorí ọmọ náà, Dáfídì sì gbààwẹ̀, ó sì wọ inú ilé lọ, ó sì dúbúlẹ̀ lorí ilé ni orú náà.
17Àwọn àgbà ilé rẹ̀ sì dìde tọ̀ ọ́ lọ, láti gbé e dìde lórí ilé: ó sì kọ̀, kò sì bá wọn jẹun.
18Ní ijọ́ keje, ọmọ náà sì kú. Àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì sì bẹ̀rù láti wí fún un pé, ọmọ náà kú: nítorí tí wọ́n wí pé, “Kíyèsí i, nígbà tí ọmọ náà ń bẹ láàyè, àwa sọ̀rọ̀ fún un, òun kọ̀ si gbọ́ ohùn wa! Ǹjẹ́ yóò ti ṣe ara rẹ̀ ní ìṣẹ́ tó, bí àwa bá wí fún un pé, ọmọ náà kú.”
19Nígbà tí Dáfídì sì rí pé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, Dáfídì sì kìyésí i, pé ọmọ náà kú: Dáfídì sì béèrè lọ́wọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ọmọ náà kú bí?”
20Dáfídì sì dìde ní ilẹ̀, ó sì wẹ̀, ó fi òróró pa ara, ó sì pààrọ̀ aṣọ rẹ̀, ó sì wọ inú ilé OLÚWA lọ, ó sì wólẹ̀ sin: ó sì wá sí ilé rẹ̀ ó sì bèèrè, wọ́n sì gbé òunjẹ kalẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì jẹun.
21Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì bí léèrè pé, “Kí lèyí tí ìwọ ṣe yìí? Nítorí ọmọ náà nígbà tí ó ń bẹ láàyè ìwọ gbààwẹ̀, o sì sunkún; ṣùgbọ́n nígbà tí ọmọ náà kú, ó dìde ó sì jẹun.”
22Ó sì wí pé, “Nígbà tí ọmọ náà ń bẹ láàyè, èmi gbààwẹ̀, èmi sì sunkún: nítorí tí Èmi wí pé, ‘Ta ni ó mọ̀ bí Ọlọ́run ó ṣàánú mi, kí ọmọ náà le yè.’
23Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó ti kú, nítorí kín ni èmi ó ṣe máa gbààwẹ̀? Èmi ha tún lè mú-un padà bí? Èmi ni yóò tọ̀ ọ́ lọ, òun kì yóò sì tún tọ̀ mí wá.”
24Dáfídì sì ṣìpẹ̀ fún Bátíṣébà aya rẹ̀, ó sì wọlé tọ̀ ọ́, ó sì bá a dàpọ̀: òun sì bí ọmọkùnrin kan, Dáfídì sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Sólómónì: OLÚWA sì fẹ́ ẹ.
25Ó sì rán Nátanì wòlíì, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jédídíáyà, nítorí OLÚWA.
26
27Jóábù sì rán àwọn ìránṣẹ́ sí Dáfídì, ó sì wí pé, “Èmi ti bá Rábà jà, èmi sì ti gba àwọn ìlú olomi.
28Ǹjẹ́ nítorí náà kó àwọn ènìyàn ìyókù jọ, kí o sì dó ti ìlú náà, kí o sì gbà á, kí èmi má báà gba ìlú náà kí a má baà pè é ní orúkọ mi.”
29Dáfídì sì kó gbogbo ènìyàn náà jọ, sí Rábà, ó sì bá a jà, ó sì gbà á.
30Òun sì gba adé ọba wọn kúrò lórí rẹ̀, ìwúwo rẹ̀ sì jẹ́ talẹ́ńtì wúrà kan, ó sì ní òkúta oníyebíye lára rẹ̀; a sì fi dé Dáfídì lórí. Òun sì kó ìkógun ìlú náà ni ọ̀pọ̀lọpọ̀.
31Ó sì kó àwọn ènìyàn náà tí ó wà nínú rẹ̀, ó sì fi wọ́n sí iṣẹ́ ayùn, àti sí iṣẹ́ nǹkan ìtùlẹ̀ tí a fi irin ṣe, àti sí iṣẹ́ àáké irin, ó sì fi wọ́n sí iṣẹ́ bíríkì ṣíṣe: bẹ́ ẹ̀ náà ni òun sì ṣe sí gbogbo ìlú àwọn ọmọ Ámónì. Dáfídì àti gbogbo àwọn ènìyàn náà sì padà sí Jérúsálẹ́mù.