Ìwé Sámúẹ́lì Kejì 13:1-39 BYB2014 - Bible AI

1Ó sì ṣe, lẹ́yìn èyí, Ábúsálómù ọmọ Dáfídì ní àbúrò obìnrin kan tí ó ṣe arẹwà, orúkọ rẹ̀ a sì máa jẹ́ Támárì; Ámúnónì ọmọ Dáfídì sì fẹ́ràn rẹ̀.

2Ámúnónì sì banújẹ́ títí ó fi ṣe àìsàn nítorí Támárì àbúrò rẹ̀ obìnrin; nítorí pé wúndíá ni; ó sì ṣe ohun tí ó ṣòro lójú Ámúnónì láti bá a dàpọ̀.

3Ṣùgbọ́n Ámúnónì ní ọ̀rẹ́ kan, orúkọ rẹ̀ a sì máa jẹ́ Jónádábù, ọmọ Ṣíméà ẹ̀gbọ́n Dáfídì: Jónádábù sì jẹ́ alárékérekè ènìyàn gidigidi.

4Ó sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ ọmọ ọba ń fi ń rù lójojúmọ́ báyìí? Ǹjẹ́ o kò ní sọ fún mi?”

4Ámúnónì sì wí fún un pé, “Èmi fẹ́ Támárì àbúrò Ábúsálómù arákùnrin mi.”

5Jónádábù sì wí fún un pé, “Dùbúlẹ̀ ní ibùsùn rẹ kí ìwọ sì díbọ́n pé, ìwọ kò sàn: baba rẹ yóò sì wá wò ó, ìwọ ó sì wá fún un pé, ‘Jọ̀wọ́ jẹ́ kí Támárì àbúrò mi wá kí ó sì fún mi ní oúnjẹ́ kí ó sì ṣe oúnjẹ náà níwájú mi kí èmi ó rí i, èmi ó sì jẹ ẹ́ ní ọwọ́ rẹ̀.’ ”

6Ámúnónì sì dùbúlẹ̀, ó sì díbọ́n pé òun ṣàìsàn: ọba sì wá wò ó, Ámúnónì sì wí fún ọba pé, “Jọ́wọ́, jẹ́ kí Támárì àbúrò mi ó wá, kí ó sì dín àkàrà méjì lójú mi, èmi ó sì jẹ ní ọwọ́ rẹ̀.”

7Dáfídì sì ránṣẹ́ sí Támárì ní ilé pé, “Lọ sí ilé Ámúnónì ẹ̀gbọ́n rẹ, kí ó sì ṣe òunjẹ́ fún un.”

8Támárì sì lọ sí ilé Ámúnónì ẹ̀gbọ́n rẹ̀, òun sì ń bẹ ní ìdúbúlẹ̀. Támárì sì mú ìyẹ̀fun, ó sì pò ó, ó sì fi ṣe àkàrà lójú rẹ̀, ó sì dín àkàrà náà.

9Òun sì mú àwo náà, ó sì dà á sínú àwo mìíràn níwájú rẹ̀; ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti jẹ.

9Ámúnónì sì wí pé, “Jẹ́ kí gbogbo ọkùnrin jáde kúrò lọ́dọ̀ mi!” Wọ́n sì jáde olúkúlùkù ọkùnrin kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.

10Ámúnónì sì wí fún Támárì pé, “Mú oúnjẹ náà wá sí yàrá, èmi ó sì jẹ ẹ́ lọ́wọ́ rẹ.” Támárì sì mú àkàrà tí ó ṣe, ó sì mú un tọ Ámúnónì ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ní yàrá.

11Nígbà tí ó sì súnmọ́ ọn láti fi oúnjẹ fún un, òun sì dì í mú, ó sì wí fún un pé, “Wá dùbúlẹ̀ tì mí, àbúrò mi.”

12Òun sì dá a lóhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́ ẹ̀gbọ́n mi, má ṣe tẹ́ mi; nítorí pé kò tọ kí a ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ní Ísírẹ́lì, ìwọ má ṣe hùwà òmùgọ̀ yìí.

13Àti èmi, níbo ni èmi ó gbé ìtìjú mi wọ̀? Ìwọ ó sì dàbí ọ̀kan nínú àwọn aṣiwèrè ní Ísírẹ́lì. Ǹjẹ́ nítorí náà, èmi bẹ̀ ọ́, sọ fún ọba; nítorí pé òun kì yóò kọ̀ láti fi mí fún ọ.”

14Ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti gbọ́ ohùn rẹ̀; ó sì fi agbára mú un, ó sì ṣẹ́gun rẹ̀, ó sì bá a dàpọ̀.

15Ámúnónì sì kóríra rẹ̀ gidigidi, ìríra náà sì wá ju ìfẹ́ tí òun ti ní sí i rí lọ. Ámúnónì sì wí fún un pé, “Dìde, kí o sì máa lọ!”

16Òun sì wí fún un pé, “Kó ha ní ìdí bí! Lílé tí ìwọ ń lé mi yìí burú ju èyí tí ìwọ ti ṣe sí mi lọ.” Ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ gbọ́ tirẹ̀.

17Òun sì pe ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ tí í ṣe ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Jọ̀wọ́, ti obìnrin yìí sóde fún mi, kí o sì ti ilẹ̀kùn mọ́ ọn.”

18Òun sì ní aṣọ aláràbarà kan làra rẹ̀: nítorí irú aṣọ àwọ̀lékè bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọbìnrin ọba tí í ṣe wúndíá máa ń wọ̀. Ìránṣẹ́ rẹ̀ sì mú un jáde, ó sì ti ilẹ̀kùn mọ́ ọn.

19Támárì sì bu èérú sí orí rẹ̀, ó sì fa aṣọ aláràbarà tí ń bẹ lára rẹ̀ ya, ó sì ká ọwọ́ rẹ̀ lé orí, ó sì ń kígbe bí ó ti ń lọ.

20Ábúsálómù ẹ̀gbọ́n rẹ̀ sì bí i léèrè pé, “Ámúnónì ẹ̀gbọ́n rẹ bá ọ sùn bí? Ǹjẹ́ àbúrò mi, dákẹ́; ẹ̀gbọ́n rẹ ní í ṣe; má fi nǹkan yìí sí ọkàn rẹ.” Támárì sì jókòó ní ìbànújẹ́ ní ilé Ábúsálómù ẹ̀gbọ́n rẹ̀.

21Ṣùgbọ́n nígbà tí Dáfídì ọba gbọ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí, inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi.

22Ábúsálómù kò sì bá Ámíúnónì sọ nǹkan rere, tàbí búburú: nítorí pé Ábúsálómù kóríra Ámúnónì nítorí èyí tí ó ṣe, àní tí ó fi agbára mú Támárì àbúrò rẹ̀.

23Ó sì ṣe, lẹ́yìn ọdún méjì, Ábúsálómù sì ní olùrẹ́run àgùntàn ní Baalihásórì, èyí tí ó gbé Éfúráímù: Ábúsálómù sì pe gbogbo àwọn ọmọ ọba.

24Ábúsálómù sì tọ ọba wá, ó sì wí pé, “Wò ó, jọ̀wọ́, ìránṣẹ́ rẹ ní olùrẹ́run àgùntàn, èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ọba, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bá ìránṣẹ́ rẹ lọ.”

25Ọba sì wí fún Ábúsálómù pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ, ọmọ mi, mo bẹ̀ ọ́, má ṣe jẹ́ kí gbogbo wa lọ, kí a má báà mú ọ náwó púpọ̀.” Ó sì rọ̀ ọ́ gidigidi, ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ lọ, òun sì súre fún un.

26Ábúsálómù sì wí pé, “Bí kò bá le rí bẹ́ ẹ̀, èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí Ámúnónì ẹ̀gbọ́n mi bá wa lọ.” Ọba sì wí pé, “Ìdí rẹ̀ tí yóò fi bá ọ lọ.”

27Ábúsálómù sì rọ̀ ọ́, òun sì jẹ́ kí Ámúnónì àti gbogbo àwọn ọmọ ọba bá a lọ.

28Ábúsálómù sì fi àṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Kí ẹ̀yin máa kíyèsí àkókò tí ọtí-wáinì yóò mú ọkàn Ámúnónì dùn, èmi ó sì wí fún yín pé, ‘Kọlu Ámúnónì,’ kí ẹ sì pa á. Ẹ má bẹ̀rù. Ṣé èmi ni ó fi àṣẹ fún yin? Ẹ ṣe gírí, kí ẹ ṣe bí alágbára ọmọ.”

29Àwọn ìránṣẹ́ Ábúsálómù sì ṣe sí Ámúnónì gẹ́gẹ́ bí Ábúsálómù ti páṣẹ. Gbogbo àwọn ọmọ ọba sì dìde, olúkúlukú gun ìbaka rẹ̀, wọ́n sì sá.

30Nígbà tí wọ́n ń bẹ lọ́nà, ìhìn sì dé ọ̀dọ̀ Dáfídì pé, “Ábúsálómù pa gbogbo àwọn ọmọ ọba, ọ̀kan kò sì kù nínú wọn.”

31Ọba sì dìde, ó sì fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì dùbúlẹ̀ ni ilẹ̀; gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n dúró tì í sì fà aṣọ wọn ya.

32Jónádábù ọmọ Ṣíméà arakùnrin Dáfídì sì dáhùn ó sì wí pé, “Kí OLÚWA mi ọba má ṣe rò pé wọ́n ti pa gbogbo àwọn ọ̀dọ́mọdé-kùnrin àwọn ọmọ ọba; nítorí pé Ámúnónì nìkan ṣoṣo ni ó kú: nítorí láti ẹnu Ábúsálómù wá ni a ti pinnu rẹ̀ láti ọjọ́ tí ó ti fi agbára mú Támárì àbúrò rẹ̀.

33Ǹjẹ́ kí OLÚWA mi ọba má ṣe fi nǹkan yìí sí ọkàn pé gbogbo àwọn ọmọ ọba ni o kú: nítorí Ámúnónì nìkan ṣoṣo ni ó kú.”

34Ábúsálómù sì sá. Ọ̀dọ́mọkùnrin náà ti ń ṣọ́nà sì gbé ojú rẹ̀ sókè, o si ríi pé, “ọ̀pọ̀ ènìyàn ń bọ́ lọ̀nà lẹ́yin rẹ̀ láti ìhà òkè wá.”

35Jónádábù sì wí fún ọba pé, “Wò ó, àwọn ọmọ ọba ń bọ́; gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó rí.”

36Nígbà tí ó sì parí ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ, sì wò ó àwọn ọmọ ọba dé, wọ́n sì gbé ohùn wọn sòkè, wọ́n sì sunkún: ọba àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú sì sọkún ńláńlá.

37Ábúsálómù sì sá, ó sì tọ Támáì lọ, ọmọ Ámíhúdù, ọba Gésúrì. Dáfídì sì ń káàánú nítorí ọmọ rẹ̀ lojojúmọ́.

38Ábúsálómù sì sá, ó sì lọ sí Géṣúrì ó sì gbé ibẹ̀ lọ́dún mẹ́ta.

39Ọkàn Dáfídì ọba sì fà gidigidi sí Ábúsálómù: nítorí tí ó tí gba ìpẹ̀ ní ti Ámúnónì: ó sáà ti kú.

cle>