1A sì rò fún Jóábù pe, “Wò ó, ọba ń sunkun, ó sì ń gbààwẹ̀ fún Ábúsálómù.”
2Ìṣẹ́gun ijọ́ náà sì di ààwẹ̀ fún gbogbo àwọn ènìyàn náà, nítorí àwọn ènìyàn náà gbọ́ ní ijọ́ náà bí inú ọba ti bàjẹ́ nítorí ọmọ rẹ̀.
3Àwọn ènìyàn náà sì yọ́ lọ sí ìlú ní ijọ́ náà gẹ́gẹ́ bí àwọn bí ènìyàn tí a dójútì ṣe máa ń yọ́ lọ nígbà tí wọ́n bá sá lójú ìjà.
4Ọba sì bo ojú rẹ̀, ọba sì kígbe ní ohùn rara pé, “Áì! Ọmọ mi Ábúsálómù! Ábúsálómù ọmọ mi, ọmọ mi!”
5Jóábù sì wọ inú ile tọ ọba lọ, ó sì wí pé, “Ìwọ dójúti gbogbo àwọn ìránṣẹ rẹ lónìí, àwọn tí ó gba ẹ̀mí rẹ̀ là lónìí, àti ẹ̀mí àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, àti ti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀, àti àwọn aya rẹ̀, àti ẹ̀mí àwọn obìnrin rẹ.
6Nítorí pé ìwọ fẹ́ àwọn ọ̀tá rẹ, ìwọ sì kóríra àwọn ọ̀rẹ́ rẹ. Nítorí tí ìwọ wí lónìí pé, Ìwọ kò náání àwọn ọmọ ọba tàbí àwọn ìránṣẹ́; èmi sì rí lónìí pé, ìbáṣe pé Ábúsálómù wà láàyè, kí gbogbo wa sì kú lónìí, ǹjẹ́ ìbá dùn mọ́ ọ gidigidi.
7Sì dìde nísinsin yìí, lọ, kí o sì sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ: nítorí pé èmi fi OLÚWA búra, bí ìwọ kò bá lọ, ẹnìkan kì yóò bá ọ dúró ni alẹ́ yìí: èyí ni yóò sì burú fún ọ ju gbogbo ibi tí ojú rẹ ti ń rí láti ìgbà èwe rẹ wá títí ó fi di ìsinsinyìí.”
8Ọba sì dìde, ó sì jókòó ní ẹnu ọ̀nà, Wọ́n sì wí fún gbogbo àwọn ènìyàn náà pé, “Wò ó, ọba jókòó lẹ́nu ọ̀nà.” Gbogbo ènìyàn sì wá sí iwájú Ọba: nítorí pé, Ísírẹ́lì ti sá, olúkúlukú sí àgọ́ rẹ̀.
9Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì ń bà ara wọn jà nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì, pé, “Ọba ti gbà wá là lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, ó sì ti gbà wá kúrò lọ́wọ́ àwọn Fílístínì; òun sì wá sá kúrò ní ìlú nítorí Ábúsálómù.
10Ábúsálómù, tí àwa fi jọba lórí wa sì kú ní ogun: ǹjẹ́ èéṣe tí ẹ̀yín fi dákẹ́ tí ẹ̀yin kò sì sọ̀rọ̀ kan láti mú ọba padà wá?”
11Dáfídì ọba sì ránṣẹ́ sí Sádókù, àti sí Ábíátarì àwọn àlùfáà pé, “Sọ fún àwọn àgbà Júdà, pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin fi kẹ́yìn láti mú ọba padà wá sí ilé rẹ̀? Ọ̀rọ̀ gbogbo Ísírẹ́lì sì ti dé ọ̀dọ̀ ọba àní ní ilé rẹ̀.
12Ẹ̀yin ni ara mi, ẹ̀yin ni egungun mi, àti ẹran ara mi: èésì ti ṣe tí ẹ̀yin fi kẹ́yìn láti mú ọba padà wá.’
13Kí ẹ̀yin sì wí fún Ámásà pé, ‘Egungun àti ẹran ara mi kọ́ ni ìwọ jẹ́ bí? Kí Ọlọ́run ó ṣe bẹ́ẹ̀ sí mi àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú, bí ìwọ kò ba ṣe olórí ogun níwájú mi títí, ní ipò Jóábù.’ ”
14Òun sì yí gbogbo àwọn ọkùnrin Júdà lọ́kàn padà àní bí ọkàn ènìyàn kan; wọ́n sì ránṣẹ́ sí ọba, pé, “Ìwọ padà àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ.”
15Ọba sì padà, o sì wá sí odò Jódánì, Júdà sì wá sí Gílígálì láti lọ pàdé ọba, àti láti mú ọba kọjá odò Jódánì.
16Ṣíméhì ọmọ Gérà, ará Bẹ́ńjámínì ti Báhúrímù, ó yára ó sì bá àwọn ọkùnrin Júdà sọ̀kalẹ̀ láti pàdé Dáfídì ọba.
17Ẹgbẹ̀rún ọmọkùnrin sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nínú àwọn ọmọkùnrin Bẹ́ńjámínì, Ṣíbà ìránṣẹ́ ilé Ṣọ́ọ̀lù, àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mẹ́ẹ̀dógún àti ogún ìránṣẹ́ sì pẹ̀lú rẹ̀; wọ́n sì gòkè odò Jódánì ṣáájú ọba.
18Ọkọ̀ èrò kan ti rékọjá láti kó àwọn ènìyàn ilé ọba sí òkè, àti láti ṣe èyí tí ó tọ́ lójú rẹ̀.
19Ó sì wí fún ọba pé, “Kí OLÚWA mi ó má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀ sí mi lọ́rùn, má sì ṣe rántí àfojúdi tí ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣe ni ọjọ́ tí OLÚWA mi ọba jáde ní Jérúsálẹ́mù, kí ọba má sì fi sí inú.
20Nítorí pé ìránṣẹ́ rẹ mọ̀ pé èmi ti ṣẹ̀; sì wòó, mo wá lónìí yìí, ẹni àkọ́kọ́ ní gbogbo ìdílé Jósẹ́fù tí yóò sọ̀kalẹ̀ wá pàdé OLÚWA mi ọba.”
21Ṣùgbọ́n Ábíṣáì ọmọ Serúíà dáhùn ó sì wí pé, “Kò há tọ́ kí a pa Síméì nítorí èyí? Nítorí pé òun ti bú ẹni àmì òróró OLÚWA.”
22Dáfídì sì wí pé, “Kí ni èmi ní ṣe pẹ̀lú yín, ẹ̀yin ọmọ Serúíà tí ẹ dàbí ọ̀ta fún mi lónìí? A há lè pa ènìyàn kan lónìí ní Ísírẹ́lì? Tàbí èmi kò ha mọ̀ pé lónìí èmi ni ọba Ísírẹ́lì.”
23Ọba sì wí fún Ṣíméhì pé, “Ìwọ kì yóò kú!” Ọba sì búra fún un.
24Méfíbóṣetì ọmọ Ṣọ́ọ̀lù sì sọ̀kalẹ̀ láti wá pàdé ọba, kò wẹ ẹṣẹ̀ rẹ̀, kò sí tọ́ irungbọ̀n rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sì fọ aṣọ rẹ̀ láti ọjọ́ tí ọba ti jáde títí ó fi di ọjọ́ tí ó fi padà ní àlàáfíà.
25Nígbà tí òun sì wá sí Jérúsálẹ́mù láti pàdé ọba, ọba sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ kò fi bá mi lọ, Méfíbóṣétì?”
26Òun sì dáhùn wí pé, “OLÚWA mi, Ọba, ìránṣẹ́ mi ni ó tàn mí, nítorí ìránṣẹ́ rẹ wí fún un pé, ‘Di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì fún mi èmi ó gùn ún, èmi ó sì tọ ọba lọ.’ Nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ yarọ.
27Ó sì sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí ìránṣẹ́ rẹ, fún OLÚWA mi ọba, ṣùgbọ́n bí áńgẹ́lì Ọlọ́run ni OLÚWA mi ọba rí: nítorí náà ṣe èyí tí ó dára lójú rẹ.
28Nítorí pé gbogbo ilé baba mi bí òkú ènìyàn ni wọ́n sáà rí níwájú OLÚWA mi ọba: ìwọ sì fi ipò fún ìránṣẹ́ rẹ láàrin àwọn tí ó ń jẹ́un ní ibi oúnjẹ́. Nítorí náà àre kín ni èmi ní tí èmi yóò fi máa ké pe ọba síbẹ̀.”
29Ọba sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń sọ ọ̀ràn ara rẹ fún mi èmi sáà ti wí pé, kí ìwọ àti Ṣíbà pín ilẹ̀ náà.”
30Méfíbóṣétì sì wí fún ọba pé, “Jẹ́ kí ó mú gbogbo rẹ̀, kí OLÚWA mi ọba sáà ti padà bọ̀ wá ilé rẹ̀ ni àlàáfíà.”
31Básíláì ará Gílíádì sì sọ̀kalẹ̀ láti Rogelímù wá, ó sì bá ọba gòkè odò Jódánì, láti ṣe ìkẹ́ rẹ̀ sí ìkọjá odò Jódánì.
32Básíláì sì jẹ́ arúgbó ọkùnrìn gidigidi, ẹni ogbó ọgọ́rin ọdún sì ni: ó sì pèsè ohun jíjẹ fún ọba nígbà tí ó ti wà ní Máhánáímù; nítorí pé ọkùnrin ọlọ́lá ni òun ń ṣe.
33Ọba sì wí fún Básíláì pé, “Ìwọ wá bá mi gòkè odò, èmi ó sì máa pésè fún ọ ní Jérúsálẹ́mù.”
34Básíláì sì wí fún ọba pé, “Ọjọ́ mélòó ni ọdún ẹ̀mí mi kù, tí èmi ó fi bá ọba gòkè lọ sí Jérúsálẹ́mù
35Ẹni ogbó ọgọ́rin ọdún sáà ni èmi lónìí: ǹjẹ́ èmi mọ ìyàtọ̀ nínú rere àti búburú? Ǹjẹ́ ìránṣẹ́ rẹ ló mọ adùn ohun tí òun ń jẹ tàbí ohun ti òun ń mu bí? Èmi tún lè mọ adùn ohùn àwọn ọkùnrin tí ń kọrin àti àwọn obìnrin tí ń kọ́rin bí, ǹjẹ́ nítorí kínni ìránṣẹ́ rẹ yóò ṣe jẹ́ ìyọnu síbẹ̀ fún OLÚWA mi ọba.
36Ìránṣẹ́ rẹ yóò sì sin ọba lọ díẹ̀ gòkè odò Jódánì; èésì ṣe tí ọba yóò fi san ẹ̀san yìí fún mi.
37Èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ìránṣẹ́ rẹ padà, èmi ó sì kú ní ìlú mi, a ó sì sin mí ní ibojì baba àti ìyá mi. Sì wo Kimhámù ìránṣẹ́ rẹ, yóò bá OLÚWA mi ọba gòkè; ìwọ ó sì ṣe ohun tí ó bá tọ́ lójú rẹ fún un.”
38Ọba sì dáhùn wí pé, “Kímhámù yóò bá mi gòkè, èmi ó sì ṣe èyí tí ó tọ́ lójú rẹ̀ fún un; ohunkóhun tí ìwọ bá sì béèrè lọ́wọ́ mi, èmi ó ṣeé fún ọ.”
39Gbogbo àwọn ènìyàn sì gòkè odò Jódánì ọba sì gòkè; ọba sì fi ẹnu ko Básíláì lẹ́nu, ó sì súre fún un; òun sì padà sí ilé rẹ̀.
40Ọba sì ń lọ́ sí Gílígálì, Kímhámù sì ń bà a lọ, gbogbo àwọn ènìyàn Júdà sì ń ṣe ìkẹ́ ọba, àti ààbò àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì.
41Sì wò ó, gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sì tọ ọba wá, wọ́n sì wí fún ọba pé, “Èéṣe tí àwọn arákùnrin wa àwọn ọkùnrin Júdà fi jí ọ kúrò, tí wọ́n sì fi mú ọba àti àwọn ará ilé rẹ̀ gòkè odò Jódánì, àti gbogbo àwọn ènìyàn Dáfídì pẹ̀lú rẹ?”
42Gbogbo ọkùnrin Júdà sì dá àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì lóhùn pé, “Nítorí pé ọba bá wa tan ni; èéṣe tí ẹ̀yin fi bínú nítorí ọ̀ràn yìí? Àwa jẹ nínú òúnjẹ ọba rárá bí? Tàbí ó fi ẹ̀bùn kan fún wa bí?”
43Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì náà sì dá àwọn ọkùnrin Júdà lóhùn pé, “Àwa ní ipá mẹ́wàá nínú ọba, àwa sì ní nínú Dáfídì jù yín lọ, èésì ṣe tí ẹ̀yin kò fi kà wá sí, tí ìmọ̀ wa kò fi ṣáájú láti mú ọba wa padà?”