Ìwé Sámúẹ́lì Kejì 22:1-51 BYB2014 - Bible AI

1Dáfídì sì kọ ọ̀rọ̀ orin yìí sí OLÚWA ní ọjọ́ tí OLÚWA gbà á kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀ta rẹ̀, àti kúrò lọ́wọ́ Sọ́ọ̀lù.

2ⓐ Ó sì wí pé,

2“OLÚWA ni àpáta mi, àti Olùgbàlà mi;

3Ọlọ́run mi, àpáta mi, nínú ẹni tí èmi ní ààbò, àti ìwọ ìgbàlà mi, ibi ìsádi gíga mi, àti ibi ìlùmọ̀ mi, Olùgbàlà mi; ìwọ ni ó ti gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìwà ipá.

4Èmi képe OLÚWA, tí ó yẹ láti máa yìn, ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.

4

5“Nígbà tí ìbìlù ìrora ikú yí mi káàkiri; tí àwọn ìṣàn ènìyàn búburú dẹ́rùbà mí.

6Ọ̀já isà-òkú yí mi káàkiri; ìkẹ́kùn ikú dojú kọ mí.

7Nínú ìpọ́njú mi, èmi ké pé OLÚWA, èmi sì gbé ohùn mi sókè sí Ọlọ́run mi. Ó sí gbóhùn mi láti tẹ́ḿpìlì rẹ̀ igbe mí wọ etí rẹ̀.

7

8“Ilẹ̀ sì mì, ó sì wárìrì; ìpìlẹ̀ ọ̀run wárìrì, ó sì mì, nítorí tí ó bínú.

9Èéfín sì jáde láti ihò-imú rẹ̀ wá; iná láti ẹnu rẹ̀ wá, ó sì ń jónirun, ẹ̀yín sì ń ràn nípasẹ rẹ̀.

10Ó tẹ orí ọ̀run ba pẹ̀lú, ó sì sọ̀kalẹ̀; òkùnkùn biribiri sì ń bẹ ní àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀.

11Ó sì gun orí kérúbù, ó sì fò: a sì rí i lórí ìyẹ́ afẹ́fẹ́.

12Ó sì fi òkùnkùn ṣe ibùjókòó yí ara rẹ̀, àti àgbájọ omi, àní ìsúdudu ìkùukùu àwọ̀n sánmà.

13Nípaṣẹ̀ ìmọ́lẹ̀ iwájú rẹ̀ ẹ̀yín-iná ràn.

14OLÚWA sán ààrá láti ọ̀run wá, ọ̀gá ogo jùlọ sì fọhùn rẹ̀.

15Ó sì ta ọfà, ó sì tú wọn ká; ó kọ mànàmànà, ó sì ṣẹ́ wọn.

16Ìṣàn ibú òkun sì fi ara hàn, ìpìlẹ̀ ayé fi ara hàn, nípa ìbáwí OLÚWA, nípa fífún èémí ihò imú rẹ̀.

16

17“Ó ránṣẹ́ láti òkè wá, ó mú mi; ó fà mí jáde láti inú omi ńlá wá.

18Ó gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá mi alágbára, lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra mi: nítorí pé wọ́n lágbára jù mí lọ.

19Wọ́n wá láti borí mi lọ́jọ́ ìpọ́njú mi: ṣùgbọ́n OLÚWA ni aláfẹ̀hìntì mi.

20Ó sì mú mi wá sí àyè ńlá: ó gbà mi, nítorí tí inú rẹ̀ dún sí mi.

20

21“OLÚWA sán án fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi; ó sì san án fún mi gẹ́gẹ́ bí mímọ́ ọwọ́ mi.

22Nítorí pé èmi pa ọ̀nà OLÚWA mọ́, èmi kò sì fi ìwà búburú yapa kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run mi.

23Nítorí pé gbogbo ìdájọ́ rẹ̀ ni ó wà níwájú mi; àti ní ti òfin rẹ̀, èmi kò sì yapa kúrò nínú wọn.

24Èmi sì wà nínú ìwà-títọ́ sí í, èmi sì pa ara mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi.

25OLÚWA sì san fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi, gẹ́gẹ́ bí ìwà-mímọ́ mi níwájú rẹ̀.

25

26“Fún aláàánú ni ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ni aláàánú, àti fún ẹni-ìdúró-ṣinṣin ní òdodo ni ìwọ ó fi ara rẹ hàn ní ìdúró-ṣinṣin ní òdodo.

27Fún onínú-funfun ni ìwọ fi ara rẹ hàn ní funfun; àti fún ẹni-wíwọ́ ni ìwọ ó fi ara rẹ hàn ní wíwọ́.

28Àwọn ènìyàn tí ó wà nínú ìyà ni ìwọ ó sì gbàlà; ṣùgbọ́n ojú rẹ wà lára àwọn agbéraga, láti rẹ̀ wọ́n sílẹ̀.

29Nítorí ìwọ ni ìmọ́lẹ̀ mi, OLÚWA; OLÚWA yóò sì sọ òkùnkùn mi di ìmọ́lẹ̀.

30Bẹ́ẹ̀ ni nítorí nípa rẹ̀ ni èmi ti la àárin ogun kọjá; nípa Ọlọ́run mi èmi ti fo odi kan.

30

31“Ọlọ́run yìí, pípé ni ọ̀nà rẹ̀; ọ̀rọ̀ OLÚWA ni a ti dán wò. Òun sì ni aṣà fún gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé e.

32Nítorí ta ni Ọlọ́run, bí kò ṣe OLÚWA? Ta ni àpáta, bí kò ṣe Ọlọ́run wa.

33Ọlọ́run alágbára ni ó fún mi ní agbára, ó sì sọ ọ̀nà mi di títọ́.

34Ó ṣe ẹsẹ̀ mi bí ẹṣẹ̀ àgbọ̀nrín; ó sì mú mi dúró ní ibi gígá mi.

35Ó kọ́ ọwọ́ mi ní ogun jíjà; tóbẹ́ẹ̀ tí apá mi fa ọrun idẹ.

36Ìwọ sì ti fún mi ní àsà ìgbàlà rẹ̀, ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ sì ti sọ mí di ńlá.

37Ìwọ sì fi àyè ńlá sí abẹ́ ìṣísẹ̀ mi; tóbẹ́ẹ̀ tí ẹsẹ̀ mi kò fi yọ̀.

37

38“Èmi ti lépa àwọn ọ̀tá mi, èmi sì ti run wọ́n, èmi kò pẹ̀yìndà títí èmi fi run wọ́n.

39Èmi ti pa wọ́n run, èmi sì ti fọ́ wọn, wọn kò sì le dìde mọ́: wọ́n ṣubú lábẹ́ mi.

40Ìwọ sì ti fi agbára dì mí ní àmùrè fún ìjà; àwọn tí ó ti dìde sí mi ni ìwọ sì ti tẹ̀ lórí ba fún mi.

41Ìwọ sì mú àwọn ọ̀ta mi pẹ̀yìndà fún mi, èmi ó sì pa àwọn tí ó kórira mi run.

42Wọ́n wò, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan láti gbà wọ́n; wọ́n wo OLÚWA, ṣùgbọ́n kò dá àwọn lóhùn.

43Nígbà náà ni èmi sì gún wọn wẹ́wẹ́ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, èmi sì tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ bí ẹrẹ̀ ìta, èmi sì tẹ́ wọn gbọrọ.

43

44“Ìwọ sì gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìjà àwọn ènìyàn mi, ìwọ pá mí mọ́ ki èmi lè ṣe olórí àwọn àjèjì orílẹ̀-èdè. Àwọn ènìyàn tí èmi kòì tí mọ̀ yóò máa sìn mí.

45Àwọn àlejò wá láti tẹríba fún mi; bí wọ́n bá ti gbúròó mi, wọn á sì gbọ́ tèmi.

46Àyà yóò pá àwọn àlejò, wọn ó sì fi ìbẹ̀rù sá kúrò níbi kọ́lọ́fín wọn.

46

47“OLÚWA ń bẹ́; olùbùkún sì ni àpáta mi! Gbígbéga sì ni Ọlọ́run àpáta ìgbàlà mi.

48Ọlọ́run ni ẹni tí ń gbẹ̀san mi, àti ẹni tí ń rẹ àwọn ènìyàn sílẹ̀ lábẹ́ mi.

49Àti ẹni tí ó gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀ta mi. Ìwọ sì gbé mi sókè ju àwọn tí ó dìde sí mi lọ; ìwọ sì gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọkùnrin oníwà ipá.

50ⓑ Nítorí náà èmi ó fi ọpẹ́ fún ọ, OLÚWA, láàrin àwọn àjèjì orílẹ̀-èdè: èmi ó sì kọrin sí orúkọ rẹ.

51Òun ni ilé-ìṣọ́ ìgbàlà fún ọba rẹ̀; ó sì fi àánú hàn fún ẹni-àmì-òróró rẹ̀, fún Dáfídì, àti fún irú-ọmọ rẹ̀ títí láéláé.”

cle>