Ìwé Sámúẹ́lì Kejì 3:1-39 BYB2014 - Bible AI

1Ogun náà sì pẹ́ títí láàrin ìdílé Ṣọ́ọ̀lù àti ìdílé Dáfídì: agbára Dáfídì sì ń pọ̀ si i, ṣùgbọ́n ìdílé Ṣọ́ọ̀lù ń rẹ̀yìn si i.

2ⓐ Dáfídì sì bí ọmọkùnrin ní Hébírónì: Ámónì ni àkọ́bí rẹ̀ tí Áhínóámù ará Jésírẹ́lì bí fún un.

3Èkéjì rẹ̀ sì ni Kíléábù, tí Ábígáílì àya Nábálì ará Kárímẹ́lì;

3bí fún un ẹ̀kẹta sì ni Ábúsálómù ọmọ tí Máákà ọmọbìnrin Tálímáì ọba Gésúrì bí fún un.

4Ẹ̀kẹ́rin sì ni Àdóníjà ọmọ Hágítì;

4àti ìkarún ni Séfátíà ọmọ Ábítalì;

5Ẹ̀kẹfà sì ni Ítíréámù, tí Égílà àya Dáfídì bí fún un.

5Wọ̀nyí ni a bí fún Dáfídì ni Hébúrónì.

6Ó sì ṣe, nígbà tí ogun wà láàárin ìdílé Ṣọ́ọ̀lù àti ìdílé Dáfídì, Ábínérì sì dì alágbára ní ìdílé Ṣọ́ọ̀lù.

7Ṣọ́ọ̀lù ti ní àlè kan, orúkọ rẹ̀ sì ń jẹ́ Rísípà, ọmọbínrin Áíyà: Íṣíbóṣétì sì bi Ábínérì léèrè pé, “Èéṣe tí ìwọ fi wọlé tọ àlè baba mi lọ.”

8Ábínérì sì bínú gidigidi nítorí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ti Iṣibósẹ́tì sọ fún un, ó sì wí pé, “Èmi jẹ́ bí orí ajá ti Júdà bí? Di òní yìí ni mọ ṣàáánú fún ìdílé Ṣọ́ọ̀lù bàbá rẹ, àti fún àwọn arákùnrin rẹ̀, àti fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, tí èmi kò sì fi ọ́ lé Dáfídì lọ́wọ́, ìwọ sì kà ẹ̀ṣẹ̀ sí mí lọ́rùn nítorí obìnrin yìí lóní?

9Bẹ́ẹ̀ ni kí Ọlọ́run ó ṣe Ábínérì, àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú, bí OLÚWA ti búra fún Dáfídì, bí èmi kò ní ṣe bẹ́ẹ̀ fún un.

10Láti mú ìjọba náà kúrò ní ìdílé Ṣọ́ọ̀lù, àti láti gbé ìtẹ́ Dáfídì kalẹ̀ lorí Ísírẹ́lì, àti lórí Júdà, láti Dánì títí ó fi dé Bíáṣébà!”

11Òun kò sì lè dá Ábínérì lóhùn kan nítorí tí ó bẹ̀rù rẹ̀.

12Ábínérì sì rán àwọn oníṣẹ́ sí Dáfídì nítorí rẹ̀ wí pé, “Ti ta ni ilẹ̀ náà ń ṣe? Bá mi ṣe àdéhùn, èmi yóò si kó gbogbo Ísírẹ́lì tọ̀ ọ́ wá.”

13Òun sì wí pé, “Ó dárá, èmi ó bá ọ ṣe àdéhùn: ṣùgbọ́n ohun kan ni èmi ó béèrè lọ́wọ́ rẹ, èyí ni pé, ìwọ kì yóò rí ojú mi, àfi bí ìwọ bá kọ́ mú Míkálì ọmọbìnrin Ṣọ́ọ̀lù wá, nígbà tí ìwọ bá wá, láti rí ojú mi.”

14Dáfídì sì rán àwọn ìránṣẹ sí Iṣíbóṣétì ọmọ Ṣọ́ọ̀lù pé, “Fi Míkálì obìnrin mi lé mi lọ́wọ́, ẹni tí èmi ti fi ọgọ́rún atoro àwọn Fílístínì fẹ́.”

15Íṣíbóṣétì sì ránṣẹ́, ó sì gbà á lọ́wọ́ ọkùnrin tí a ń pè ní Fálítíélì ọmọ Láíṣì.

16Ọkọ rẹ̀ sì ń bà a lọ, ó ń rìn, ó sì ń sunkún lẹ́yìn rẹ̀ títí ó fi dé Báhúrímù Ábínérì sì wí fún un pé, “Padà sẹ́yìn!” Òun sì padà.

17Ábínérì sì bá àwọn àgbà Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀ pé, “Ẹ̀yin ti ń ṣe àfẹ́rí Dáfídì ní ìgbà àtijọ́, láti jọba lórí yín.

18Ǹjẹ́, ẹ ṣe: nítorí tí OLÚWA ti sọ fún Dáfídì pé, ‘Láti ọwọ́ Dáfídì ìránṣẹ mi lémi ó gba Isíraẹ́lì ènìyàn mi là kúrò lọ́wọ́ àwọn Fílístínì àti lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀taa wọn.’ ”

19Ábínérì sì sọ̀rọ̀ létí Béńjámẹ́nì: Ábínérì sì lọ sọ létí Dáfídì ní Hébírónì, gbogbo èyí tí ó dára lójú Ísírẹ́lì, àti lójú gbogbo ilé Béńjámíní.

20Ábínérì sì tọ Dáfídì wá ní Hébírónì, ogún ọmọkùnrin sì lọ pẹ̀lú rẹ̀ Dáfídì sì se àsè fún Ábínérì àti fún àwọn ọmọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀.

21Ábínérì sì wí fún Dáfídì pé, “Èmi ó dìde, èmi ó sì lọ, èmi ó sì kó gbogbo Ísírẹ́lì jọ sọ́dọ̀ ọba OLÚWA mi, wọn ó sì báa ṣe àdéhùn, ìwọ ó sì jọba gbogbo wọn bí ọkàn rẹ ti ń fẹ́.” Dáfídì sì rán Ábínérì lọ; òun sì lọ ní àlàáfíà.

22Sì wò ó, àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì àti Jóábù sì ti ibi ìlépa ẹgbẹ́ ogun kan bọ̀, wọ́n sì mú ìkógún púpọ̀ bọ̀; ṣùgbọ́n Ábínérì kò sí lọ́dọ̀ Dáfídì ní Hébírónì; nítorí tí òun ti rán an lọ: òun sì ti lọ ní Àlàáfíà.

23Nígbà tí Jóábù àti gbogbo ogun tí ó pẹ̀lú rẹ̀ sì dé, wọ́n sì sọ fún Jóábù pé Ábínérì, ọmọ Nérì ti tọ ọba wá, òun sì ti rán an lọ, ó sì ti lọ ní àlàáfíà.

24Jóábù sì tọ ọba wá, ó sì sọ pé, “Kí ni ìwọ ṣe yìí? Wò ó, Ábínérì tọ̀ ọ́ wá; èé ha ti ṣe tí ìwọ sì fi rán an lọ? Òun sì ti lọ.

25Ìwọ mọ Ábínérì ọmọ Nérì, pé ó wá láti tàn ọ́ jẹ ni, àti láti mọ ìjáde lọ rẹ, àti wíwọlé rẹ́ àti láti mọ gbogbo èyí tí ìwọ ń ṣe.”

26Nígbà tí Jóábù sì jáde kúrò lọ́dọ̀ Dáfídì, ó sì rán àwọn ìránṣẹ́ láti lépa Ábínérì, wọ́n sì pè é padà láti ibi kànga Sírà: Dáfídì kò sì mọ̀.

27Ábínérì sì padà sí Hébírónì, Jóabù sì bá a tẹ̀ láàrin ojú ọ̀nà láti bá a sọ̀rọ̀ ní àlàáfíà, ó sì gún un níbẹ̀ lábẹ́ inú, ó sì kú, nítorí ẹ̀jẹ̀ Ásáhẹ́lì arákùnrin rẹ̀.

28Lẹ́yìn ìgbà tí Dáfídì sì gbọ́ ọ ó sì wí pé, “Èmi àti ìjọba mi sì jẹ́ aláìlẹ́bi níwájú OLÚWA títí láé ní ti ẹ̀jẹ̀ Ábínérì ọmọ Nérì:

29Jẹ́ kí ó wà ní orí Jóabù, àti ní orí gbogbo ìdílé baba rẹ̀; kí a má sì fẹ́ ẹni ó tí ní àrùn ìṣun, tàbí adẹ́tẹ̀, tàbí ẹni tí ń tẹ ọ̀pá, tàbí ẹni tí a ó fi ìdà pa, tàbí ẹni tí ó ṣe aláìní oúnjẹ kù ní ilé Jóábù.”

30(Jóábù àti Ábíṣáì arákùnrin rẹ̀ sì pa Ábínérì, nítorí pé òun ti pa Áṣáhélì arákùnrin wọn ní Gíbíónì ní ogun.)

31Dáfídì sì wí fún Jóábù àti fún gbogbo ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ fa aṣọ yín ya, kí ẹ̀yin sì mú aṣọ-ọ̀fọ̀, kí ẹ̀yín sì sunkún níwájú Ábínérì.” Dáfídì ọba tìkararẹ̀ sì tẹ̀lẹ́ pósí rẹ̀.

32Wọ́n sì sin Ábínérì ní Hébírónì: ọba sì gbé ohùn rẹ̀ sókè, ó sì sunkùn ní ibojì Ábínérì; gbogbo àwọn ènìyàn náà sì sunkún.

33Ọba sì sọkún lórí Ábínérì, ó sì wí pé, “Ǹjẹ́ Ábínérì; yẹ kí ó kú bí aṣiwèrè?

34A kò sáà dè ọ́ lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kò kan ẹsẹ̀ rẹ ní àbà. Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí ń ṣubú níwájú àwọn ìkà ènìyàn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ ṣubú.” Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì tún sọkún lórí rẹ̀.

35Nígbà tí gbogbo ènìyàn sì wá láti gba Dáfídì ní ìyànjú kí ó jẹun, nígbà tí ọjọ́ sì ń bẹ, Dáfídì sì búra wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni kí Ọlọ́run ó ṣe sí mi àti jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí èmi yóò bá tọ́ ounjẹ wò, tàbí nǹkan mìíràn títí òòrùn yóò fi wọ̀!”

36Gbogbo àwọn ènìyàn sì kíyèsí i, ó sì dára lójú wọn: gbogbo èyí tí ọba ṣe sì dára lójú gbogbo àwọn ènìyàn náà.

37Gbogbo àwọn ènìyàn náà àti gbogbo Ísírẹ́lì sì mọ̀ lọ́jọ́ náà pé, kì í ṣe ìfẹ́ ọba láti pa Ábínérì ọmọ Nérì.

38Ọba sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin kò mọ̀ pé olórí àti ẹni-ńlá kan ni ó ṣubú lónìí ní Ísírẹ́lì.

39Èmi sì ṣe aláìlágbára lónìí, bí ó tílẹ̀ jẹ́ pé a fi èmi jọba; àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ọmọ Saerúíà sì le jù mí lọ: OLÚWA ni yóò san án fún ẹni tí ó ṣe ibi gẹ́gẹ́ bí ìwà búburú rẹ̀!”

le>