1
2Dáfídì sì dìde, ó sì lọ àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ń bẹ́ lọ́dọ̀ rẹ́, láti Báálà Júdà wá, láti mú àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run tí ibẹ̀ wá, èyí tí a ń pe orúkọ rẹ̀ ní orúkọ OLÚWA àwọn ọmọ-ogun tí ó jókòó láàrin àwọn kérúbù.
3Wọ́n sì gbé àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run náà gun kẹ̀kẹ́ tuntun kan, wọ́n sì mú un láti ilé Ábínádábù wá, èyí tí ó wà ní Gíbéà: Úsà àti Áhíò, àwọn ọmọ Ábínádábù sì ń dá kẹ̀kẹ́ tuntun náà.
4Wọ́n sì mú un láti ilé Ábínádábù jáde wá, tí ó wà ní Gíbéà, pẹ̀lú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run: Áhíò sì ń rìn níwájú àpótí-ẹ̀rí náà.
5Dáfídì àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì sì ṣiré níwájú OLÚWA lára gbogbo onírúurúu èlò orin àti ìlù háàpù, ní ara tanborí, sisitirumù àti kíńbálì.
6Nígbà tí wọ́n sì dé ibi ìpakà Nákónì, Úsà sì na ọwọ́ rẹ̀ sí àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run, ó sì dì í mú, nítorí tí màlúù kọsẹ̀.
7Ibínú OLÚWA sì ru sí Úsà; Ọlọ́run sì pa á níbẹ̀ nítorí ìṣìṣe rẹ̀; níbẹ̀ ni ó sì kù ní ẹ̀bá àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run.
8Inú Dáfídì sì bàjẹ́ nítorí tí OLÚWA gé Úsà kúrò: ó sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Peresí-Úsà títí ó fi di òní yìí.
9Dáfídì sì bẹ̀rù OLÚWA ní ijọ́ náà, ó sì wí pé, “Àpótí-ẹ̀rí OLÚWA yóò ti ṣe tọ̀ mí wá?”
10Dáfídì kò sì fẹ́ mú àpótí-ẹ̀rí OLÚWA sọ́dọ̀ rẹ̀ sí ìlú Dáfídì; ṣùgbọ́n Dáfídì sì mú un yà sí ilé Obedì-Édómù ará Gátì.
11Àpótí-ẹ̀rí OLÚWA sì gbé ní ilé Obedì-Édómù ará Gátì ní oṣù mẹ́ta; OLÚWA sì bùkún fún Obedì-Édómù, àti gbogbo ilé rẹ̀.
12
13Ó sì ṣe nígbà tí àwọn ènìyàn tí ó ru àpótí-ẹ̀rí OLÚWA bá sì ṣí ẹsẹ̀ mẹ́fà, òun a sì fi màlúù àti ẹran àbọ́pa rúbọ.
14Dáfídì sì fi gbogbo agbára rẹ̀ jó níwájú OLÚWA; Dáfídì sì wọ éfódù ọ̀gbọ̀.
15Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì sì gbé àpótí-ẹ̀rí OLÚWA gòkè wá, pẹ̀lú ìhó ayọ̀, àti pẹ̀lú ìró ìpè.
16Bí àpótí-ẹ̀rí OLÚWA sì ti wọ ìlú Dáfídì wá; Mikali ọmọbìnrin Ṣọ́ọ̀lù sì wo láti ojú fèrèsé, ó sì rí Dáfídì ọba ń fò sòkè ó sì ń jó níwájú OLÚWA; òun sì kẹ́gàn rẹ̀ ní ọkàn rẹ̀.
17Wọ́n sì mú àpótí-ẹ̀rí OLÚWA náà wá, wọ́n sì gbé e kalẹ̀ sípò rẹ̀ láàrin àgọ́ náà tí Dáfídì pa fún un: Dáfídì sì rubọ́ sísun àti ẹbọ ìrẹ́pọ̀ níwájú OLÚWA.
18Dáfídì sì parí ìṣe ẹbọ sísun àti ẹbọ ìrẹ́pọ̀ náà, ó sì súre fún àwọn ènìyàn náà ní orúkọ OLÚWA àwọn ọmọ-ogun.
19Ó sì pín fún gbogbo àwọn ènìyàn náà, àní fún gbogbo ọ̀pọ̀ ènìyàn Ísírẹ́lì, àti ọkùnrin àti obìnrin; fún olúkúlùkù ìṣù àkàrà kan àti èkìrí ẹran kan, àti àkàrà díndín kan. Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì túká lọ, olúkúlùkù sí ilé rẹ̀.
20Dáfídì sì yípadà láti súre fún àwọn ará ilé rẹ̀, Míkálì ọmọbìnrin Ṣọ́ọ̀lù sì jáde láti wá pàdé Dáfídì, ó sì wí pé, “Báwo ni ọba Ísírẹ́lì ṣe ṣe ara rẹ̀ lógo bẹ́ẹ̀ lónìí, tí ó bọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ lónìí lójú àwọn ìránṣẹ́bìnrin àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn lásán tí ń bọ́ra rẹ̀ sílẹ̀.”
21Dáfídì sì wí fún Míkálì pé, “Níwájú OLÚWA ni, ẹni tí ó yàn mí fẹ́ ju baba rẹ lọ, àti ju gbogbo ìdílé rẹ lọ, láti fi èmi ṣe olórí àwọn ènìyàn OLÚWA, àní lórí Ísírẹ́lì, èmi ó sì ṣúre níwájú OLÚWA.
22Èmi ó sì tún rẹ ara mi sílẹ̀ jú bẹ́ẹ̀ lọ, èmi ó sì ṣe aláìnìyín lójú ara mi, àti lójú àwọn ìránṣẹ́bìnrin náà ti ìwọ wí, lọ́dọ̀ wọn náà ni èmi ó sì ní ògo.”
23Míkálì ọmọbìnrin Ṣọ́ọ̀lù kò sì bí ọmọ, títí o fi di ọjọ́ ikú rẹ̀ nítorí tí ó sọ̀rọ̀ òdì yìí sí Dáfídì.