1
2Ó sì kọlu Móábù, ó sì fi okùn títa kan dìwọ́n, ó sì dá wọn dùbúlẹ̀; ó sì ṣe òṣùwọ̀n okùn méjì ni iye àwọn tí yóò dá sí. Àwọn ará Móábù sì ń sin Dáfídì, wọn a sì máa mú ẹ̀bùn wá.
3Dáfídì sì kọlu Hadadésérì ọmọ Rehóbù, ọba Sóbà, bí òun sì ti ń lọ láti mú agbára rẹ̀ bọ̀ sípò ni odò Éfúrétì.
4Dáfídì sì gba ẹgbẹ̀rún kẹ̀kẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, àti ẹ̀ẹ́dẹ̀gbẹ̀rin ẹlẹ́ṣin, àti ẹgbàawá àwọn ẹlẹ́sẹ̀: Dáfídì sì já gbogbo àwọn ẹṣin kẹ̀kẹ́ wọn ní pátì, ṣùgbọ́n ó dá ọgọ́rún kẹ̀kẹ́ sí nínú wọn.
5Nígbà tí àwọn ará Síríà ti Dámásíkù sì wá láti ran Hadadésérì ọba Sóbà lọ́wọ́, Dáfídì sì pa ẹgbàámọ́kànlá ènìyàn nínú àwọn ará Síríà.
6Dáfídì sì fi àwọn ológún sí Síríà ti Dámásíkù: àwọn ará Síríà sì wá sin Dáfídì, wọn a sì máa mú ẹ̀bùn wá, OLÚWA sì pa Dáfídì mọ́ níbikíbi tí o ń lọ.
7Dáfídì sì gba àṣà wúrà tí ó wà lára àwọn ìránṣẹ Hadadésérì, ó sì kó wọn wá sí Jérúsálẹ́mù.
8Láti Bétà, àti láti Bérótáì, àwọn ìlú Hadadésérì, ni Dáfídì ọba sì kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ baba wá.
9Nígbà tí Tóù ọba Hámátì sì gbọ́ pé Dáfídì ti pa gbogbo ogun Hadadésérì.
10Tóì sì rán Jórámù ọmọ rẹ̀ sí Dáfídì ọba, láti kí i, àti láti súre fún un, nítorí pé ó tí bá Hadadésérì jagun, ó sì ti pa á: nítorí tí Hadadésérì sáà ti bá Tóù jagun. Jórámù sì ni ohun èlò fàdákà, àti ohun èlò wúrà, àti ohun èlò idẹ ní ọwọ́ rẹ̀.
11Dáfídì ọba sì fi wọ́n fún OLÚWA pẹ̀lú fàdákà, àti wúrà tí ó yà sí mímọ́, èyí tí ó ti gbà lọ́wọ́ àwọn orilẹ̀-èdè tí ó ti ṣẹ́gun.
12Lọ́wọ́ Síría àti lọ́wọ́ Móábù àti lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ámónì, àti lọ́wọ́ àwọn Fílístínì, àti lọ́wọ́ Ámálékì, àti nínú ìkógun Hadadésérì ọmọ Réhóbù ọba Sóbà.
13Dáfídì sì ní òkìkí gidigidi nígbà tí ó padà wá ilé láti ibi pípa àwọn ará Síríà ní àfonífojì iyọ̀, àwọn tí o pa jẹ́ ẹgbaàsán ènìyàn.
14Ó sì fi àwọn ológun sí Édómù; àti ní gbogbo Édómù yíká ni òun sì fi ológun sí, gbogbo àwọn tí ó wà ní Édómù sì wá sin Dáfídì, OLÚWA sì fún Dáfídì ní ìṣẹgún níbikíbi tí ó ń lọ.
15
16Jóábù ọmọ Sérúyà ni ó sì ń ṣe olórí ogun; Jéhóṣáfátì ọmọ Áhílúdì sì ń ṣe akọ̀wé.
17Sádókù ọmọ Áhítúbì, àti Áhímélékì ọmọ Ábíátarì, ni àwọn àlùfáà; Sérúyà a sì máa ṣe akọ̀wé.
18Bénáyà ọmọ Jéhóíádà ni ó sì ń ṣe olórí àwọn Kérétì, àti àwọn Pélétì; àwọn ọmọ Dáfídì sì jẹ́ aláṣẹ.