Ìwé Tímótíù Kìn-ín-ní 1:1-20 BYB2014 - Bible AI

1Pọ́ọ̀lù, àpósítélì Kírísítì Jésù gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Ọlọ́run Olùgbàlà wa, àti Jésù Kírísítì ìrètí wa.

2Sí Tímótíù ọmọ mi nínú ìgbàgbọ́: Oore-ọ̀fẹ́, àánú àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run baba àti Jésù Kírísítì Olúwa wa.

3Bí mo se rọ̀yín nígbàtí mò ń lọ sí Makedóníà, ẹ dúró ní Éfésù, kí ẹ lè dá àwọn ènìyàn kan lẹ́kun láti má ṣe kọ́ ni ní ẹ̀kọ́ èké mọ́

4kí wọ́n má sì ṣe fiyèsí àwọn ìtàn-asán, àti ìtàn-ìran aláìlópin. Irú èyí máa ń mú iyàn jíjà wá dípò iṣẹ́ ìríjú Ọlọ́run èyí tí í ṣe ti ìgbàgbọ́.

5Ète àṣẹ náà ni ìfẹ́ ti ń jáde wá láti inú ọkàn mímọ́ àti ẹ̀rí-ọkàn rere àti ìgbàgbọ́ àìṣẹ̀tàn.

6Àwọn ẹlòmíràn ti yapa kúrò tí wọ́n sì yà sápákan sí ọ̀rọ̀ asán.

7Wọ́n ń fẹ́ ṣe olùkọ́ òfin; òye ohun tí wọ́n ń wí kò yé wọn tàbí ti ohun tí wọ́n ń fi ìgboyà tẹnumọ́.

8Ṣùgbọ́n àwa mọ̀ pé òfin dára, bí ènìyàn bá lò ó dáradára.

9Bí a ti mọ̀ pé, a kò ṣe òfin fún olódodo, bí kò ṣe fún àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, fún àwọn aláìmọ́ àti àwọn ẹlẹ́gàn, fún àwọn tí ń pa baba àti àwọn tí ń pa ìyá àti àwọn apànìyàn,

10fún àwọn àgbèrè, fún àwọn aláyídà, fún àwọn onísòwò-ẹrú, fún àwọn èké, fún àwọn abúra èké, àti bí ohun mìíràn bá wà tí ó lòdì sí ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro.

11Gẹ́gẹ́ bí ìyìn rere ti ògo Ọlọ́run olùbùkún, tí a fi sí ìtọ́jú mi.

12Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ẹni tí ó fún mi ní agbára, àní Kírísítì Jésù Olúwa wa, nítorí tí ó kà mí sí olóòótọ́ ní yíyànmí sí iṣẹ́ rẹ̀;

13Bí mo tilẹ̀ jẹ́ asọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run rí, àti onínúnibíni àti ìkà ènìyàn: ṣùgbọ́n mo rí àánú gbà, nítorí tí mo ṣe é nínú àìmọ̀ àti àìgbàgbọ́.

14Oore-ọ̀fẹ́ Olúwa wa sì pọ̀ rékọjá pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́, tí ń bẹ nínú Kírísítì Jésù.

15Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà, ó sì yẹ fún ìtẹ́wọ́gbà, pé Jésù Kírísítì wá sí ayé láti gba ẹlẹ́sẹ̀ là; nínú àwọn ẹni tí èmi jẹ́ búburú jùlọ.

16Ṣùgbọ́n nítorí èyí ni mo ṣe rí àánú gbà, pé lára mi, bí olórí ẹlẹ́sẹ̀ ni kí Jésù Kírísítì fi gbogbo ìpamọ́ra rẹ̀ hàn bí àpẹẹrẹ fún àwọn tí yóò gbà á gbọ́ sí ìyè àìnípẹ̀kun ìkẹyìn.

17Ǹjẹ́ fún Ọba ayérayé, àìdíbàjẹ́, àìrí, Ọlọ́run kan ṣoṣo, ni ọlá àti ògo wà fún láéláé. Àmín.

18Àṣẹ yìí ni mo pa fún ọ, Tímótíù ọmọ mi, gẹ́gẹ́ bí ìsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí tó ó ti ṣáájú nípa rẹ̀, pé nípaṣẹ̀ wọ́n kí ìwọ lè máa ja ìjà rere;

19Máa ní ìgbàgbọ́ àti ẹ̀rí-ọkàn rere. Àwọn ẹlòmíràn tanù lọ́dọ̀ wọn tí wọ́n sì rí ọkàn ìgbàgbọ́ wọn;

20Nínú àwọn ẹni tí Híménéù àti Alẹkisáńdérù wà; àwọn tí mo ti fi lé Sàtánì lọ́wọ́, kí a lè kọ́ wọn kí wọn má sọ̀rọ̀-òdì mọ́.

rticle>