1Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà, bí ẹnìkan bá fẹ́ ipò Bíṣọ́ọ̀bù, iṣẹ́ rere ni ó ń fẹ́,
2Ǹjẹ́ Bíṣọ́ọ̀bù yẹ kí ó jẹ́ aláìlẹ́gàn, ọkọ aya kan, olùsọ̀ràn, aláìrékọjá, oníwà yíyẹ, olùfẹ́ àlejò ṣíṣe, ẹni tí ó lè ṣe olùkọ́.
3Kí ó má jẹ́ ọ̀mùtí, tàbí alu-ni, tàbí olójúkòkòrò, bí kò ṣe onísùúrù, kí ó má jẹ́ oníjà, tàbí olùfẹ́ owó.
4Ẹni tí ó káwọ́ ilé ara rẹ̀ gírígírí, tí ó mú àwọn ọmọ rẹ̀ tẹríba pẹ̀lú ìwà àgbà gbogbo;
5Ṣùgbọ́n bí ènìyàn kò bá mọ̀ bí a ti ń ṣe ìkáwọ́ ilé ara rẹ̀, òun ó há ti ṣe lè tọ́jú ìjọ Ọlọ́run?
6Kí ó má jẹ́ ẹni titun ti ó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbàgbọ́, kí ó má baà gbéraga, a sì ṣubú sínú ẹ̀bi Èsù.
7Ó sì yẹ kí ó ni ẹ̀rí rere pẹ̀lú lọ́dọ̀ àwọn tí ń bẹ lóde; kí ó má baà bọ́ sínú ẹ̀gàn àti sínú ìdẹ́kun Èṣù.
8Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ó yẹ fún àwọn Díákónì láti ní ìwà àgbà, kí wọ́n máa jẹ́ ẹlẹ́nu méjì, kí wọ́n máa fi ara wọn fún wáìnì púpọ̀, kí wọ́n má jẹ́ olójúkòkòrò.
9Kí wọn máa di ohun ìjìnlẹ̀ ìgbàgbọ́ mú pẹ̀lú ọkàn funfun.
10Kí a kọ́kọ̀ wádìí àwọn wọ̀nyí dájú pẹ̀lú; nígbà náà ni kí a jẹ́ kí wọn ó ṣiṣẹ́ díákónì, bí wọn bá jẹ́ aláìlẹ́gàn.
11Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ó yẹ fún àwọn obìnrin láti ni ìwá àgbà, kí wọn má jẹ́ asọ̀rọ̀-ẹni-lẹ́yìn bí kò ṣe aláìrékọjá, olóòótọ́ ní ohun gbogbo.
12Kí àwọn díákónì jẹ́ ọkọ obìnrin kan, kí wọn káwọ́ àwọn ọmọ àti ilé ara wọn dáradára.
13Nítorí àwọn tí ó lo ipò díákónì dáradára ra ipò rere fún ara wọn, àti ìgboyà púpọ̀ nínú ìgbàgbọ́ tí ń bẹ nínú Kírísítì Jésù.
14Ìwé nǹkan wọ̀nyí ni mo kọ sí ọ, mo sì ń réti àti tọ̀ ọ́ wá ní lọ́ọ́lọ́ọ́.
15Ṣùgbọ́n bí mo bá pẹ́, kí ìwọ lè mọ̀ bí ó ti yẹ fún àwọn ènìyàn láti máa hùwà nínú ilé Ọlọ́run, tì í ṣe ìjọ Ọlọ́run, alààyè, ọ̀wọ́n àti ìpìlẹ̀ òtítọ́.
16Láìṣiyè méjì, títóbi ní ohun ìjìnlẹ̀ ìwà-bí-Ọlọ́run: