Ìwé Tímótíù Kejì 2:1-26 BYB2014 - Bible AI

1NÍTORÍ náà ìwọ ọmọ mi, jẹ́ alágbára nínú oore-ọ̀fẹ́ ti ń bẹ nínú Kírísítì Jésù.

2Àwọn ohun ti ìwọ ti gbọ́ lọ́dọ̀ mi níwájú ẹlẹ́rìí púpọ̀, àwọn náà ni kí ìwọ fi lé àwọn olóòótọ́ ènìyàn lọ́wọ́, àwọn ti yóò lè máa kọ́ àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.

3Ṣe alábàápín pẹ̀lú mi nínú ìpọ́njú, bí ọmọ-ogun rere Jésù Kírísítì.

4Kò sí ẹni tí ń jagun ti ń fi ohun ayé yìí dí ara rẹ̀ lọ́wọ́, kí ó lè mú inú ẹni tí ó yàn ni ọmọ-ogun dùn.

5Ní ọ̀nà kán náà, bí ẹnìkẹ́ni bá sì ń dije bí olùdíje, a kì í dé e ládé, bí kò ṣe bí ó bá parí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà

6Àgbẹ̀ ti ó ń ṣe làálàá ni ó yẹ láti kọ́kọ́ mu nínú àwọn èso.

7Ronú lórí ohun ti èmi ń sọ; nítorí Olúwa yóò fún ọ lóye nínú ohun gbogbo.

8Rántí Jésù Kírísítì, ti ó jíǹde kúrò nínú òkú, láti inú irú-ọmọ Dáfídì gẹ́gẹ́ bí ìyìn rere mi.

9Nínú èyí tí èmi ń rí ìpọ́njú títí dé inú ìdè bí arúfin; ṣùgbọ́n a kò de ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

10Nítorí náà mo ń faradà ohun gbogbo nítorí àwọn àyànfẹ́; kí àwọn náà pẹ̀lú lè ní ìgbàlà tí ń bẹ nínú Kírísítì Jésù pẹ̀lú ògo ayérayé.

11Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà: Bi àwa bá bá a kú, àwa yóò yè pẹ̀lú rẹ̀.

12Bí àwa bá faradà, àwa ó sì bá a jọba: Bí àwa bá sẹ́ ẹ, òun náà yóò sì sẹ́ wa.

13Bí àwa kò bá gbàgbọ́, òun dúró ni olóòótọ́: Nítorí òun kò lè sẹ ara rẹ̀.

14Nǹkan wọ̀nyí ni ki ó máa rán wọn létí. Máa kìlọ̀ò fún wọn níwajú Olúwa pé, ki wọn ó yẹra kúrò nínú jíjiyàn ọ̀rọ̀ tí kò léèrè, bí kò ṣe ìparun fún àwọn tí ń gbọ́.

15Ṣaápọn láti fi ara rẹ̀ hàn níwájú Ọlọ́run bi ẹni tí ó yege àti òṣìṣẹ́ tí kò níláti tijú, tí ó ń pin ọ̀rọ̀ òtítọ́ bí ó ti yẹ

16Yà kúrò nínú ọ̀rọ̀ asán, nítorí ti wọn máa ṣíwájú nínú àìwà-bí-Ọlọ́run.

17Ọ̀rọ̀ wọn yóò sì máa fẹ́ bí egbò kíkẹ̀; nínú àwọn ẹni tí Híménéù àti Fílétù wà;

18Àwọn ẹni tí ó ti sìnà kúrò nínú òtítọ́, tí ń wí pé àjíǹde ti kọjá ná; tí wọ́n sì ń bi ìgbàgbọ́ àwọn mìíràn ṣubú.

19ⓐ Ṣùgbọ́n ìpìlẹ̀ Ọlọ́run tí ó dájú dúró ṣinṣin, ó ní èdìdì yìí, pé, “Olúwa mọ àwọn tí í ṣe tirẹ̀.” Àti pẹ̀lú, “Kí olúkúlùkù ẹni tí ń pé orúkọ Olúwa kúró nínú àìṣòdodo.”

20Ṣùgbọ́n nínú ilé nla, kì í ṣe kìkì ohun-èlò wúrà àti ti fàdákà nìkan ni ń bẹ, ṣùgbọ́n ti igi àti amọ̀ pẹ̀lú; àti òmíràn sí ọlá, àti òmíràn sí àìlọ́lá.

21Bí ẹnìkẹni bá wẹ ara rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ìwọ̀nyí, òun yóò jẹ́ ohun-èlò sí ọlá, tí a yà sọ́tọ̀, tí ó sì yẹ fún ìlò baálé, tí a sì ti pèsè sílẹ̀ fún iṣẹ́ rere gbogbo.

22Máa sá fún ìfẹ́kùfẹ̀ẹ́ èwe: sì máa lépa òdodo, ìgbàgbọ́, ìfẹ́, àlàáfíà, pẹ̀lú àwọn tí ń ké pe Olúwa láti inú ọkàn funfun wá.

23Ìbéèrè òmùgọ̀ àti aláìní èkọ́ nínú ni kí a kọ̀, bí a ti mọ̀ pe wọn a máa dá ìjà sílẹ̀.

24Ìránsẹ́, Olúwa kò sì gbọdọ̀ jà; bí kò ṣe kí ó jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ sí ènìyàn gbogbo ẹni tí ó lè kọ́ni, onísùúrù.

25Ẹni tí yóò máa kọ́ àwọn alátakò pẹ̀lú ìwà tútù, ní ìrèti pé Ọlọ́run lè fún wọn ní ìrònúpìwàdà sí ìmọ̀ òtìtọ́,

26wọn ó sì lè bọ́ kúrò nínú ìdèkùn èṣù, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti mú wọn láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀.

e>