Ìwé Tímótíù Kejì 4:1-22 BYB2014 - Bible AI

1Nítorí náà mo pàṣẹ fún ọ níwájú Ọlọ́run, àti Kírísítì Jésù, ẹni tí yóò ṣe ìdájọ́ alààyè àti òkú, àti nítorí ìfarahàn rẹ̀ àti ìjọba rẹ̀.

2Wàásù ọ̀rọ̀ náà, ṣe àìsinmi ní àkókò tí ó wọ̀, àti àkókò ti kò wọ̀; bániwí, ṣe ìtọ́ni, gbani níyànjú pẹ̀lú ìpamọ́ra àti ẹ̀kọ́ gbogbo.

3Nítorí pé ìgbà yóò dé, tí wọn kì yóò lè gba ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro, ṣùgbọ́n bí wọ́n ti jẹ́ ẹni tí etí ń rin, wọn ó lọ kó oluko jọ fún ara wọn nínú ìfẹ́kùfẹ́ ara wọn.

4Wọ́n ó sì yí etí wọn padà kúrò nínú òtítọ́, wọn ó sì yípadà sí ìtàn asán.

5Ṣùgbọ́n máa faradà ìpọ́nju, ṣe iṣẹ́ ẹ̀fáńjẹ́lísítì, ṣe iṣẹ́ rẹ láṣepé.

6Nitorí à ń fí mi rúbọ nisínsinyìí, àtilọ mi sì súnmọ́ etíle.

7Èmi ti ja ìjà rere, èmi tí parí iré-ìje mi, èmi ti pa ìgbàgbọ́ mọ́;

8Láti ìsinsinyìí lọ a fi adé òdodo lélẹ̀ fún mi, tí Olúwa onídàjọ́ òdodo, yóò fífún mi ni ọjọ́ náà kì í sì í ṣe kìkì èmi nìkan ṣùgbọ́n pẹ̀lú fún gbogbo àwọn tí ó ti fẹ́ ìfarahàn rẹ̀.

9Sa ipá rẹ láti tètè tọ̀ mí wá.

10ⓐ  Nítorí Démà ti kọ̀ mí sílẹ̀, nitorí ó ń fẹ́ ayé yìí, ó sì lọ sí Tẹsalóníkà; Kírésíkénì sí Gálátíà, Títù sí Dalimátíà.

11Lúùkù nìkan ni ó wà pẹ̀lú mi, mú Máàkù wá pẹ̀lú rẹ: nítorí ó wúlò fún mi fún iṣẹ́-ìránṣẹ́.

12Mo rán Tíkíkù ní iṣẹ lọ sí Éfésù.

13Aṣọ òtútù tí mọ fi sílẹ̀ ní Tíróà lọ́dọ̀ Kárípù, nígbà tí ìwọ bá ń bọ̀ mu un wa, àti àwọn ìwé, pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ìwé-awọ.

14Alekisáńdérù alágbẹ̀dẹ bàbà ṣe mi ni ibi púpọ̀: Olúwa yóò san án fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀:

15Lọ́dọ̀ ẹni tí kí ìwọ máa ṣọ́ra pẹ̀lú, nítorí tí ó kọ ojú ìjà sí ìwàásù wa púpọ̀.

16Ní àkọ́kọ́ jẹ́ ẹjọ́ mi, kò sí ẹni tí ó ba mi gba ẹjọ́ rò ṣùgbọ́n gbogbo ènìyàn ni o kọ̀ mi sílẹ̀: Àdúrà mi ni kí a má ṣe ká à sí wọn lọ́rùn.

17Ṣùgbọ́n Olúwa gba ẹjọ́ mi rò, ó sì fún mi lágbára; pé nipasẹ̀ mi kí a lè wàásù náà ní àwàjálẹ̀, àti pé kí gbogbo àwọn aláìkọlà lè gbọ́; a sì gbà mí kúrò lẹ́nu kìnìún náà.

18Olúwa yóò yọ mí kúrò nínú iṣẹ́ bubúrú gbogbo, yóò sì gbà mí dé inú ìjọba rẹ̀; ẹni ti ògo wà fún láé àti láéláé. (Àmín).

19Kí Parísíkà àti Àkúílà, àti ilé Onésífórù.

20Érásítù wà ní Kọ́ríntí: ṣùgbọ́n mo fi Tírófímù sílẹ̀ ni Mílétù nínú àìsàn.

21Sa ipá rẹ láti tètè wá ṣáájú ìgbà òtútù. Éúbúlù kí ọ, àti Páúdánì, àti Línù, Kíláúdíà, àti gbogbo àwọn ará-kùnrin.

22Kí Olúwa wà pẹ̀lú ẹ̀mí rẹ kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹ̀lú yín. (Àmín).

e>