1Ìran sí Júdà àti Jérúsálẹ́mù èyí tí Àìṣáyà ọmọ Ámọ́sì rí ní àsìkò ìjọba Hùṣáyà, Jótamù, Áhásì àti Heṣekáyà àwọn ọba Júdà.
2Gbọ́ ẹ̀yin ọ̀run! Fi etí sílẹ̀, ìwọ ayé!Nítorí OLÚWA ti sọrọ̀:“Mo tọ́ àwọn ọmọ dàgbà,Ṣùgbọ́n wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi.
3Màlúù mọ olówó rẹ̀,kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì mọ ibùjẹ olówó rẹ̀,ṣùgbọ́n Ísírẹ́lì kò mọ̀,òye kò yé àwọn ènìyàn mi.”
3
4Á à! Orílẹ̀-èdè ẹlẹ́ṣẹ̀,àwọn ènìyàn tí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ń pa lẹ́rù,Ìran àwọn aṣebi,àwọn ọmọ tó ti di aṣèbàjẹ́!Wọn ti kọ OLÚWA sílẹ̀wọn ti gan Ẹni-Mímọ́ Ísírẹ́lì,wọn sì ti kẹ̀yìn sí i.
4
5Èéṣe tí a ó fi tún lù yín mọ́?Èéṣe tí ẹ ò dẹ́kun ọ̀tẹ̀ ṣíṣe?Gbogbo orí yín jẹ́ kìkì ọgbẹ́,gbogbo ọkan yín sì ti pòrúúru.
6Láti àtẹ́lẹṣẹ̀ yín dé àtàrí yínkò sí àlàáfíà rárá,àyàfi ọgbẹ́ òun ìfarapaàti ojú egbò,tí a kò nùnù tàbí kí á dì tàbí kí a kùn ún ní òróró.
6
7Orílẹ̀-èdè yín dahoro,a dáná sun àwọn ìlú yín,oko yín ni àwọn àjèjì ti jẹ runlójú ara yín náà,ni gbogbo rẹ̀ ṣòfò bí èyí tíàwọn àjèjì borí rẹ̀.
8Ọmọbìnrin Ṣíónì ni a fi sílẹ̀gẹ́gẹ́ bí àtíbàbà nínú ọgbà àjàrà,gẹ́gẹ́ bí àbá nínú oko ẹ̀gúsí,àti bí ìlú tí a dótì.
9Àyàfi bí OLÚWA àwọn ọmọ-ogunbá sẹ́ díẹ̀ kù fún wà,a ò bá ti rí bí Sódómù,a ò bá sì ti dàbí Gòmórà.
9
10Gbọ́ ọ̀rọ̀ OLÚWA,ẹ̀yin aláṣẹ Sódómù,tẹ́tí sí òfin Ọlọ́run wa,ẹ̀yin ènìyàn Gòmórà!
11“Ọpọ̀lọpọ̀ ẹbọ yínkín ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹbọ yín jásí fún mi?” ni OLÚWA wí.“Mo ti ní ànító àti àníṣẹ́kù ẹbọ sísunti àgbò àti ọ̀rá ẹran àbọ́pa,Èmi kò ní inú dídùnnínú ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù, ti àgùntànàti ti orúkọ.
12Nígbà tí ẹ wá farahàn níwájú mi,ta ni ó bèèrè èyí lọ́wọ́ ọ yín,Gìrì gìrì ẹsẹ̀ nínú àgbàlá mi?
13Ẹ má mú ọrẹ aṣán wá mọ́!Ìríra ni tùràrí yín jásí fún mi,oṣù tuntun, ọjọ́ ọ̀sẹ̀ àti àwọn àpèjọÈmi kò lè faradà àpèjọ ibi yín wọ̀nyí.
14Ayẹyẹ oṣù tuntun yín àti àpèjẹtí ẹ yà ṣọ́tọ̀ni ọkàn mi kórìíra.Wọ́n ti di àjàgà sí mi ní ọrùn,Ó ti sú mi láti máa fara dà wọ́n.
15Nigbà tí ẹ bá tẹ́ ọwọ́ yín sóke ni àdúrà,Èmi yóò fi ojú mi pamọ́ fún un yín,kódà bí ẹ bá gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àdúrà,Èmi kò ni tẹ́ti sí i.Ọwọ́ yín kún fún ẹ̀jẹ̀.
16Wẹ̀ kí ẹ sì jẹ́ kí ara yín mọ́.Ẹ mú ìwà ibi yín kúrò níwájú mi!Dáwọ́ àìṣedéédéé dúró,
17kọ́ láti ṣe rere!Wá ìdájọ́ òtítọ́,tù àwọn tí a ń pọ́n lójú nínú.Ṣàtìlẹ́yìn fún ẹ̀tọ́ aláìní baba,gbà ẹjọ́ opó rò.
17
18“Ẹ wá ní ìsinsìnyìí, ẹ jẹ́ kí a jọ ṣàsàrò,”ni OLÚWA wí.“Bí ẹ̀ṣẹ̀ yín bá rí bí osùn,wọn ó sì funfun bí i yìnyín,bí wọn bá sì pọ́n bí ẹ̀jẹ̀,wọn ó sì dàbí ẹ̀gbọ̀n-òwú.
19Tí ó bá tinú un yín wá tí ẹ sì gbọ́ràn,ẹ̀yin yóò sì jẹ ojúlówó adùn ilẹ̀ náà.
20Ṣùgbọ́n tí ẹ bá kọ̀ tí ẹ sì ṣọ̀tẹ̀,idà ni a ó fi pa yín run.”Nítorí ẹnu OLÚWA la ti sọ ọ́.
20
21Wo bí ìlú òtítọ́ ṣe di àgbèrè!Ó ti kún fún ìdájọ́ òtítọ́ nígbà kan rí,òdodo ń gbé ibẹ̀ tẹ́lẹ̀ ríṣùgbọ́n báyìí o àwọn apànìyàn!
22Sílífà rẹ ti di ìpẹ́pẹ́,ààyò wáìnì rẹ la ti bomi là.
23Ọlọ̀tẹ̀ ni àwọn aláṣẹ yín,akẹgbẹ́ àwọn olè,gbogbo wọn ló fẹ́ràn àbẹ̀tẹ́lẹ̀wọ́n sì ń wá ẹ̀bùn kiri.Wọ́n kì í ṣàtìlẹyìn fún ẹ̀tọ́ aláìní baba,ẹjọ́ opó kì í sìí dé iwájú wọn.
24Nítorí náà ni OLÚWA, OLÚWA àwọn ọmọ-ogunAlágbára kanṣoṣo tí Ísírẹ́lì sọ wí pé:“Á à! Èmi yóò ní ìfọ̀kànbalẹ̀ lórí àwọn ọ̀tá min ó sì gbẹ̀ṣan lára àwọn ọ̀tá mi.
25Èmi yóò pa ọwọ́ mi dà sí ọ,èmi ó sì ku ìpẹ́pẹ́ rẹ dànù,n ó sì mú gbogbo ìdọ̀tí rẹ kúrò.
26Èmi yóò mú àwọn adájọ́ rẹ bọ̀sípò gẹ́gẹ́ bí i ti àtijọ́,àti àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀ bí i ti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀.Lẹ́yìn náà ni a ó pè ọ ní ìlú òdodo, ìlú òtítọ́.”
26
27A ó fi ìdájọ́ òtítọ́ ra Ṣíhónì padà,àti àwọn tí ó ronú pìwàdà pẹ̀lú òdodo.
28Ṣùgbọn àwọn ọlọ̀tẹ̀ àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni a ó pa runÀwọn tí ó bá sì kọ OLÚWA sílẹ̀ ni yóò ṣègbé.
28
29“Ojú yóò tì yín nítorí igi óákù mímọ́èyí tí ẹ ní inú dídùn sía ó kàn yín lábùkù nítorí àwọn ọgbà yìítí ẹ ti yàn fúnra yín.
30Ẹ ó sì dàbí igi óákù tí ewé rẹ̀ tí,tàbí bí ọgbà tí kò ní omi.
31Alágbára ọkùnrin náà yóò sì dàbí lẹ́ùiṣẹ́ rẹ̀ bí ẹ̀ṣẹ́-iná,àwọn méjèèjì ni yóò jóná papọ̀,láì sí ẹni tí yóò lè pa iná yìí.”