Ìwé Wòlíì Àìsáyà 10:1-34 BYB2014 - Bible AI

1Ègbé ni fún àwọn ti ń ṣe òfin àìṣòdodo

2láti dún àwọn aláìní ní ẹ̀tọ́ wọn àti láti fa ọwọ́ ìdájọ́ sẹ́yìn kúrò níwájú àwọn olùpọ́njú ènìyàn mi, wọ́n sọ àwọn ọ̀pọ̀ di ìjẹ fún wọn. Wọ́n sì ń ja àwọn aláìní lólè.

3Kí ni ìwọ yóò ṣe ní ọjọ́ ìṣirò nígbà tí ìparun bá ti ọ̀nà jínjìn wá? Ta ni ìwọ yóò sá tọ̀ fún ìrànlọ́wọ́? Níbo ni ìwọ yóò fi ọrọ̀ rẹ sí?

4Ohunkóhun kò ní ṣẹ́kù mọ́ bí kò ṣe láti tẹ̀ ba láàrin àwọn ìgbèkùn tàbí kí o ṣubú sáàrin àwọn tí a pa.

4Pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ìbínú rẹ̀ kò kúrò, ọwọ́ rẹ̀ sì tún gbé sókè.

5ⓐ “Ègbé ni fún àwọn ará Ásíríà, ọ̀gọ ìbínú mi, ní ọwọ́ ẹni tí kùmọ̀ ìbínú mi wà!

6Mo rán an sí orílẹ̀ èdè aláìní Ọlọ́run Mo dojúu rẹ̀ kọ àwọn ènìyàn tí ó múmi bínú láti já ẹrù gbà, àti láti kó ìkógun láti tẹ̀mọ́lẹ̀ bí amọ̀ ní ojú òpópó.

7Ṣùgbọ́n, èyí kì í ṣe ohun tí ó fẹ́ ṣe, èyí kọ́ ni ohun tí ó ní lọ́kàn; èrò rẹ̀ ni láti parun, láti fi òpin sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè.

8‘Kì í haá ṣe pé ọba ni gbogbo àwọn aláṣẹ mi?’ ni Olúwa wí.

9‘Kì í ha á ṣe pé Kálínò dàbí i Káṣẹ́míṣì? Hámátì kò ha dàbí i Ápádì, àti Ṣamáríà bí i Dámásíkù?

10Gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ mi ti gbá ìjọba àwọn òrìṣà mú, Ìjọba tí ère rẹ̀ pọ̀ ju ti Jérúsálẹ́mù àti Ṣamáríà lọ.

11Èmi kì yóò a bá Jérúsálẹ́mù wí àti àwọn ère rẹ̀?’ ” Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ṣe sí Ṣamáría àti àwọn ère rẹ̀?

12Nígbà tí OLÚWA bá parí iṣẹ́ rẹ̀ sí òkè Ṣíhónì àti Jérúsálẹ́mù, yóò sọ wí pé, “Èmi yóò fi ìyà jẹ Ásíríà nítoríi gààrù àyà rẹ̀ àti ìgbéraga ojúu rẹ̀.

13Nítorí ó sọ pé:

13“ ‘Pẹ̀lú agbára ọwọ́ọ̀ mi ni mo fi ṣe èyí àti pẹ̀lú ọgbọ́n ọ̀n mi, nítorí mo ní òye. Mo mú ààlà àwọn orílẹ̀ èdè kúrò, Mo sì ti kó ìṣúra wọn. Gẹ́gẹ́ bí alágbára kan, mo borí àwọn ọba wọn.

14Bí ènìyàn tií tọwọ́ bọ ìtẹ́ ẹyẹ, bẹ́ẹ̀ ni ọwọ́ọ̀ mi tẹ ọrọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè. Bí ènìyàn tii kó ẹyin tí a kọ̀ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni mo kó àwọn orílẹ̀ èdè kò sí èyí tí ó fapálupá, tàbí kí ó ya ẹnu láti dún.’ ”

14

15Ǹjẹ́ àáké le gbé ara rẹ̀ sókè kọjá ẹni tí ó ń fì í, tàbí kí ayùn fọnnu sí ẹni tí ó ń lò ó? Àfi bí ẹni pé ọ̀pá ó na ẹni tí ó gbé e sókè, tàbí kí kùmọ̀ lu èyí tí kì í ṣe igi.

16Nítorí náà, ni OLÚWA, OLÚWA àwọn ọmọ-ogun, yóò rán àrùn ìrẹ̀dànù sórí àwọn akíkanjú jagunjagun, lábẹ́ ògo rẹ̀ ni iná kan yóò ti sọ gẹ́gẹ́ bí iná ajónirun.

17Ìmọ́lẹ̀ Ísírẹ́lì yóò di iná, ẹni Mímọ́ an wọn ahọ́n iná, ní ijọ́ kan ṣoṣo yóò jó yóò sì run àti ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n.

18Gbogbo ẹwà igbóo rẹ̀, àti àwọn pápá ọlọ́ràá gbogbo rẹ̀ ni yóò run pátapáta, gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó sàìṣàn ti í ṣòfò dànù.

19Àwọn igi tí yóò kù nínú igbóo rẹ̀ yóò kéré níye, tí ọ̀dọ́mọdé yóò fi le kọ̀ wọ́n sílẹ̀.

20Ní ijọ́ náà, àwọn tí ó ṣẹ́kù ní Ísírẹ́lì Àwọn tí ó yè ní ilée Jákọ́bù kò ní gbẹ́kẹ̀lé ẹni náà tí ó lùwọ́n bolẹ̀ ṣùgbọ́n yóò gbẹ́kẹ̀lé OLÚWA Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.

21Àwọn ìyókù yóò padà, àwọn ìyókù ti Jákọ́bù yóò padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Alágbára.

22Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn an rẹ, ìwọ Ísírẹ́lì dàbí yanrìn ní òkun, ẹni díẹ̀ ni yóò padà. A ti pàṣẹ ìparun à kún wọ́ sílẹ̀ àti òdodo.

23OLÚWA, OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ni yóò mú-un ṣẹ, ìparun tí a ti pàṣẹ rẹ̀ lórí gbogbo ilẹ̀ náà.

24Nítorí náà, báyìí ni OLÚWA, OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí, “Ẹ̀yin ènìyàn mi tí ó ń gbé Ṣíhónì, Ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn Ásíríà, tí ó ń fi ọ̀pá lù yín, tí wọ́n sì ń gbé ọ̀gọ tìyín bí Éjíbítì ti ṣe.

25Láìpẹ́, ìbínú mi síi yín yóò wá sí òpin n ó sì dojú ìrunú mi kọ wọ́n, fún ìparun wọn.”

25

26OLÚWA àwọn ọmọ-ogun yóò nà wọ́n ní ẹgba. Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe lu Mídíánì ní òkè Órébù, yóò sì gbé ọ̀páa rẹ̀ lé orí omi gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ní Éjíbítì.

27Ní ọjọ́ náà, a ó gbé ẹrùu wọn kúrò ní èjìká a yín, àti àjàgà a wọn kúrò ní ọrùn un yín a ó fọ́ àjàgà náà, nítorí pé ẹ̀yin ó ti sanra.

27

28Wọ́n wọ Áíyátì, Wọ́n gba Mígírónì kọjá Wọ́n kó nǹkan pamọ́ sí Mísímásì.

29Wọ́n ti rékọjá ọ̀nà, wọ́n wí pé, “Àwa ó tẹ̀dó sí Gébà lóru yìí.” Rámà mì tìtì Gíbíà ti Ṣọ́ọ̀lù sá lọ.

30Kígbe ṣókè, ìwọ ọmọbìnrin Gálímù Dẹtísílẹ̀, Ìwọ Láíṣà Òpè Ánátótì.

31Mádíménà ti fẹṣẹ̀ fẹ́ ẹ Àwọn ènìyàn Gébímù ti farapamọ́.

32Ní ọjọ́ yìí, wọn yóò dúró ní Nóbù wọn yóò kan sáárá, ní òkè ọmọbìnrin Ṣíhónì ní òkè Jérúsálẹ́mù.

32

33Wò ó, OLÚWA, OLÚWA àwọn ọmọ-ogun, yóò kán ẹ̀ka náà sọnù pẹ̀lú agbára. Àwọn igi ọlọ́lá ni a ó gé lulẹ̀ Àwọn tí ó ga gogoro ni a ó rẹ̀ sílẹ̀.

34Òun yóò gé igbó dídí pẹ̀lú àáké, Lẹ́bánónì yóò ṣubú níwájú Alágbára náà.

le>