Ìwé Wòlíì Àìsáyà 11:1-16 BYB2014 - Bible AI

1ⓐ Èhíhù kan yóò sọ láti ibi kùkùté Jéésè, láti ara gbòǹgbò rẹ̀ ni ẹ̀ka kan yóò ti so èso.

2ⓑ Ẹ̀mí OLÚWA yóò sì bà lé e ẹ̀mí ọgbọ́n àti ti òye ẹ̀mí ìmọ̀ràn àti ti agbára ẹ̀mí ìmọ̀ àti ti ìbẹ̀rù OLÚWA

3Òun yóò sì ní inúdídùn nínú ìbẹ̀rù OLÚWA.

3Òun kì yóò ṣe ìdájọ́ pẹ̀lú ohun tí ó fi ojúu rẹ̀ rí, tàbí pẹ̀lú ohun tí ó fi etíi rẹ̀ gbọ́,

4Ṣùgbọ́n pẹ̀lú òdodo ni yóò ṣe ìdájọ́ àwọn aláìní, pẹ̀lú òtítọ́ ni yóò ṣe ìpinnu fún àwọn aláìní ayé. Òun yóò lu ayé pẹ̀lú ọ̀pá tí ó wà ní ẹnu rẹ̀, pẹ̀lú ooru ẹnu rẹ̀ ni yóò pa àwọn ìkà.

5ⓒ Òdodo ni yóò jẹ́ ìgbànú rẹ̀ àti òtítọ́ ni yóò ṣe ọ̀já yí ẹ̀gbẹ́ẹ rẹ̀ ká.

5

6ⓓ Ìkookò yóò sì máa bá ọmọ àgùntàn gbé, àmọ̀tẹ́kùn yóò sì sùn ti ewúrẹ́ ọmọ màlúù òun ọmọ kìnnìún àti ọmọ ẹran ó wà papọ̀ ọ̀dọ́mọdé yóò sì máa dà wọ́n.

7Màlúù àti béárì yóò máa jẹun pọ̀, àwọn ọmọ wọn yóò dùbúlẹ̀ pọ̀, kìnnìún yóò sì máa jẹ koríko gẹ́gẹ́ bí akọ màlúù.

8Ọ̀dọ́mọdé yóò ṣeré lẹ́bàá ihò ọká, Ọmọdé yóò ki ọwọ́ọ rẹ̀ bọ ìtẹ́ẹ paramọ́lẹ̀.

9Wọn kò ní ṣeni lọ́ṣẹ́ tàbí panirun ní gbogbo òkè mímọ́ mi, nítorí gbogbo ayé yóò kún fún ìmọ̀ OLÚWA gẹ́gẹ́ bí omi ti í bo òkun.

10ⓔ Ní ọjọ́ náà, gbòǹgbò Jéésè yóò dúró gẹ́gẹ́ bí àṣíá fún gbogbo ènìyàn, àwọn orílẹ̀ èdè yóò pagbo yí i ká, ibùdó ìsinmi rẹ̀ yóò jẹ́ èyí tí ó lógo.

11Ní ọjọ́ náà, OLÚWA yóò na ọwọ́ọ rẹ̀ jáde nígbà kejì láti tún gba àwọn tí ó ṣẹ́kù àní àwọn tí a ṣẹ́kù nínú àwọn ènìyàn an rẹ̀ láti Ásíríà wá, láti ìsàlẹ̀ Éjíbítì àti Òke Éjíbítì, láti Kúṣì, láti Élámù láti Babilóníà, láti Hámátì àti láti àwọn erékùṣù inú òkun.

12Òun yóò gbé àṣíá sókè fún àwọn orílẹ̀ èdè, yóò sì kó àwọn ìgbèkùn Ísírẹ́lì jọ, yóò kó gbogbo àwọn ènìyàn Júdà tí a ti fọ́n káàkiri jọ, láti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé.

13Owú jíjẹ Éfáímù yóò pòórá, àwọn ọ̀tá Júdà ni a ó ké kúrò, Éfáímù kò ní jowúu Júdà, tàbí Júdà kó dojú kọ Éfáímù.

14Wọn yóò dìgbòlu àwọn gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Fílísítíà ni apá ìwọ̀ oòrùn, wọn yóò pawọ́pọ̀ kọlu àwọn ènìyàn apá ìlà oòrùn. Wọn yóò gbé ọwọ́ọ wọn lé Édómù àti Móábù, àwọn ará Ámónì yóò sì di ìwẹ̀fàa wọn.

15OLÚWA yóò sọ di gbígbé àyasí òkun Éjíbítì, pẹ̀lú atẹ́gùn gbígbóná ni yóò na ọwọ́ọ rẹ̀, kọjá lórí odò Éúfírétì. Òun yóò sì sọ ọ́ di ọmọdò méje tó fi jẹ́ pé àwọn ènìyàn yóò máa là á kọjá pẹ̀lúu bàtà.

16Ọ̀nà gidi yóò wà fún àwọn ènìyàn an rẹ̀ tí ó ṣẹ́kù tí ó kù sílẹ̀ ní Ásíríà, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà fún Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n gòkè láti Éjíbítì wá.

le>