Ìwé Wòlíì Àìsáyà 12:1-6 BYB2014 - Bible AI

1Ní ọjọ́ náà ìwọ ó wí pé: “Èmi ó yìn ọ́, OLÚWA. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ò ti bínú sí mi ìbínú rẹ ti yí kúrò níbẹ̀ ìwọ sì ti tù mí nínú.

2Nítòótọ́ Ọlọ́run ni ìgbàlà mi, Èmi yóò gbẹ́kẹ̀lé e èmi kì yóò bẹ̀rù. OLÚWA, OLÚWA náà ni agbára à mi àti orin ìn mi, òun ti di ìgbàlà mi.”

3Pẹ̀lú ayọ̀ ni ìwọ yóò máa pọn omi láti inú un kànga ìgbàlà.

4Ní ọjọ́ náà, ìwọ yóò wí pé: “Fi ọpẹ́ fún OLÚWA, ké pe orúkọ rẹ̀, Jẹ́ kí ó di mímọ̀ láàrin àwọn orílẹ̀ èdè, ohun tí ó ti ṣe kí o sì kéde pé a ti gbé orúkọ rẹ̀ ga.

5Kọ orin sí OLÚWA, nítorí ó ti ṣe ohun tí ó lógo, jẹ́ kí èyí di mímọ̀ fún gbogbo ayé.

6Kígbe ṣókè kí o sì kọrin fún ayọ̀, ẹ̀yin ènìyàn Ṣíhónì, nítorí títóbi ni ẹni mímọ́ kanṣoṣo ti Ísírẹ́lì láàrin yín.”

e>