Ìwé Wòlíì Àìsáyà 14:1-32 BYB2014 - Bible AI

1OLÚWA yóò fi àánú hàn fún Jákọ́bù, yóò tún Ísírẹ́lì yàn lẹ́ẹ̀kan síi yóò sì fi ìdíi wọn kalẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn tìkálára wọn. Àwọn àjèjì yóò darapọ̀ mọ́ wọn, wọn yóò sì fọwọ́ṣowọ́pọ̀ pẹ̀lú ilée Jákọ́bù.

2Àwọn orílẹ̀ èdè yóò gbà wọ́n wọn yóò sì mú wọn wá sí àyèe wọn. Ilé Ísírẹ́lì yóò gba àwọn orílẹ̀ èdè gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin ní ilẹ̀ OLÚWA. Wọn yóò kó àwọn akónilẹ́rú wọn ní ìgbèkùn wọn yóò sì jọba lórí àwọn amúnisìn wọn.

3Ní ọjọ́ tí OLÚWA yóò fi ìtùra fún un yín kúrò nínú ìpọ́njú àti ìyà àti ìdè ìkà,

4ẹ ó sì fi ọ̀rọ̀ àbùkù yìí kan ọba Bábílónì pé: Báwo ni amúnisìn ṣe wá sí òpin! Báwo ni ìbínú rẹ̀ ṣe parí!

5OLÚWA ti dá ọ̀pá ìkà náà, ọ̀pá àwọn aláṣẹ,

6èyí tí ó ti lu àwọn ènìyàn bolẹ̀ pẹ̀lú ti kò dáwọ́ dúró, nínú ìrunú ni ó ṣẹ́gun àwọn orílẹ̀ èdè pẹ̀lú ìgbónára tí kò lópin.

7Gbogbo ilẹ̀ ni ó wà ní ìsinmi àti àlàáfíà, wọ́n bú sí orin.

8Pẹ̀lú pẹ̀lù àwọn igi Páínì àti àwọn igi kédárì ti Lẹ́bánónì ń yọ̀ lóríì rẹ ó wí pé, “Níwọ̀n bí a ti rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ báyìí, kò sí alagi tí yóò wá láti gé wa lulẹ̀.”

8

9Ibojì tí ó wà ní ìṣàlẹ̀ ni a ru sókè láti pàdé rẹ ní àpadàbọ̀ rẹ̀ ó ru ẹ̀mí àwọn tí ó ti lọ ṣókè láti wá kí ọ gbogbo àwọn tí ó jẹ́ olórí ní ayé ó mú kí wọn dìde lórí ìtẹ́ẹ wọn gbogbo àwọn tí ó jọba lórí àwọn orílẹ̀ èdè.

10Gbogbo wọn yóò dáhùn, wọn yóò wí fún ọ wí pé, “Ìwọ pẹ̀lú ti di aláìlera, gẹ́gẹ́ bí àwa pẹ̀lú ìwọ náà ti dàbí wa.”

11Gbogbo rẹ̀ ni ó di ìrẹ̀sílẹ̀ lọ sí ibojì, pẹ̀lú ariwo àwọn hápù rẹ, àwọn ìdin ni wọ́n fọ́nkálẹ̀ lábẹ́ rẹ àwọn ekòló sì ti bò ọ́ mọ́lẹ̀.

11

12Báwo ni ìwọ ṣe ṣubúlulẹ̀ láti ọ̀run wá, ìwọ ìràwọ̀ òwúrọ̀, ọmọ òwúrọ̀ náà! A ti sọ ọ́ sílẹ̀ sínú ayé Ìwọ tí o ti tẹ orí àwọn orílẹ̀ èdè ba rí!

13Ìwọ sọ nínú ọkàn rẹ pé, “Èmi yóò gòkè lọ sí ọ̀run; Èmi yóò gbé ìtẹ́ mi sókè ga ju àwọn ìràwọ̀ Ọlọ́run, Èmi yóò gúnwà ní orí òkè àpèjọ ní ṣónṣó orí òkè mímọ́.

14Èmi yóò gòkè lọ rékọjá àwọn àwọ̀sánmọ̀; Èmi yóò ṣe ara mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá ògo.”

15Ṣùgbọ́n a ti rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ wọ inú ibojì lọ lọ sí ìṣàlẹ̀ ọ̀gbun.

15

16Àwọn tí ó rí ọ yóò tẹjúmọ́ ọ, wọ́n ronú nípa àtubọ̀tán rẹ: “Ǹjẹ́ èyí ni ẹni tí ó mi ayé tìtì tí ó sì jẹ́ kí àwọn ilẹ̀ ọba wárìrì.

17Ẹni tí ó sọ ayé di aṣálẹ̀, tí ó dojú àwọn ìlú ńlá ńlá bolẹ̀ tí kò sì jẹ́ kí àwọn ìgbèkùn padà sílé?”

17

18Gbogbo àwọn ọba orílẹ̀ èdè ni a tẹ́ sílẹ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú ibojì tirẹ̀.

19Ṣùgbọ́n a jù ọ́ síta kúrò nínú ibojì gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka igi tí a kọ̀ sílẹ̀, àwọn tí a pa ni ó bò ọ́ mọ́lẹ̀, àwọn tí idà ti gún, àwọn tí ó ṣọ̀kalẹ̀ lọ sínú òkúta inú ọ̀gbun. Gẹ́gẹ́ bí òkú ó di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ ní abẹ́ àtẹ́lẹṣẹ̀,

20A kò ní sin ọ́ pẹ̀lúu wọn, nítorí pé o ti ba ilẹ̀ rẹ jẹ́ o sì ti pa àwọn ènìyàn rẹ.

20Ìran àwọn ìkà ni a kì yóò dárúkọ wọn mọ́.

21Tọ́jú ibìkan tí a ó ti pa àwọn ọmọkùnrin rẹ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńláa wọn, wọn kò gbọdọ̀ dìde láti jogún ilẹ̀ kí wọ́n sì bo orí ilẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìlúu wọn.

21

22“Èmi yóò dìde ṣókè sí wọn,” ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí. “Èmi yóò ké orúkọ rẹ̀ kúrò ní Bábílónì àti àwọn tí ó sálà, àwọn ọmọ àti ìran rẹ̀,” ni OLÚWA wí.

23“Èmi yóò yí i padà sí ibùgbé àwọn òwìwí àti sí irà; Èmi yóò fi ọwọ́ ìparun gbá a,” ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí.

24OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ti búra, “Gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣètò, bẹ́ẹ̀ ni yóò rí, àti bí mo ti pinnu, bẹ́ẹ̀ ni yóò sì dúró.

25Èmi yóò run Ásíríà ní ilẹ̀ mi, ní àwọn orí òkè mi ni èmi yóò ti rún un mọ́lẹ̀. Àjàgà rẹ̀ ni a ó mú kúrò lọ́rùn àwọn ènìyàn mi, ẹrù u rẹ̀ ni ó mú kúrò ní èjìkáa wọn.”

25

26Èyí ni ètò tí a pinnu rẹ̀ fún gbogbo ayé, èyí ni ọwọ́ tí a nà jáde káàkiri gbogbo orílẹ̀ èdè.

27Nítorí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ti pète, ta ni yóò sì ká a lọ́wọ́ kò? Ọwọ́ọ rẹ ti nà jáde, ta ni ó sì le è fà á padà?

28Ọ̀rọ̀ ìmọ̀ yí wá ní ọdún tí ọba Áhásì kú:

29ⓐ Má ṣe yọ̀, gbogbo ẹ̀yin Fílístínì, pé ọ̀pá tí ó lù ọ́ ti dá; láti ibi gbòngbò ejò náà ni pamọ́lẹ̀ yóò ti hù jáde, èṣo rẹ̀ yóò sì jẹ́ oró ejò tíí jóni.

30Ẹni tí ó kúṣẹ̀ẹ́ jù yóò ní pápá oko, àwọn aláìní yóò sì dùbúlẹ̀ láìléwu. Ṣùgbọ́n gbòǹgbòo rẹ ni èmi ó fi ìyàn parun, yóò sì ké àwọn ẹni rẹ tí ó sálà kúrò.

30

31Kígbe, Ìwọ ẹnu ọ̀nà! Pariwo, Ìwọ ìlú! Yọ́ kúrò, gbogbo ẹ̀yin Fílístínì! Kurukuru èéfín kan ti Àríwá wá, kò sì sí amóríbọ́ kan nínú ẹgbẹ́ wọn.

32Kí ni ìdáhùn tí a ó fún agbẹnusọ orílẹ̀ èdè náà? “OLÚWA ti fi ìdí Ṣíhónì kalẹ̀, àti nínú un rẹ̀ ni àwọn ènìyàn rẹ̀ tí a ti pọ́nlójú yóò ti rí ààbò o wọn.”

le>