Ìwé Wòlíì Àìsáyà 15:1-9 BYB2014 - Bible AI

1ⓐ Ọ̀rọ̀ ìmọ̀ tí ó kan Móábù: A pa Árì run ní Móábù, òru kan kí a paárun! A pa Kárì run ní Móábù, òru kan kí a paárun!

2Díbónì gòkè lọ sí tẹ́ḿpìlìi rẹ̀, sí àwọn ibi gíga rẹ̀ láti ṣunkún, Móábù pohùnréré lórí Nébónì àti Médíbà. Gbogbo orí ni a fá gbogbo irungbọ̀n ni a gé dànù.

3Wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀ ní ojú òpópónà, ní àwọn òrùlé àti àwọn gbàgede àkójọ wọ́n pohùnréré, Wọ́n dọ̀bálẹ̀ pẹ̀lú ẹkún.

4Hẹ́ṣíbónì àti Élíálè ké ṣóde, ohùn wọn ni a gbọ́ títí fi dé Jáhásì. Nítorí náà ni àwọn ọmọ ogun Móábù ṣe kígbe tí ọkàn wọn sì rẹ̀wẹ́sì.

4

5Ọkàn mi kígbe lórí Móábù; àwọn ìṣáǹṣá rẹ sálà títí dé Ṣóárì, títí fi dé Égílátì Ṣẹ́líṣíyà. Wọ́n gòkè lọ títí dé Lúhítì wọ́n ń ṣunkún bí wọ́n ti ń lọ, Ní òpópónà tí ó lọ sí Hórónáímù wọ́n ń pohùnréré ìparun wọn

6Gbogbo omi Nímírímù ni ó ti gbẹ àwọn koríko sì ti gbẹ, gbogbo ewéko ti tán ewé tútù kankan kò sí mọ́.

7Báyìí gbogbo ọrọ̀ tí wọ́n ti ní tí wọ́n sì tòjọ wọ́n ti kó wọn kọjá lọ lóríi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ odò pópúlárì.

8Gbohùngbohùn ń gba igbe wọn dé ìpẹ̀kun ilẹ̀ Móábù; ìpohùnréré wọn lọ títí dé Ẹgíláémù, igbe ẹkún wọn ni a gbọ́ títí dé kànga Élímù.

9Omi Dímónì kún fún ẹ̀jẹ̀, ṣíbẹ̀ èmi ó tún mu ohun tí ó jù báyìí lọ wá sórí Dímónì— kìnnìún kan wá ṣórí àwọn ìṣáǹṣá Móábù àti lórí àwọn tí ó tún ṣẹ́kù sórí ilẹ̀ náà.

e>