Ìwé Wòlíì Àìsáyà 16:1-14 BYB2014 - Bible AI

1Fi ọ̀dọ́-àgùntàn ṣe ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí aláṣẹ ilẹ̀ náà, Láti Ṣẹ́là, kọjá ní ihà, lọ sí orí òkè ọ̀dọ́mọbìnrin Ṣíhónì.

2Gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ ẹ̀rẹ̀ǹbalẹ̀ tí a tì jáde kúrò nínú ìtẹ́, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwọn obìnrin Móábù ní àwọn ọmọdo Ánónì.

2

3“Fún wa ní ìmọ̀ràn ṣe ìpinnu fún wa. Jẹ́ kí òjìji rẹ dàbí òru— ní ọ̀sán gangan. Fi àwọn ìsáǹsá pamọ́, má ṣe tú àwọn aṣàtìpó fó

4Jẹ́ kí àwọn ìsáǹsá Móábù gbé pẹ̀lúù rẹ, jẹ́ ààbò fún wọn kúrò lọ́wọ́ ìparun.”

4Aninilára yóò wá sí òpin, ìparun yóò dáwọ́; òfinràn yóò pòórá kúrò lórí ilẹ̀.

5Nínú ìfẹ́ a ó fi ìdí ìjọba kan múlẹ̀, ní òdodo ọkùnrin kan yóò jókòó lóríi rẹ̀— ọ̀kan láti ilé Dáfídì wá. Ẹni nní ti ìdájọ́ ń wá ẹ̀tọ́ tí ó sì fi ìyára wá ohun tí í ṣe òdodo.

5

6Àwa ti gbọ́ nípa ìgbéraga Móábù— Wábiwọ́sí ìgbéraga rẹ̀ àti fùlenge fùlenge, gààrùu rẹ̀ àti àfojúdi rẹ̀— ṣùgbọ́n ìfọ́nnu rẹ̀ jẹ́ ìmúlẹ̀mófo.

7Nítorí náà ni àwọn ará Móábù pohùnréré wọ́n jùmọ̀ pohùnréré lórí Móábù. Ṣunkún kí o sì banújẹ́ fún àwọn ọkùnrin ìlú Hárésétì.

8Gbogbo pápá-oko Héṣíbónì ti gbẹ, bákan náà ni àjàrà Ṣíbínà rí. Àwọn aláṣẹ àwọn orílẹ̀ èdè wọ́n tẹ àwọn àyànfẹ́ àjàrà mọ́lẹ̀, èyí tí ó ti fà dé Jáṣérì ó sì ti tàn dé agbègbè aṣálẹ̀. Àwọn èhu rẹ̀ fọ́n jáde ó sì lọ títí ó fi dé òkun.

9Nítorí náà mo ṣunkún, gẹ́gẹ́ bí Jáṣérì ṣe ṣunkún, fún àwọn àjàrà Ṣíbínà. Ìwọ Hẹ́ṣíbónì, Ìwọ Élíálẹ̀, mo bomirin ọ́ pẹ̀lú omi ojú! Igbe ayọ̀ lórí àwọn èṣo pípọ́n rẹ àti lórí ìkóórè èyí tí o ti mọ́wọ́dúró.

10Ayọ̀ àti ìdùnnú ni a ti mú kúrò nínú ọgbà-igi eléso rẹ; kò sí ẹnìkan tí ó kọrin tàbí kígbe nínu ọgbà-àjàrà: ẹnikẹ́ni kò fún ọtí níbi ìfúntí, nítorí mo ti fi òpin sí gbogbo igbe.

11Ọkàn mi kérora fún Móábù gẹ́gẹ́ bí i hápù, àní tọkàntọkàn mi fún ìlú Háréṣétì.

12Nígbà tí Móábù farahàn ní ibi gíga rẹ̀, ó ṣe ara rẹ̀ ní wàhálà lásán; Nígbà tí ó lọ sí ojúbọ rẹ̀ láti gbàdúrà òfo ni ó já sí.

13Èyí ni ọ̀rọ̀ tí OLÚWA ti sọ nípa Móábù.

14Ṣùgbọn ní àkókò yìí OLÚWA wí pé: “Láàrin ọdún mẹ́ta gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀fà tí ó wà lábẹ́ ìdè ọgbà rẹ̀ ti máa kà á, Ògo Móábù àti àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn rẹ̀ ni a ó kẹ́gàn, àwọn tí ó ṣálà nínú un rẹ̀ yóò kéré níye, wọn yóò sì jẹ́ akúrẹtẹ̀.”

le>