Ìwé Wòlíì Àìsáyà 17:1-14 BYB2014 - Bible AI

1ⓐ Ọ̀rọ̀ ìmọ̀ tí ó kan Dámásíkù: “Kíyèsíí, Dámásíkù kò ní jẹ́ ìlú mọ́ ṣùgbọ́n yóò padà di ààtàn.

2Àwọn ìlú Áróérì ni a ó kọ̀ sílẹ̀ fún àwọn agbo ẹran tí yóò máa sùn ṣíbẹ̀, láìsí ẹni tí yóò dẹ́rùbà wọ́n.

3Ìlú olódi ni yóò pòórá kúrò ní Éfáímù, àti agbára ọba kúrò ní Dámásíkù; àwọn àsẹ́ku Árámù yóò dá gẹ́gẹ́ bí ògo ti àwọn Ísírẹ́lì,” ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí.

3

4“Ní ọjọ́ náà ni ògo Jákọ́bù yóò ṣá; ọ̀rá ara rẹ̀ yóò ṣòfò dànù.

5Yóò sì dàbí ìgbà tí olùkóórè kó àwọn irúgbìn tí ó dúró jọ tí ó sì ń kórè irúgbìn pẹ̀lú apá rẹ̀— àti gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí ènìyàn pa ọkà ní àfonífojì ti Réfémù.

6Ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀ irúgbìn díẹ̀ yóò ṣẹ́kù, gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí a gbọn igi ólífì, tí èṣo ólífì méjì tàbí mẹ́ta ṣẹ́kù sórí ẹ̀ka tí ó ga jùlọ, mẹ́rin tàbí márùn ún lórí ẹ̀ka tí ó so jù,” ni OLÚWA wí, àní Ọlọ́run Ísírẹ́lì.

6

7Ní ọjọ́ náà, àwọn ènìyàn yóò gbójúsókè sí Ẹlẹ́dàá wọn wọn yóò sì síjú wo Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.

8Wọn kò ní wo àwọn pẹpẹ mọ́, èyí tí í ṣe iṣẹ́ ọwọ́ọ wọn, wọn kò sì ní kọbi ara sí òpó Áṣérà mọ́ tàbí pẹpẹ tùràrí tí ìka ọwọ́ wọn ti ṣe.

9Ní ọjọ́ náà àwọn ìlú alágbára wọn, tí wọ́n fi sílẹ̀ nítorí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, yóò dàbí ilẹ̀ tí a dà sílẹ̀ kó di ìgbòrò. Gbogbo wọn yóò sì di ahoro.

10Ẹ ti gbàgbé Ọlọ́run Olùgbàlà yín; ẹ kò sì rántí àpáta náà, àní odi agbára yín.

11Nítorí náà, bí ẹ tilẹ̀ mú àsàyàn igi tí ẹ sì gbin àjàrà tí ó ti òkèrè wá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ tí ẹ kó wọn jáde ẹ mú wọn hú jáde, àti ní òwúrọ̀ tí ẹ gbìn wọ́n ẹ mú kí wọ́n rúdí, ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀ ìkóórè kò ní mú nǹkan wá ní ọjọ́ àrùn àti ìrora tí kò gbóògùn.

11

12Kíyèsii, ìrunú àwọn orílẹ̀ èdè— wọ́n ń runú bí ìgbì òkun! Kíyèsii, rògbòdìyàn tí ogunlọ́gọ̀ ènìyàn wọ́n bú ramúramù gẹ́gẹ́ bí ariwo odò ńlá!

13Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn ń bú ramúramù gẹ́gẹ́ bí ìrúmi odò, nígbà tí ó bá wọn wí wọ́n ṣálọ jìnnà réré, a tì wọ́n lọ gẹ́gẹ́ bí ìyàngbò ní orí òkè, àti gẹ́gẹ́ bí ewéko níwájú ìjì líle.

14Ní ihà, ìpayà òjijì! Kí ó tó di òwúrọ̀, a ò rí wọn mọ́! Èyí ni ìpín àwọn tí ó jí wa lẹ́rù, àti ìpín àwọn tí ó fi ogun kó wa.

le>