Ìwé Wòlíì Àìsáyà 18:1-7 BYB2014 - Bible AI

1ⓐ Ègbé ni fún ìwọ ilẹ̀ tí ó kún fún ariwo ìyẹ́, ní àwọn ipadò Kúṣì,

2tí ó rán àwọn ikọ̀ lórí òkun lórí omi nínú ọkọ̀-ọpọ́n tí a fi kóríko ṣe.

2Ẹ lọ, ẹ̀yin ikọ̀ tí ó yára, sí àwọn ènìyàn gíga tí àwọ̀-ara wọn jọ̀lọ̀, sí àwọn ènìyàn tí a ń bẹ̀rù káàkiri, orílẹ̀ èdè aláfojúdi alájèjì èdè, tí odò pín ilẹ̀ rẹ̀ yẹ́lẹyẹ̀lẹ.

3Gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ayé, tí ó ń gbé orílẹ̀ ayé, nígbà tí a bá gbé àṣíá kan ṣókè lórí òkè, ẹ ó rí i, nígbà tí a bá fun fèrè kan ẹ ó gbọ́ ọ.

4Èyí ni ohun tí OLÚWA sọ fún mi: “Èmi yóò dákẹ́ jẹ́ ẹ́, n ó sì máa wo òréré láti ibùgbé e mi wá, gẹ́gẹ́ bí ooru gbígbóná nínú ìtànsán òòrùn, gẹ́gẹ́ bí òjò-dídì ní àárin gbùngbùn ìkóórè.”

5Nítorí, kí ìkóórè tó bẹ̀rẹ̀, nígbà tí ìtànná kò sí mọ́, nígbà tí ìtànná di èso tí ó ń pọ́n bọ̀. Òun yóò sì fi ọ̀bẹ ìwẹgi gé àwọ ìsó tuntun kúrò, yóò sì gé àwọn ẹ̀ka tí ó ń gbilẹ̀ lulẹ̀ a sì kó wọn dànù.

6Gbogbo wọn la ó fi lé àwọn jẹran jẹran ẹyẹ lọ́wọ́ lórí òkè àti fún àwọn ẹranko búburú; àwọn ẹyẹ yóò fi wọ́n ṣoúnjẹ nínú ẹ̀ẹ̀rùn àti àwọn ẹranko búburú nígbà òjò.

7Ní àkókò náà ni a ó mú ẹ̀bùn wá fún OLÚWA àwọn ọmọ-ogun láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn gíga tí ẹran ara wọn jọ̀lọ̀, láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí a bẹ̀rù níbi gbogbo, orílẹ̀ èdè aláfojúdi àti alájèjì èdè, ilẹ̀ ẹni tí omi pín sí yẹ́lẹyẹ̀lẹ— a ó mú àwọn ẹ̀bùn náà wá sí òkè Síónì, ibi tí orúkọ OLÚWA àwọn ọmọ-ogun gbé wà.

e>