Ìwé Wòlíì Àìsáyà 19:1-25 BYB2014 - Bible AI

1ⓐ Ọ̀rọ̀ ìmọ̀ tí ó kan Éjíbítì: Kíyèsíi, OLÚWA gun àwọsánmọ̀ tí ó yára lẹ́sin ó sì ń bọ̀ wá sí Éjíbítì. Àwọn ère òrìṣà Éjíbítì wárìrì níwájúu rẹ̀, ọkàn àwọn ará Éjíbítì sì ti domi nínú un wọn.

2“Èmi yóò rú àwọn ará Éjíbítì sókè sí ara wọn arákùnrin yóò bá arákùnrin rẹ̀ jà, aládúgbò yóò dìde sí aládúgbò rẹ̀, ìlú yóò dìde sí ìlú, ilẹ̀ ọba sí ilẹ̀ ọba.

3Àwọn ará Éjíbítì yóò sọ ìrètí nù, èmi yóò sì sọ èrò wọn gbogbo di òfo; wọn yóò bá àwọn òrìṣà àti ẹ̀mí àwọn òkú sọ̀rọ̀, àwọn awoṣẹ́ àti àwọn abókúsọ̀rọ̀.

4Èmi yóò fi Éjíbítì lé agbára àwọn ìkà amúnisìn lọ́wọ́, ọba aláìláàánú ni yóò jọba lé wọn lórí,” ni OLÚWA, OLÚWA Alágbára wí.

4

5Gbogbo omi inú odò ni yóò gbẹ, gbogbo ilẹ̀ odò ni yóò gbẹ tí yóò sì sáàpá.

6Àyasí omi yóò máa rùn; àwọn odò ilẹ̀ Éjíbítì yóò máa dínkù wọn yóò sì gbẹ. Àwọn koríko odò àti ìrẹ̀tẹ̀ yóò gbẹ,

7àwọn igi ìpadò Náì pẹ̀lú, tí ó wà ní oríṣun odò Náì. Gbogbo oko tí a dá sí ìpadò Náì yóò gbẹ dànù tí yóò sì fẹ́ dànù tí kò sì ní sí mọ́.

8Àwọn apẹja yóò ṣunkún kíkorò, gbogbo àwọn tí ó ń ju ìwọ̀ sínú Náí; yóò sì máa rùn.

9Àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ọ̀gbọ̀ yóò kọminú àwọn ahunsọ ọ̀gbọ̀ yóò sọ ìrètí nù.

10Àwọn tí ń ṣiṣẹ́ aṣọ yóò rẹ̀wẹ̀sì, gbogbo àwọn oníṣẹ́ oṣù ni àìṣàn ọkàn yóò ṣe.

10

11Àwọn oníṣẹ́ Ṣóánì ti di aláìgbọ́n, àwọn ọlọgbọ́n olùdámọ̀ràn Fáráò ń mú ìmọ̀ràn àìgbọ́n wá. Báwo ló ṣe lè sọ fún Fáráò pé, “Mo jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àwọn ọba ijọ́un.”

11

12Níbo ni àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn rẹ wà báyìí? Jẹ́ kí wọn fi hàn ọ́ kí wọn sì sọ ọ́ di mímọ̀ ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ti pinnu lórí Éjíbítì.

13Àwọn oníṣẹ́ Ṣóárì ti di aláìgbọ́n, a ti tan àwọn adarí Méḿfísì jẹ; àwọn òkúta igunlé tí í ṣe ti ènìyàn rẹ ti ṣi Éjíbítì lọ́nà.

14OLÚWA ti da ẹ̀mí òòyì sínú un wọn; wọ́n mú Éjíbítì ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n nínú ohun gbogbo tí ó ń ṣe, gẹ́gẹ́ bí ọ̀mùtí ti í ta gbọ̀n-ọ́ngbọ̀n-ọ́n nínú èébì i rẹ̀.

15Kò sí ohun tí Éjíbítì le ṣe— orí tàbí ìrù, ọ̀wá ọ̀pẹ tàbí koríko odò.

16Ní ọjọ́ náà ni àwọn ará Éjíbítì yóò dàbí obìnrin. Wọn yóò gbọ̀n jìnnìjìnnì pẹ̀lú ẹ̀rù nítorí ọwọ́ OLÚWA àwọn ọmọ-ogun tí a gbé sókè sí wọn.

17Ilẹ̀ Júdà yóò da wárìwàrì jó àwọn ará Éjíbítì; gbogbo àwọn tí a bá ti dárúkọ Júdà létíi wọn ni yóò wárìrì, nítorí ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun gbérò láti ṣe sí wọn.

18Ní ọjọ́ náà ìlú márùn ún ní ilẹ̀ Éjíbítì yóò sọ èdè àwọn ará Kénánì, wọn yóò sì búra àtìlẹyìn fún OLÚWA àwọn ọmọ-ogun. Ọ̀kan nínú wọn ni a ó sì máa pè ní ìlú ìparun.

19Ní ọjọ́ náà pẹpẹ kan yóò wà fún OLÚWA ní àárin gbùngbùn Éjíbítì, àti ọ̀wọ̀n kan fún OLÚWA ní etí bodè rẹ̀.

20Yóò sì jẹ́ ààmì àti ẹ̀rí sí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ní ilẹ̀ Éjíbítì. Nígbà tí wọ́n bá ké pe OLÚWA nítorí àwọn aninilára wọn, yóò rán olùgbàlà àti olùgbéjà kan sí wọn tí yóò sì gbà wọ́n sílẹ̀.

21Báyìí ni OLÚWA yóò sọ ara rẹ̀ di mímọ̀ fún àwọn ará Éjíbítì àti ní ọjọ́ náà ni wọn yóò gba OLÚWA gbọ́. Wọn yóò sìn ín pẹ̀lú ẹbọ ọrẹ oníhóró, wọn yóò jẹ́jẹ̀ẹ́ fún OLÚWA wọn yóò sì mú un ṣẹ.

22OLÚWA yóò fi àjàkálẹ̀-àrùn kan bá Éjíbítì jà; yóò bá wọn jà yóò sì tún wò wọ́n sàn. Wọn yóò yípadà sí OLÚWA, Òun yóò sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn yóò sì wò wọ́n sàn.

23Ní ọjọ́ náà òpópónà kan yóò wá láti Éjíbítì lọ sí Ásíríà. Àwọn ará Ásíríà yóò lọ sí Éjíbítì àti àwọn ará Éjíbítì lọ sí Ásíríà. Àwọn ará Éjíbítì àti ará Ásíríà yóò jọ́sìn papọ̀.

24Ní ọjọ́ náà Ísírẹ́lì yóò di ẹ̀kẹta pẹ̀lú Éjíbítì àti Áṣíríà, àní oríṣun ìbùkún ní ilẹ̀ ayé.

25OLÚWA àwọn ọmọ-ogun yóò bùkún wọn yóò wí pé, “Ìbùkún ni fún Éjíbítì ènìyàn mi, Áṣíríà iṣẹ́ ọwọ́ mi, àti Ísírẹ́lì ìní mi.”

le>