Ìwé Wòlíì Àìsáyà 23:1-18 BYB2014 - Bible AI

1ⓐ Ọ̀rọ̀ ìmọ̀ tí ó kan Tírè: Pohùnréré, ìwọ ọkọ̀-ojú omi Táṣíṣì! Nítorí a ti pa Tírè run láìsí ilé tàbí èbúté. Láti ilẹ̀ Ṣáípúrọ́sì ni ọ̀rọ̀ ti wá sọ́dọ̀ wọn.

2Dákẹ́ jẹ́ẹ́, ẹ̀yin ènìyàn erékùṣù àti ẹ̀yin oníṣòwò ti Sídónì, ẹ̀yin tí àwọn awẹ̀kun ti sọ dọlọ́rọ̀.

3Láti orí àwọn omi ńlá ni irúgbìn oníhóró ti ilẹ̀ Ṣíhórì ti wá ìkóórè ti Náì ni owóòná Tírè, òun sì ti di ibùjókòó ọjà fún àwọn orílẹ̀ èdè.

3

4Kí ojú kí ó tì ọ́, ìwọ Ṣídónì àti ìwọ àní ìwọ ilé-ààbò ti òkun, nítorí òkun ti sọ̀rọ̀: “Èmi kò tí ì wà ní ipò ìrọbí tàbí ìbímọ rí Èmi kò tí ì wọ àwọn ọmọkùnrin tàbí kí n tọ́ àwọn ọmọbìnrin dàgbà rí.”

5Nígbà tí ọ̀rọ̀ bá dé Éjíbítì, wọn yóò wà ní ìpayínkeke nípa ìròyìn láti Tírè.

5

6Kọjá wá sí Táṣíṣì; pohùnréré, ẹ̀yin ènìyàn erékùṣù.

7Ǹjẹ́ èyí náà ni ìlú àríyáa yín, ògbólógbòò ìlú náà, èyí tí ẹṣẹ̀ rẹ̀ ti sìn ín lọ láti lọ tẹ̀dó sí ilẹ̀ tí ó jìnnà réré.

8Ta ló gbérò èyí sí Tírè, ìlú aládé, àwọn oníṣòwò ẹni tí ó jẹ́ ọmọ aládé tí àwọn oníṣòwò o wọ́n jẹ́ ìlúmọ̀míká ní orílẹ̀ ayé?

9OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ti ṣètò rẹ̀, láti tẹrí ìgbéraga àti ògo rẹ ba àti láti rẹ gbogbo àwọn ọlọ́lá ilé ayé sílẹ̀.

9

10Tu ilẹ̀ rẹ gẹ́gẹ́ bí i ti ipadò Náì, Ìwọ ọmọbìnrin Táṣíṣì, nítorí ìwọ kò ní èbúté mọ́.

11OLÚWA ti na ọwọ́ọ rẹ̀ jáde sí orí òkun ó sì mú kí àwọn ilẹ̀ ọba wárìrì. Ó ti pa àṣẹ kan tí ó kan Fonísíà pé kí a pa ilé ààbò rẹ̀ run.

12Ó wí pé, “Kò sí àríyá fún ọ mọ́” ìwọ wúndíá ti Ṣídónì, tí a ti tẹ̀rẹ́ báyìí!

12“Gbéra, rékọjá lọ sí Ṣáípúrọ́sì, níbẹ̀ pẹ̀lú o kì yóò ní ìsinmi.”

13Bojú wo ilẹ̀ àwọn ará Bábílónì, àwọn ènìyàn tíkò jámọ́ nǹkankan bàyìí Àwọn Ásíríà ti sọ ọ́ di ibùgbé àwọn ohun abẹ̀mí ihà; wọn ti gbé ilé ìṣọ́ ìtẹ̀gun wọn ṣókè, wọ́n ti tú odi rẹ̀ sí ìhòòhò wọ́n sì ti sọ ọ́ di ààtàn.

13

14Pohùnréré, ìwọ ọkọ̀ ojú omi Táṣíṣì; wọ́n ti pa odi rẹ̀ run!

15Ní àkókò náà a ó gbàgbé Tírè fún àádọ́rin ọdún, ọjọ́ ayé ọba kan. Ṣùgbọ́n ní òpin àádọ́rin ọdún wọ̀nyí, yóò ṣẹlẹ̀ sí Tírè gẹ́gẹ́ bí orin àgbèrè:

16“Mú hápù kan, rìn kọjá láàrin ìlú, Ìwọ àgbèrè tí a ti gbàgbé; lu hápù rẹ dáadáa, kọ ọ̀pọ̀ orin, kí a lè ba à rántíi rẹ.”

17ⓑ Ní òpin àádọ́rin ọdún náà, OLÚWA yóò bá Tírè jà. Òun yóò sì padà sí àyálò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣẹ́wó, yóò sì máa ṣe òwò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ọba tí ó wà ní ilẹ̀ ayé.

18Ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀ èree rẹ̀ àti owó iṣẹ́ẹ rẹ̀ ni a ó yà ṣọ́tọ̀ fún OLÚWA; a kò ní kó wọn pamọ́ tàbí kí a há wọn mọ́wọ́. Ère rẹ̀ ni a ó fi fún àwọn tí ó ń gbé níwájú OLÚWA, fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ àti aṣọ.

le>