Ìwé Wòlíì Àìsáyà 24:1-23 BYB2014 - Bible AI

1Kíyèsí i, OLÚWA yóò sọ ohun gbogbo dòfo ní ilẹ̀ ayé yóò sì pa á run òun yóò pa ojúu rẹ̀ rẹ́ yóò sì fọ́n àwọn olùgbé ibẹ̀ káàkiri—

2bákan náà ni yóò sì rí fún àlùfáà àti àwọn ènìyàn, fún ọ̀gá àti ọmọ ọ̀dọ̀, fún ìya-ilé àti ọmọbìnrin, fún olùtà àti olùrà, fún ayáni àti atọrọ fún ayánilówó àti onígbésè.

3Ilé ayé ni a ó sọ di ahoro pátapáta a ó sì jẹ gbogbo rẹ̀ run. OLÚWA ni ó ti sọ ọ̀rọ̀ yìí.

3

4Ilẹ̀ ayé ti gbẹ ó sì ṣá, ayé ń ṣòjòjò, àárẹ̀ mú un, àwọn ẹni gíga ilẹ̀ ayé wà nínú ìpọ́njú

5àwọn ènìyàn ayé ti bà á jẹ́; wọ́n ti pa àwọn òfin run wọ́n ṣe lòdì sí àwọn ìlànà wọ́n sì ti ba májẹ̀mú ayérayé jẹ́.

6Nítorí náà, ègún kan ti jẹ ayé run; àwọn ènìyàn rẹ̀ ní láti ru ẹ̀bi wọn. Nítorí náà, àwọn olùgbé ayé ti gbiná dànù, àwọn ẹ̀tàhóró ló sì kù.

7Wáìnì tuntun ti gbẹ, àjàrà sì ti rọ, gbogbo àwọn alárìíyá sì kérora.

8ⓐ Àríyá ti tamborínì ti dákẹ́ ariwo àwọn tí ń ṣàjọyọ̀ ti dáwọ́ dúró ayọ̀ hápù ti dákẹ́ jẹ́ẹ́.

9Kò ṣeéṣe fún wọn láti máa mu wáìnì pẹ̀lú orin kíkọ mọ́ ọtí líle ti di ìkorò fún àwọn ọ̀mu.

10Ìlú tí a run ti dahoro, ẹnu ọ̀nà à bá wọlé kọ̀ọ̀kan ni a dí pa.

11Ní òpópónà ni wọ́n ti ń kígbe fún wáìnì gbogbo ayọ̀ọ wọn ti di ìbànújẹ́, gbogbo àríyá ni a lé kúrò lórí ilẹ̀ ayé.

12Ìlú ni a ti fi sílẹ̀ ní ahoro, ìlẹ̀kùn rẹ̀ ni a sì ti pa bámú bámú.

13Bẹ́ẹ̀ ni yóò sì rí ní orí ilẹ̀ ayé àti láàrin àwọn orílẹ̀ èdè pẹ̀lú, gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí a lu igi ólífì, tàbí gẹ́gẹ́ bí i pàǹtí tí ó ṣẹ́kù lẹ́yìn tí a kórè èso tán.

13

14Wọ́n gbé ohùn wọn ṣókè, wọ́n sì hó fún ayọ̀; láti ìwọ̀ oòrùn ni wọn yóò ti polongo ọlá-ńlá OLÚWA.

15Nítorí náà ní ìlà oòrùn ẹ fi ògo fún OLÚWA; gbé orúkọ OLÚWA ga, àní Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ní àwọn erékùṣù ti inú òkun,

16Láti òpin ayé wá ni a ti gbọ́ orin; “Ògo ni fún olódodo n nì.” Ṣùgbọ́n mo wí pé, “mo ṣègbé, mo ṣègbé!”

16“Ègbé ni fún mi! Alárékérekè dalẹ̀! Pẹ̀lú ìhàlẹ̀ ni àgàbàgebè fi dalẹ̀!”

17Ìpáyà, isà-òkú, àti ìdẹkùn ń dúró dè ọ́, Ìwọ ènìyàn ilẹ̀ ayé.

18Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá nítorí ariwo ìpayà yóò ṣubú sínú ihò, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì yọ́ jáde nínú ihò ni ìdẹkùn yóò gbámú.

18Ibodè ọ̀run ti wà ní sísí sílẹ̀ Ìpìlẹ̀ ayé mì tìtì.

19Ilẹ̀ ayé ti fọ́ ilẹ̀ ayé ti fọ́ dànù, a ti mi ilẹ̀ ayé rìrìrìrì.

19

20Ilẹ̀ ayé yí gbiri bí ọ̀mùtí, ó bì síwá ṣẹ́yìn bí ahéré nínú afẹ́fẹ́; Ẹ̀bi ìṣọ̀tẹ̀ rẹ̀ ń pa á lẹ́rù tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi ṣubú láìní lè dìde mọ́.

21Ní ọjọ́ náà ni OLÚWA yóò jẹ ẹ́ níyà gbogbo agbára tí ó wà lókè lọ́run àti àwọn ọba tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé.

22A ó dà wọ́n papọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́wọ̀n tí a dè nínú un túbú, a ó tì wọ́n mọ́ inú ẹ̀wọ̀n a ó sì jẹ wọ́n ní ìyà lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́.

23A ó rẹ òṣùpá sílẹ̀, ojú yóò sì ti òòrùn; nítorí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun yóò jọba ní orí òkè Ṣíhónì àti ní Jérúsálẹ́mù, àti níwájú àwọn alàgbà rẹ ní ògo.

le>