Ìwé Wòlíì Àìsáyà 25:1-12 BYB2014 - Bible AI

1OLÚWA, ìwọ ni Ọlọ́run un mi; Èmi yóò gbé ọ ga èmi ó sì fi ìyìn fún orúkọọ̀ rẹ nítorí nínú òtítọ́ aláìlẹ́gbẹ́ o ti ṣe ohun ńlá, àwọn ohun tí o ti gbèròo rẹ̀ lọ́jọ́ pípẹ́.

2Ìwọ ti sọ ìlú di àkójọ àlàpà, ìlú olódi ti di ààtàn, ìlú olódi fún àwọn àjèjì ni kò sí mọ́; a kì yóò tún un kọ́ mọ́.

3Nítorí náà àwọn ènìyàn alágbára yóò bọ̀wọ̀ fún ọ; àwọn ìlú orílẹ̀ èdè aláìláàánú yóò bọlá fún ọ.

4Ìwọ ti jẹ́ ààbò fún àwọn òtòsì ààbò fún aláìní nínú ìpọ́njúu rẹ̀ ààbò kúrò lọ́wọ́ ìjì bòòji kúrò lọ́wọ́ ooru. Nítorí pé èémí àwọn ìkà dàbí ìjì tí ó bì lu ògiri

5àti gẹ́gẹ́ bí ooru ní ihà. O mú ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ bá rògbòdìyàn àwọn àjèjì, gẹ́gẹ́ bí òjìji kùrukùru ṣe ń dín ooru kù, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni orin àwọn ìkà yóò dákẹ́.

5

6Ní ori òkè yìí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun yóò ti pèṣè àṣè oúnjẹ àdídùn kan fún gbogbo ènìyàn àpèjẹ ti wáìnì àtijọ́ ti ẹran tí ó dára jù àti ti wáìnì tí ó gbámúṣé.

7Ní orí òkè yìí ni yóò parun aṣọ òkú tí ó ti ń di gbogbo ènìyàn, abala tí ó bo gbogbo orílẹ̀ èdè mọ́lẹ̀;

8ⓐ Òun yóò sì gbé ikú mì títí láé. OLÚWA gbogbo ayé yóò sì nu gbogbo omijé nù, kúrò ní ojúu gbogbo wọn; Òun yóò sì mú ẹ̀gàn àwọn ènìyàn an rẹ̀ kúrò ní gbogbo ilẹ̀ ayé. OLÚWA ni ó ti sọ ọ́.

9Ní ọjọ́ náà wọn yóò sọ pé, “Nítòótọ́ eléyìí ni Ọlọ́run wa; àwa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú un rẹ̀, òun sì gbà wá là. Èyí ni OLÚWA, àwa gbẹ́kẹ̀lé e, ẹ jẹ́ kí a yọ̀ kí inú un wa sì dùn nínú ìgbàlà rẹ̀.”

10ⓑ Ọwọ́ OLÚWA yóò sinmi lé orí òkè yìí ṣùgbọ́n a ó tẹ Móábù mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹṣẹ̀ rẹ̀; gẹ́gẹ́ bí a ti gún koríko mọ́lẹ̀ di ajílẹ̀.

11Wọn yóò na ọwọ́ọ wọn jáde nínú un rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí òmùwẹ̀ tí ń na ọwọ́ọ rẹ̀ jáde láti lúwẹ̀ẹ́. Ọlọ́run yóò mú ìgbéraga wọn wálẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣeféfé wà ọwọ́ ọ wọn.

12Òun yóò sì bi gbogbo ògiri gíga alágbára yín lulẹ̀ wọn yóò sì wà nílẹ̀ Òun yóò sì mú wọn wá si ilẹ̀, àní sí erùpẹ̀ lásán.

le>