Ìwé Wòlíì Àìsáyà 26:1-21 BYB2014 - Bible AI

1Ní ọjọ́ náà ni a ó kọ orin yìí ní ilẹ̀ Júdà: Àwa ní ìlú alágbára kan, Ọlọ́run fi ìgbàlà ṣe ògiri àti ààbò rẹ̀.

2Ṣí àwọn ìlẹ̀kùn kí àwọn olódodo orílẹ̀ èdè kí ó lè wọlé, orílẹ̀ èdè tí ó pa ìgbàgbọ́ mọ́.

3Ìwọ yóò paámọ́ ní àlàáfíà pípé ọkàn ẹni tí ó dúró ṣinṣin, nítorí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ.

4Gbẹ́kẹ̀lé OLÚWA títí láé, nítorí OLÚWA, OLÚWA ni àpáta ayérayé náà.

5Ó sọ àwọn tí ó ń gbé ní òkè di onírẹ̀lẹ̀ ó rẹ ìlú agbéraga náà nílẹ̀; ó sọ ọ́ di ilẹ̀ pẹrẹṣẹ ó sì sọ ọ́ sílẹ̀ nínú erùpẹ̀.

6Ẹṣẹ̀ tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ ẹṣẹ̀ aninilára n nì, ipaṣẹ̀ àwọn òtòsì.

6

7Ipa ọ̀nà àwọn olódodo tẹ́jú Ìwọ adúró ṣinṣin, ìwọ mú ọ̀nà àwọn olódodo kúnná.

8Bẹ́ẹ̀ ni, OLÚWA, rírìn ní ọ̀nà òfin rẹ àwa dúró dè ọ́; orúkọọ rẹ àti òkìkíì rẹ àwọn ni ohun tí ọkàn wa ń fẹ́.

9Ọkàn mi ń pòùngbẹẹ̀ rẹ ní ọ̀gànjọ́ òru; ní òwúrọ̀ ni ẹ̀mí mi ń ṣàfẹ́rí rẹ. Nígbà tí ìdájọ́ọ̀ rẹ bá sọ̀kalẹ̀ sórí ayé àwọn ènìyàn yóò kọ́ ìṣòdodo.

10Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a fi oore-ọ̀fẹ́ hàn sí àwọn ìkà wọn kò kọ́ láti ṣòdodo; kódà ní ilẹ̀ àwọn tí ó dúró ṣinṣin wọ́n tẹ̀ṣíwájú láti máa ṣe ibi wọn kò sì ka ọlá ńlá OLÚWA sí.

11OLÚWA, ti gbé ọwọ́ọ rẹ̀ sókè ṣùgbọ́n àwọn kò rí i. Jẹ́ kí wọ́n rí ìtara rẹ fún àwọn ènìyàn rẹ kí ojú kí ó tì wọ́n; jẹ́ kí iná tí a fi pamọ́ fún àwọn ọ̀ta rẹ jó wọn run.

11

12OLÚWA, ìwọ fi àlàáfíà lélẹ̀ fún wa; ohun gbogbo tí a ti ṣe yọrí ìwọ ni ó ṣe é fún wa.

13OLÚWA Ọlọ́run wa, àwọn olúwa mìíràn lẹ́yìn rẹ ti jọba lé wa lórí, ṣùgbọ́n orúkọọ̀ rẹ nìkan ni àwa fi ọ̀wọ̀ fún.

14Wọ́n ti kú báyìí, wọn ò sí láàyè mọ́; gbogbo ẹ̀mí tí ó ti kọjá lọ wọ̀nyí kò le dìde mọ́. Ìwọ jẹ́ wọ́n ní ìyà o sì sọ wọ́n di asán, Ìwọ pa gbogbo ìrántíi wọn rẹ́ pátapáta.

15Ìwọ ti mú orílẹ̀ èdè gbòòrò, OLÚWA; ìwọ ti mú orílẹ̀ èdè bí sí i. Ìwọ ti gba ògo fún araàrẹ; ìwọ ti sún gbogbo àwọn ààlà ilẹ̀ ṣẹ́yìn.

15

16OLÚWA, Wọ́n wá sọ́dọ̀ rẹ nínú ìpọ́njúu wọn; nígbà tí o jẹwọ́n ní ìyà, wọ́n tilẹ̀ fẹ́ ẹ̀ má le gbàdúrà kẹ́lẹ́ kẹ́lẹ́.

17Gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó lóyún tí ó sì fẹ́rẹ bímọ tí í rúnra tí ó sì ń sunkún nínú ìrora rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwa rí níwájúu rẹ OLÚWA.

18Àwa wà nínú oyún, a wà nínú ìrora ṣùgbọ́n, afẹ́fẹ́ ni a bí lọ́mọ. Àwa kò mú ìgbàlà wá sí ilẹ̀ ayé; àwa kọ́ ni a bí àwọn ènìyàn tí ó wà láyé.

18

19Ṣùgbọ́n àwọn òkúu yín yóò wà láàyè ara wọn yóò dìde. Ìwọ tí o wà nínú erùpẹ̀, dìde nílẹ̀ kí o sì ké igbe ayọ̀. Ìrì rẹ dàbí ìrì òwúrọ̀, ayé yóò bí àwọn òkúu rẹ̀ lọ́mọ.

19

20Ẹ lọ, ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ wọ ìyẹ̀wùu yín lọ kí ẹ sì ti àwọn ìlẹ̀kùn lẹ́yìn in yín, ẹ fi ara yín pamọ́ fún ìgbà díẹ̀ títí tí ìbínú un rẹ̀ yóò fi rékọjá.

21Kíyèsíì, OLÚWA ń jáde bọ̀ láti ibùgbé e rẹ̀ láti jẹ àwọn ènìyàn ilẹ̀ ayé ní ìyà fún ẹ̀ṣẹ̀ẹ wọn. Ayé yóò sì sọ àwọn ẹ̀jẹ̀ tí a ta sí oríi rẹ̀, kì yóò sì fi àwọn tí a ti pa pamọ́ mọ́.

le>