1Ní ọjọ́ náà, OLÚWA yóò fi idà rẹ̀ jẹni níyàidà rẹ̀ amúbí-iná tí ó tóbi tí ó sì lágbáraLẹ́fíátanì ejò tí ń yọ̀ tẹ̀ẹ̀rẹ̀ n nì,Lẹ́fíátanì ejò tí ń lọ́ bìrìkìtì;Òun yóò sì pa ewèlè inú òkun náà.
2Ní ọjọ́ náà “Kọrin nípa ọgbà-àjàrà eléso kan.
3ÈMI OLÚWA ń bojú tó o,Mo ń bomirin ín láti ìgbàdégbà.Mò ń sọ́ ọ tọ̀sán tòrukí ẹnikẹ́ni má ba à pa á lára.
4Inú ò bí mi.Bí ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n bá dojú ìjà kọ mí!Èmi yóò dìde sí wọn ní ogun;Èmi yóò sì dáná ṣun gbogbo wọn.
5Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, jẹ́ kí wọn wá sọ́dọ̀ mi fún ààbò;jẹ́ kí wọ́n wá àlàáfíà pẹ̀lúu mi,bẹ́ẹ̀ ni, jẹ́ kí wọn wá àlàáfíà pẹ̀lúu mi.”
5
6Ní ọjọ́ iwájú Jákọ́bù yóò ta gbòǹgbò,Ísírẹ́lì yóò tanná yóò sì rudièṣo rẹ̀ yóò sì kún gbogbo ayé.
6
7Ǹjẹ́ OLÚWA ti lù úgẹ́gẹ́ bí ó ti lu àwọn tí ó lù ú bolẹ̀?Ǹjẹ́ a ti pa ágẹ́gẹ́ bí a ti pa àwọn tí ó pa á?
8Nípa ogun-jíjà àti lílé nílùú ni ófi dojú kọ ọ́pẹ̀lú ìjì gbígbóná ni ó lé e jáde,gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí afẹ́fẹ́ ìlà oorùn fẹ́
9Nítorí èyí báyìí ni ètùtù yóò ṣe wàfún ẹ̀ṣẹ̀ Jákọ́bù,èyí ni yóò sì jẹ́ èṣo kíkún tiìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ rẹ:Nígbà tí ó bá mú kí àwọn òkúta pẹpẹdàbí òkúta ẹfun tí a fọ́ sí wẹ́wẹ́,kì yóò sí ọ̀pá Áṣérà tàbí pẹpẹ tùràrítí yóò wà ní ìdúró.
10Ìlú olódi náà ti dahoro,ibùdó ìkọ̀sílẹ̀, tí a kọ̀tìgẹ́gẹ́ bí aṣálẹ̀;níbẹ̀ ni àwọn ọmọ màlúù ti ń jẹkoníbẹ̀ ni wọn ń sùn sílẹ̀;wọn sì jẹ gbogbo ẹ̀ka rẹ̀ tán.
11Nígbà tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ gbẹ, a kán wọn dànùàwọn obìnrin wá wọ́n, sì fi wọ́n dánánítorí àwọn ènìyàn tí òye kò yéni wọ́n jẹ́;Nítorí náà ni Ẹlẹ́dàá wọn kò ṣe yọ́nú sí wọn.Ẹlẹ́dàá wọn kò sì síjú àánú wò wọ́n.
12Ní ọjọ́ náà OLÚWA yóò sì kó ooré láti ìṣàn omi Éúfírétì wá títí dé Wádì ti Éjíbítì, àti ìwọ, ìwọ ọmọ Ísírẹ́lì, ni a ó kójọ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan.
13ⓐ Àti ní ọjọ́ náà, a ó fun fèrè ńlá kan. Gbogbo àwọn tí ń ṣègbé lọ ní Ásíríà àti àwọn tí ń ṣe àtìpó ní Éjíbítì yóò wá sin OLÚWA ní òkè mímọ́ ní Jérúsálẹ́mù.