1Ègbé ni fún òdòdó-ẹ̀yẹ náà, tí í ṣeìgbéraga àwọn ọ̀mùtí Éfáímù,àti sí òdòdó náà tí ń rọ, tí í ṣeògo ẹwàa rẹ̀,tí ó tò sí orí àfonífojì ẹlẹ́tù lójúàti sí ìlú náà ìgbéraga àwọn tía rẹ̀ sílẹ̀ láti ọ̀dọ̀ wáìnì!
2Kíyèsíì, OLÚWA ní ẹnìkan tí ó le tí ó sì lágbára,gẹ́gẹ́ bí ẹ̀wọ́ yìnyín àti bí àtẹ̀gùn apanirun,gẹ́gẹ́ bí àrọ̀ọ̀dá òjò àti òjò tí ómú ẹ̀kún omi wá,òun yóò fi tipátipá sọ ọ́ sílẹ̀.
3Òdòdó-ẹ̀yẹ náà, tí í ṣe ìgbéraga àwọnọ̀mùtí Éfáímù,òun ni a ó tẹ̀ mọ́lẹ̀ lábẹ́ àtẹ́lẹṣẹ̀.
4Òdòdó tí ó ń rọ náà tí í ṣe ẹwà ògo rẹ̀,tí ó tò sí orí àfonífojì ẹlẹ́tù lójú,yóò dàbí èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó pọ́n ṣáájú ìkóórèbí ẹnikẹ́ni bá ti rí i tí ó sì mú un ní ọwọ́ọ rẹ̀,òun a sì mì ín.
4
5Ní ọjọ́ náà OLÚWA àwọn ọmọ-ogunyóò jẹ́ adé tí ó lógo,Òdòdó tí ó lẹ́wàfún àwọn ènìyàn an rẹ̀ tí ó ṣẹ́kù.
6Òun yóò sì jẹ́ ẹ̀mí ìdájọ́-òdodofún ẹni tí ó jókòó ní ìtẹ́-ìdájọ́àti oríṣun agbárafún àwọn ẹni tí ó ń dá ogun padàní ẹnubodè.
6
7Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú ta gbọ̀n ọ́n gbọ̀n ọ́n fún ọtí wáìnìwọ́n pòòrì dànìn fún ọtí bíà,Àwọn àlùfáà àti wòlíì ta gbọ̀n ọ́n gbọ̀n ọ́n fún ọtí bíàwọ́n ta gíẹ́ gíẹ́ fún ọtí wáìnìwọ́n ń lọ́ bìrì bìrì fún ọtí bíà,wọ́n ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n nígbà tí wọ́n ń ríran,wọ́n kọsẹ̀ nígbà tí wọ́n ń mú ìpinnu wá.
8Gbogbo orí i tábìlì ni ó kún fún èébìkò sì sí ibìkan tí kò sí ẹ̀gbin.
8
9“Ta ni ẹni náà tí ó ń gbìyànjú àti kọ́?Ta ni ó sì ń ṣàlàyé ìhìn in rẹ̀ fún?Sí àwọn ọmọdé tí a já lẹ́nu ọmú un wọn,sí àwọn tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà lẹ́nu ọmú.
10Nítorí tí í ṣe:Ṣe kí o ṣe, ṣe kí o ṣe,àṣẹ lé àṣẹ, àṣẹ lé àṣẹdíẹ̀ níhìnín, díẹ̀ lọ́hùn ún.”
10
11ⓐ Ó dára báyìí, pẹ̀lú ètè àjèjì àti ahọ́n àìmọ̀Ọlọ́run yóò bá àwọn ènìyàn yìí ṣọ̀rọ̀
12ⓑ àwọn tí ó sọ fún wí pé,“Èyí ni ibi ìsinmi, jẹ́ kí àwọn aláàárẹ̀ sinmi”;àti pé, “èyí ni ibi ìsinmi”ṣùgbọ́n wọn kò tẹ́tísílẹ̀.
13Fún ìdí èyí, ọ̀rọ̀ OLÚWA sí wọn yóò di péṣe kí o ṣe, ṣe kí o ṣe,àṣẹ lé àṣẹ, àṣẹ lé àṣẹ;díẹ̀ níhìnín, díẹ̀ ní ọ̀húnbẹ́ẹ̀ ni wọn yóò lọ tí wọn yóò tún ṣubu ṣẹ́yìn,wọn yóò farapa, wọn yóò bọ́ sínú okùna ó sì gbá wọn mú.
13
14Nítorí náà, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLÚWA, ẹ̀yin ẹlẹ́gàn,tí ń jọba lórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní Jérúsálẹ́mù.
15Ẹ fọ́n pé, “Àwa ti bá ikú mulẹ̀,pẹ̀lú ibojì ni àwa ti jọ ṣe àdéhùn.Nígbà tí ìbáwí gbígbóná fẹ́ kọjá,kò le kàn wá lára,nítorí a ti fi irọ́ ṣe ààbò o waàti àìṣòtítọ́ ibi ipamọ́ wa.”
16ⓒ Fún ìdí náà èyí ni ohun tí OLÚWA Jèhófà sọ: “Kíyèsíì, mo gbé òkúta kan lélẹ̀ ní Ṣíhónìòkúta tí a dánwò,òkúta igunlé iyebíye fún ìpìlẹ̀ tí ó dájúẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀le kì yóò ní ìfòyà.
17Èmi yóò fi ìdájọ́ ṣe okùn òṣùwọ̀nàti òdòdó òjé òṣùwọ̀n;yìnyín yóò gbá ààbò yín dànù àti irọ́,omi yóò sì kún bo gbogbo ibi tíẹ ń farapamọ́ sí mọ́lẹ̀.
18Májẹ̀muu yín tí ẹ bá ikú dá ni a ó fagi lé;àdéhùn yín pẹ̀lú ibojì ni kì yóò dúró.Nígbà tí ìbínú gbígbóná náà bá fẹ́ kọjá,a ó ti ipa rẹ̀ lù yín bolẹ̀.
19Nígbàkúùgbà tí ó bá ti wá niyóò máa gbé ọ lọ,ni àràárọ̀, ní ọ̀sán àti ní òru,ni yóò máa fẹ́ kọjá lọ.”
19Ìmòye ọ̀rọ̀ ìmọ̀ yìí yóò máa mú ìpayà ńlá wá.
20Ibùsùn kúrújù fún ìnara lé lórí,ìbora kò fẹ̀ tó láti yí ara yín ká.
21OLÚWA yóò dìde sókè gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣení òkè Péráṣímùyóò ru ara rẹ̀ ṣókè gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣení àfonífojì Gíbíónì—láti ṣe iṣẹ́ rẹ̀, abàmì iṣẹ́ ẹ rẹ̀,yóò ṣe iṣẹ́ rẹ̀, àní àjèjì iṣẹ́ rẹ̀.
22Ní ìsinsìn yìí ẹ dákẹ́ ẹlẹ́yà ṣíṣe,bí bẹ́ẹ̀ kọ́ ìdè e yín yóò le sí i;OLÚWA, àní OLÚWA àwọn-ogun ti sọ fún minípa àṣẹ ìparun ti ó ti pa lórí gbogbo ilẹ̀ náà.
22
23Tẹ́tí kí o sì gbọ́ ohùn mi,fi ara balẹ̀ kí o sì gbọ́ ohun tí mo sọ.
24Nígbà tí àgbẹ̀ kan bá tu ilẹ̀ láti gbìnyóò ha máa tulẹ̀ títí títí ni?Ǹjẹ́ yóò ha máa tu ilẹ̀ kíó sì máa jọ̀ ọ́ títí lọ bí?
25Lẹ́yìn ìgbà tí ó bá ti tẹ́ ilẹ̀ pẹrẹṣẹòun kì yóò ha gbìn káráwè kíó sì fọ́n irúgbìn kúmínì ká bí?Òun kì yóò ha gbin jéró sí àyè e tirẹ̀ọkà báálì sì àyè e tirẹ̀,àti Ṣípẹ́lítì ní oko tirẹ̀?
26Ọlọ́run rẹ̀ tọ́ ọ sọ́nàó sì kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ ní ọ̀nà tótọ́.
26
27A kì í fi òòlù pa káráwétàbí kẹ̀kẹ́-ẹrù là á fi yí kúmínì mọ́lẹ̀;ọ̀pá ni a fi ń lu káráwé,àti kúmínì pẹ̀lú igi.
28A gbọdọ̀ lọ hóró kí a tó ṣe àkàrà;bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kì í máa pa á lọ títí láé.Bí ó tilẹ̀ yí ẹṣẹ̀ kẹ̀kẹ́ ìpakà a rẹ̀ lóríi rẹ̀,àwọn ẹṣin rẹ̀ kò le lọ̀ ọ́.
29Gbogbo èyí pẹ̀lú ti ọ̀dọ̀ OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wá,oníyanu ní ìmọ̀ràn àti ológo ní ọgbọ́n.