Ìwé Wòlíì Àìsáyà 29:1-24 BYB2014 - Bible AI

1Ègbé ni fún ọ, Áríẹ́lì, Áríẹ́lì, ìlú níbi tí Dáfídì tẹ̀dó sí! Fi ọdún kún ọdún sì jẹ́ kí àwọn àkọlùkọgbà àjọ̀dún un rẹ tẹ̀ṣíwájú.

2Ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀ èmi yóò dó ti Áríẹ́lì òun yóò ṣọ̀fọ̀ yóò sì sunkún, òun yóò sì dàbí pẹpẹ ọkàn sí mi.

3Èmi yóò sì wà ní bùba yí ọ ká níbi gbogbo; Èmi yóò sì fi ilé-ìṣọ́ yí ọ ká: èmi yóò sì fi iṣẹ́ ìdótini mi dojú kọ ọ́.

4Ní ìrẹ̀sílẹ̀, ìwọ ó sì máa sọ̀rọ̀ láti ilẹ̀ wá; ọ̀rọ̀ rẹ yóò sì máa kùn jáde láti inú erùpẹ̀. Ohun rẹ yóò máa jáde bí i ti iwin láti ilẹ̀ wá, láti inú erùpẹ̀ ni ohùn rẹ yóò máa wá wúyẹ́wúyẹ́.

4

5Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀tá rẹ, yóò dàbí yanrìn kíkúnná, agbo àwọn aláìláàánú bí ìyàngbò tí a fẹ́ dànù. Lójijì, ní ìṣẹ́jú àáyá,

6OLÚWA àwọn ọmọ-ogun yóò wá pẹ̀lú àrá, ilẹ̀ ríri àti ariwo ńlá àti ẹ̀fúúfù líle àti iná ajónirun orílẹ̀ èdè tí ó bá Áríẹ́lì jà, tí ó dojú ìjà kọ òun àti ilé olódì rẹ̀ tí ó sì dó tì í, yóò dàbí ẹni pé nínú àlá, bí ìran ní òru

7Lẹ́yìn náà, ọ̀gọ̀rọ̀ ènìyàn tí gbogbo

8àti bí ìgbà tí ẹni tí ebi ń pa ń lá àlá pé òun ń jẹun, ṣùgbọ́n ó jí, ebi rẹ̀ sì wà pẹ̀lúu rẹ̀; àti bí ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ lá àlá pé òun ń mumi, ṣùgbọ́n nígbà tí ó yajú pẹ́ ẹ́, pẹ̀lú òùngbẹ tí kò dáwọ́ dúró ni. Bẹ́ẹ̀ ni yóò sì rí fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè tí ń bá òkè Ṣíhónì jà.

8

9Ẹ bẹ̀rù kí ẹnu kí ó yà yín, ẹ fọ́ ara yín lójú kí ẹ má sì ríran; ẹ mutí yó kì í ṣe ọtí wáìnì, ẹ ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n, ṣùgbọ́n kì í se ti ọtí bíà.

10OLÚWA ti mú oorun ìjìká wá sóríi yín: ó ti dì yín lójú (ẹ̀yin wòlíì); ó ti bo oríi yín (ẹ̀yin aríran).

11Fún un yín gbogbo ìran yìí kò yàtọ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ tí a fi èdìdì dì sínú ìwé kíká. Bí ẹ bá sì fún ẹni tí ó lè ka ìwé kíká náà, tí ẹ sì sọ fún un pé, “Jọ̀wọ́ ka èyí,” òun yóò dáhùn pé, “Èmi kò lè kà á; a ti dì í ní èdìdì.”

12Tàbí bí ẹ bá fún ẹni tí kò lè ka ìwé kíká náà tí ẹ sì sọ pé, “Jọ̀wọ́ ka èyí,” òun yóò dáhùn pé, “Èmi kò mọ̀ ọ́n kà.”

13ⓐ  OLÚWA wí pé: “Àwọn ènìyàn yìí súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú ẹnu wọn wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún mi pẹ̀lú ètè wọn, ṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnnà sí mi. Ìsìn wọn fún mi ni a gbé ka orí òfin tí àwọn ọkùnrin kọ́ ni.

14ⓑ Nítorí náà lẹ́ẹ̀kan sí i èmi yóò ya àwọn ènìyàn yìí lẹ́nu pẹ̀lú ìyanu lórí ìyanu; ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n ni yóò ṣègbé, ìmọ̀ àwọn onímọ̀ ni yóò pòórá.”

15Ègbé ni fún àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun láti fi ètò wọn pamọ́ kúrò lójú OLÚWA, tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ẹ wọn nínú òkùnkùn tí wọ́n sì rò pé, “Ta ló rí wa? Ta ni yóò mọ̀?”

16ⓒ Ẹ̀yin dojú nǹkan délẹ̀, bí ẹni pé wọ́n rò pé amọ̀kòkò dàbí amọ̀! Ǹjẹ́ ohun tí a ṣe le sọ fún olùṣe pé “Òun kọ́ ló ṣe mí”? Ǹjẹ́ ìkòkò lè sọ nípa amọ̀kòkò pé, “kò mọ nǹkan”?

16

17Ní àìpẹ́ jọjọ, ǹjẹ́ a kò ní sọ Lẹ́bánónì di pápá ẹlẹ́tù lójú àti pápá ẹlẹ́tù lójú yóò dàbí ihà?

18ⓓ Ní ọjọ́ náà adití yóò gbọ́ ọ̀rọ̀ ìwé kíká náà, láti inú fìrífìrí àti òkùnkùn ni àwọn ojú afọ́jú yóò ríran.

19Lẹ́ẹ̀kan síi àwọn onírẹ̀lẹ̀ yóò yọ̀ nínú OLÚWA: àwọn aláìní yóò yọ̀ nínú Ẹni Mímọ́ ti Ísírẹ́lì.

20Aláìláàánú yóò pòórá, àwọn tí ń ṣẹlẹ́yà yóò dàwátì, gbogbo àwọn tí ó ní ojú ibi ni a ó ké lulẹ̀—

21àwọn tí wọ́n fi ọ̀rọ̀ kan mú ẹnìkan di ẹlẹ́bi, ẹni tí ń dẹkùn mú olùgbèjà ní kóòtù tí ẹ fi ẹ̀rí èkè dun aláìṣẹ̀ ní ìdájọ́.

22Nítorí náà, èyí ni ohun tí OLÚWA, ẹni tí ó ra Ábúráhámù padà sọ sí ilé Jákọ́bù: “Ojú kì yóò ti Jákọ́bù mọ́; ojúu wọn kì yóò sì rẹ̀wẹ̀sì mọ́.

23Nígbà tí wọ́n bá ríi láàrin àwọn ọmọ wọn, àwọn iṣẹ́ ọwọ́ mi, wọn yóò ya orúkọ mi sí mímọ́, wọn yóò tẹ́wọ́gba mímọ́ Ẹni Mímọ́ Jákọ́bù wọn yóò dìde dúró ní ìbọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run Ísírẹ́lì.

24Gbogbo àwọn tí ń rìn ṣégeṣège ní ẹ̀mí yóò jèrè ìmọ̀; gbogbo àwọn tí ń ṣe àròyé yóò gba ìtọ́sọ́nà.”

le>