Ìwé Wòlíì Àìsáyà 3:1-26 BYB2014 - Bible AI

1Kíyèsí i, OLÚWA, OLÚWA àwọn ọmọ-ogun, fẹ́ mú ìpèsè àti ìrànlọ́wọ́ kúrò ní Jérúsálẹ́mù àti Júdà gbogbo ìpèsè ounjẹ àti ìpèsè omi

2àwọn akíkanjú àti jagunjagun, adájọ́ àti wòlíì, aláfọ̀sẹ àti alàgbà,

3balógun àádọ́ta àti bọ̀rọ̀kìnní ènìyàn, olùdámọ̀ràn, oníṣọ̀nà tí ó dáńtọ́ àti ògbójú oníṣegùn.

3

4Èmi ó sọ àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin di aláṣẹ wọn, ọ̀dọ́mọdé lásán làsàn ni yóò sì máa jọba lóríi wọn.

5Àwọn ènìyàn yóò sì má a pọ́n ọmọnìkejì wọn lójú ẹnìkan sí ẹnìkejìi rẹ̀, aládùúgbò sí aládùúgbò rẹ̀. Àwọn ọ̀dọ́ yóò gbogun ti àwọn àgbà, àwọn mẹ̀kúnnù yóò dìde sí bọ̀rọ̀kìnní.

5

6Ọkùnrin kan yóò di ọ̀kan nínu àwọn arákùnrin rẹ̀ mú nínú ilé baba rẹ̀, yóò sì wí pé, “Ìwọ́ ní aṣọ, ìwọ máa ṣe olórí wa, sì mójútó àwọn ahoro wọ̀nyí!”

7Ṣùgbọn ní ọjọ́ náà ni yóò figbe bọnu pé, “Èmi kò ní àtúnṣe kan. Èmi kò ní oúnjẹ, bẹ́ẹ̀ ni n ò ní aṣọ nílé, ẹ má fi mí ṣe olórí àwọn ènìyàn náà.”

7

8Jérúsálẹ́mù ń ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n Júdà ń ṣubú lọ, ọ̀rọ̀ àti ìṣe wọn lòdì sí OLÚWA, láti mú ojú ògo rẹ̀ bínú.

9Ìwò ojú wọn ń jẹ́rìí lòdì sí wọn, wọ́n ń polongo ẹ̀ṣẹ̀ wọn bí i Sódómù; wọn ò fi pamọ́! Ègbé ni fún wọn! Wọ́n ti mú ìparun wá sórí ara wọn.

9

10Ẹ sọ fún olódodo pé yóò dára fún wọn, nítorí ní àjẹgbádùn ni wọn yóò jẹ èṣo iṣẹ́ ẹ wọn.

11Ẹ̀gbé ni fún aṣebi! Ìparun wà lóríi wọn A ó sì san èrè iṣẹ́ tí ọwọ́ wọn ti ṣe fún wọn.

11

12Àwọn ọ̀dọ̀mọdé ni o ń pọ́n àwọn ènìyàn mi lójú àwọn obìnrin ń jọba lé wọn lórí. Áà! Ènìyàn mi àwọn afinimọ̀nà yín ti sìyín lọ́nà, wọn sì mú yín kúrò ní ipa ọ̀nà yín.

12

13OLÚWA bọ sí ipo rẹ̀ ní ìtẹ́ ìdájọ́ Ó dìde láti dá àwọn ènìyàn lẹ́jọ́.

14OLÚWA dojú ẹjọ́ kọ àwọn alàgbà àti àwọn olórí àwọn ènìyàn rẹ̀. “Ẹyin ni ẹ ti run ọgbà àjàrà mi, ogún àwọn tálákà ń bẹ̀ nínú ilé yín.

15Kín ni èro yín láti máa run àwọn ènìyàn mi túútúú tí ẹ sì fojú àwọn tálákà ni gbolẹ?” ni OLÚWA wí, OLÚWA àwọn ọmọ-ogun.

15

16OLÚWA wí pé, “Àwọn obìnrin Ṣíónì jẹ́ agbéraga, wọn ń rìn lọ pẹ̀lú ọrùn tí ó nà tàntàn, tí wọn ń fojú pe ọkùnrin, tí wọn ń sọ̀dí bí wọn ti ń yan lọ pẹ̀lú ohun ọ̀ṣọ́ tí ń mì wọnjan wọnjan lọ́rùn ẹṣẹ̀ wọn.

17Nítorí náà OLÚWA yóò mú egbò wá sórí àwọn obìnrin Ṣíónì, OLÚWA yóò sì pá wọn ní agbárí.”

18Ní ọjọ́ náà, OLÚWA yóò já ọ̀ṣọ́ wọn gbà kúrò ti ọwọ́ àti ìgbàrí àti ẹ̀gbà ọrùn tí ó dàbí òṣùpá

19gbogbo yẹtí, ẹ̀gbà ọwọ́ àti ìbòjú,

20gbogbo gèlè ìwégbà ọrùn ẹ̀ṣẹ̀ àti àyà, àwọn ìgo tùràrí àti òògùn,

21òrùka ọwọ́ àti ti imú,

22àwọn àtàtà aṣọ, àwọ̀lékè, agbádá àti àpamọ́wọ́,

23Díńgí wọn, aṣọ funfun nigínnigín ìbòrí àti ìbòjú.

23

24Dípò òórùn dídùn, òórún búbubú ni yóò wá, okùn ni yóò wà dípò àmùrè, orí pípá ni yóò dípò ìrun ti a ṣe ní ọ̀ṣọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ ni yóò dípò aṣọ ẹ̀yẹ ìjóná dípò ẹwà.

25Àwọn ọkùnrin rẹ yóò ti ipa idà ṣubú, àti àwọn jagunjagun rẹ̀ lójú ogun.

26Àwọn bodè Síònì yóò sunkún kíkorò, wọn ó ṣọ̀fọ̀, nítorí ó dahoro, yóò jókòó ní orí ilẹ̀.

e>