Ìwé Wòlíì Àìsáyà 30:1-33 BYB2014 - Bible AI

1“Ègbé ni fún orílẹ̀-èdè alágídí náà,” ni OLÚWA wí, “Fún àwọn tí ó gbé ètò jáde tí kì í ṣe tèmi, tí wọ́n ń gbìmọ̀ pọ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe nípa Ẹ̀mí mi, tí wọ́n ń dá ẹ̀ṣẹ̀ lórí ẹ̀ṣẹ̀;

2tí wọ́n lọ sí Éjíbítì láì ṣe fún mi, tí ó ń wá ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Fáráò fún ààbò, sí òjìji, Éjíbítì fún ibi ìsádi.

3Ṣùgbọ́n ààbò Fáráò yóò já sí ìtìjú fún un yín, òjìji Éjíbítì yóò mú àbùkù báa yín.

4Bí wọ́n tilẹ̀ ní àwọn òṣìṣẹ́ ní Sóánì tí àwọn ikọ̀ wọn sì ti dé sí Hánísì,

5gbogbo wọn ni a ó dójútì, nítorí àwọn ènìyàn kan tí kò wúlò fún wọn, tí kò mú ìrànlọ́wọ́ tàbí àǹfààní wá, bí kò ṣe àbùkù àti ìdójúti ni.”

6Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ sí àwọn ẹranko tí ó wà ní Gúúsù: Láàrin ilẹ̀ ìnira àti ìpọ́njú, ti kìnnìún àti abo kìnnìún ti pamọ́lẹ̀ àti ejò olóró, àwọn ikọ̀ náà kó ẹrù àti ọrọ̀ wọn lẹ́yìn àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àwọn ohun ìní wọn ní orí iké àwọn ràkunmí, sí orílẹ̀ èdè aláìlérè,

7sí Éjíbítì tí ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ kò wúlò rárá. Nítorí náà mo pè é ní Ráhábù Aláìlẹ́sẹ̀ nǹkankan.

7

8Lọ nísinsìn yìí, kí o sì kọ ọ́ sí ara pátakó fún wọn, tẹ̀ ẹ́ sí ara ìwé kíká, pé fún àwọn ọjọ́ tí ó ń bọ̀ kí ó sì lè jẹ́ ẹ̀rí ayérayé.

9Àwọn wọ̀nyí jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn àti ẹlẹ́tanu ọmọ, àwọn ọmọ tí wọn kò ṣetán láti tẹ́tí sí ìtọ́ni OLÚWA.

10Wọ́n sọ fún àwọn aríran pé, “Ẹ má ṣe rí ìran mọ́!” àti fún àwọn wòlíì, “Ẹ má ṣe fi ìran ohun tí ó tọ́ hàn wá mọ́! Ẹ sọ ohun tí ó tura fún wa, ẹ sàsọtẹ́lẹ̀ ẹ̀tàn.

11Ẹ fi ọ̀nà yìí sílẹ̀, ẹ kúrò ní ọ̀nà yìí ẹ dẹ́kun à ń dojú ìjà kọwá pẹ̀lú Ẹni-Mímọ́ Ísírẹ́lì!”

12Nítorí náà, èyí ni ohun tí Ẹni-Mímọ́ Ísírẹ́lì wí: “Nítorí pé ẹ ti kọ ọ̀rọ̀ yìí sílẹ̀, ẹ gbáralé ìnilára kí ẹ sì gbọ́kànlé ẹ̀tàn,

13ẹ̀ṣẹ̀ yìí yóò rí fún ọ gẹ́gẹ́ bí ògiri gíga, tí ó sán tí ó sì fì tí ó sì wó lójijì, àti ńi ìṣẹ́jú àáyá.

14Yóò sì fọ́ ọ sí wẹ́wẹ́ bí àpáàdì tí a fọ́ yánkanyànkan àti pé a kò ní rí ẹ̀rún kan nínú àfọ́kù rẹ̀, fún mímú èédú kúrò nínú ààrò tàbí gbígbọ́n omi jáde kúrò nínú àmù.”

15Èyí ni ohun tí OLÚWA alágbára, Ẹni-Mímọ́ ti Ísírẹ́lì wí: “Nínú ìrònúpìwàdà àti ìsinmi ni ìgbàlà rẹ wà, ní ìdákẹ́jẹ́ ẹ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé ni agbára rẹ wà, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò ní ọ̀kankan nínú wọn.

16Ẹ̀yin wí pé, ‘bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa yóò sálọ lórí ẹṣin.’ Nítorí náà ẹ̀yin yóò sá! Ẹ̀yin wí pé, ‘Àwa yóò gun àwọn ẹṣin tí ó yára lọ.’ Nítorí náà àwọn tí ń lée yín yóò yára!

17Ẹgbẹ̀rún yóò sá nípa ìdẹ́rùbà ẹnìkan; nípa ìdẹ́rùbà ẹni márùn ún gbogbo yín lẹ ó ṣálọ, tí a ó fi yín sílẹ̀ àti gẹ́gẹ́ bí igi àṣíá ní orí òkè, gẹ́gẹ́ bí àṣíá lórí òkè.”

17

18Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀ OLÚWA sì fẹ́ síjú àánú wò ọ́; ó dìde láti ṣàánú fún ọ. Nítorí OLÚWA jẹ́ Ọlọ́run ìdájọ́. Ìbùkún ni fún gbogbo àwọn tí ó dúró dè é!

19Ẹ̀yin ènìyàn Ṣíhónì, tí ń gbé ní Jérúsálẹ́mù, ìwọ kì yóò ṣunkún mọ́. Báwo ni àánú rẹ̀ yóò ti pọ̀ tó nígbà tí ìwọ bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́! Bí ó bá ti gbọ́, òun yóò dá ọ lóhùn.

20Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLÚWA fún ọ ní àkàrà ìyà àti omi ìpọ́njú, àwọn olùkọ́ rẹ kì yóò farasin mọ́; pẹ̀lú ojú rẹ ni ìwọ ó rí wọn.

21Bí o bá yí sápá ọ̀tún tàbí apá òsi, etí rẹ yóò máa gbọ́ ohùn kan lẹ́yìn rẹ, wí pé, “Ọ̀nà nìyìí, máa rìn nínú rẹ̀.”

22Lẹ́yìn náà ni ẹ ó ba àwọn ère yín jẹ́ àwọn tí ẹ fi fàdákà bò àti àwọn ère tí ẹ fi wúrà bò pẹ̀lú, ẹ ó sọ wọ́n nù bí aṣọ tí obìnrin fi ṣe nǹkan oṣù ẹ ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ kúrò níbí!”

23Òun yóò sì rọ òjò fún un yín sí àwọn irúgbìn tí ẹ gbìn sórí ilẹ̀, oúnjẹ tí yóò ti ilẹ̀ náà wá yóò ní ọ̀rá yóò sì pọ̀. Ní ọjọ́ náà ni àwọn ẹran ọ̀sìn yín yóò máa jẹ koríko ní pápá oko tútù tí ó tẹ́jú.

24Àwọn màlúù àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó ń tú ilẹ̀ yóò jẹ oúnjẹ àdídùn tí a fi amúga àti ṣọ́bìrì fọ́nkálẹ̀.

25Ní ọjọ́ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò sọ ẹ̀míi wọn nù nígbà tí ilé ìṣọ́ yóò wó lulẹ̀, odò omi yóò ṣàn lórí òkè gíga àti lórí àwọn òkè kékeré.

26Òṣùpá yóò sì tàn bí òòrùn, àti ìtànsán òòrùn yóò mọ́lẹ̀ ní ìlọ́po méje, gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ odidi ọjọ́ méje, nígbà tí OLÚWA yóò di ojú ọgbẹ́ àwọn ènìyàn an rẹ̀ tí yóò sì wo ọgbẹ́ tí ó ti dá sí wọn lára sàn.

27Kíyèsí i, orúkọ OLÚWA ti òkèèrè wá pẹ̀lú ìbínú gbígbóná àti kùrukùru èéfín tí ó nípọn; ètè rẹ̀ kún fún ìbínú ahọ́n rẹ̀ sì jẹ́ iná ajónirun.

28Èémíi rẹ̀ sì dàbí òjò alágbára, tí ó rú sókè dé ọ̀run. Ó jọ àwọn orílẹ̀ èdè nínú asẹ́ ìparun; ó sì fi sí àgbọ̀n àwọn ènìyàn kókó kan tí ó ń sì wọ́n lọ́nà.

29Ẹ̀yin ó sì kọrin gẹ́gẹ́ bí i ti alẹ́ tí ẹ̀ ń ṣe àjọyọ̀ àpéjọ mímọ́, ọkàn yín yóò yọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí àwọn ènìyàn gòkè lọ pẹ̀lúu fèrè sí orí òkè OLÚWA, àní sí àpáta Ísírẹ́lì.

30OLÚWA yóò jẹ́ kí wọn ó gbọ́ ohùn ògo rẹ̀ yóò sì jẹ́ kí wọ́n rí apá rẹ̀ tí ó ń bọ̀ wálẹ̀ pẹ̀lú ìbínú gbígbóná àti iná ajónirun, pẹ̀lúu mọ̀nàmọ́ná, àrá àti yìnyín.

31Ohùn OLÚWA yóò fọ́ Áṣíríà túútúú, pẹ̀lú ọ̀pá aládé rẹ̀ ni yóò lù wọ́n bolẹ̀.

32Ẹgba kọ̀ọ̀kan tí OLÚWA bá gbé lé wọn pẹ̀lú ọ̀pá ìjẹníyà rẹ̀ yóò jẹ́ ti ìlù tamborínì àti ti hápù, gẹ́gẹ́ bí ó ti ń bá wọn jà lójú ogun pẹ̀lú ẹ̀sẹ́ láti apá rẹ̀.

33A ti tọ́jú Tófẹ́tì sílẹ̀ tipẹ́tipẹ́, a ti tọ́jú rẹ̀ sílẹ̀ fún ọba. Ojú ààrò rẹ̀ ni a ti gbẹ́ jìn tí ó sì fẹ̀, pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ iná àti igi ìdáná; èémí OLÚWA, gẹ́gẹ́ bí ìsàn ṣúfúrù tí ń jó ṣe mú un gbiná.

le>