2
3Nígbà náà ni ojú àwọn tí ó rí kò ní pàdé mọ́, àti etí àwọn tí ó gbọ́ yóò tẹ́tí sílẹ̀.
4Ọkàn àwọn oníwàdùwàdù ni yóò là tí yóò sì yè, àti ahọ́n tí ń kólòlò ni yóò là geerege.
5A kò ní pe òmùgọ̀ ní bọ̀rọ̀kìnní mọ́ tàbí kí a fi ọ̀wọ̀ tí ó ga jù fún mọ̀dàrú.
6Nítorí òmùgọ̀ ṣọ̀rọ̀ òmùgọ̀, ọkàn rẹ̀ kún fún ìwà ibi: òun hùwà àìwà-bí-Ọlọ́run ó sì ń tan àṣìṣe tí ó kan OLÚWA kalẹ̀; ẹni ebi ń pa ló fi sílẹ̀ lófo àti fún àwọn tí òrùngbẹ ń gbẹ ni ó mú omi kúrò.
7Ìlànà àwọn aṣa jẹ ti ìkà, ó pète oríṣìí ìlànà ibi láti pa aláìní run pẹ̀lú irọ́ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀bẹ̀ òtòsì sì tọ̀nà.
8Ṣùgbọ́n bọ̀rọ̀kìnní ènìyàn a máa pète ohun ńlá àti nípa èrò rere ni yóò dúró.
9Ẹ̀yin obìnrin tí ẹ ti gba ìtẹ́lọ́rùn gidi ẹ dìde kí ẹ tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin ọ̀dọ́mọbìnrin tí ọkàn yín ti balẹ̀, ẹ gbọ́ ohun tí mo fẹ́ sọ!
10Ní ó lé díẹ̀ ní ọdún kan ẹ̀yin tí ọkàn an yín balẹ̀ yóò wárìrì; ìkóórè àjàrà kò ní múnádóko, bẹ́ẹ̀ ni ìkóórè èṣo kò ní sí.
11Wárìrì, ẹ̀yin obìnrin onítẹ̀lọ́rùn bẹ̀rù, ẹ̀yin ọ̀dọ́mọbìnrin tí ẹ rò pé ọkàn yín balẹ̀! Ẹ bọ́ aṣọ yín kúrò, ẹ ró aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́ẹ yín.
12Ẹ lu ọmú un yín fún pápá ìgbádùn náà, fún àwọn àjàrà eléso
13àti fún ilẹ̀ àwọn ènìyàn mi ilẹ̀ tí ó ti kún fún ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n— bẹ́ẹ̀ ni, kẹ́dùn fún gbogbo ilé ìtura àti fún ìlú àríyá yìí.
14Ilé olódi ni a ó kọ̀ sílẹ̀, ìlù aláriwo ni a ó kọ̀tì; ilé olódi àti ilé ìṣọ́ ni yóò di ìdànù títí láéláé, ìdùnnú àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti pápá oko fún àwọn ẹran ọ̀sìn,
15títí a ó fi tú Ẹ̀mí sí wa lórí láti òkè wá, àti ti aṣálẹ̀ tí yóò dí pápá oko ọlọ́ràá àti tí pápá ọlọ́ràá yóò dàbí ẹgàn.
16Ẹ̀tọ́ yóò máa gbé ní inú aṣálẹ̀ àti òdodo yóò sì máa gbé ní pápá oko ọlọ́ràá.
17Èṣo òdodo náà yóò sì jẹ́ àlàáfíà; àbájáde òdodo yóò sì jẹ́ ìdákẹ́jẹ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé títí láé.
18Àwọn ènìyàn mi yóò máa gbé ní àlàáfíà ní ibùgbé àlàáfíà, ní àwọn ilé ààbò, ní àwọn ibi ìsinmi tí kò ti sí ìdíwọ́.
19Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé yìnyín ti tẹ́jú igbó pẹrẹṣẹ àti tí ojú ìlú ti tẹ́ pẹrẹṣẹ pátapáta,
20báwo ni ẹ ó ti jẹ́ alábùkún tó, nípa gbíngbin irúgbìn sí ipa odò gbogbo, àti nípa jíjẹ́ kí àwọn màlúù yín àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ jẹ láìsí ìdíwọ́.