Ìwé Wòlíì Àìsáyà 34:1-17 BYB2014 - Bible AI

1ⓐ Súnmọ́ tòsí, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè láti gbọ́, tẹ́tísílẹ̀ ẹyín ènìyàn jẹ́ kí ayé gbọ́, àti ẹ̀kún rẹ̀, ayé àti ohun gbogbo tí ó ti inú un rẹ̀ jáde.

2Nítorí ibínú OLÚWA ń bẹ lára gbogbo orílẹ̀-èdè, àti irunú un rẹ̀ lórí gbogbo ogun wọn: o ti fi wọ́n fún pipa,

3Àwọn ti a pa nínú un wọn ni a ó sì jù ṣóde, òórùn wọn yóò ti inú òkúu wọn jáde, àwọn òkè-ńlá yóò sì yọ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ wọn

4ⓑ Gbogbo àwọn ogun ọ̀run ni yóò di yíyọ́, a ó sì ká àwọn ọ̀run jọ bí i takàdá, gbogbo ogun wọn yóò si ṣubú lulẹ̀, bí ewé ti n bọ́ kúrò lára àjàrà, àti bí i bíbọ́ èṣo lára igi ọ̀pọ̀tọ́.

4

5Nítorí ti a rẹ idà mi ní ọ̀run, kíyèsì í, yóò ṣọ̀kalẹ̀ wá sórí Édómù, sórí àwọn ènìyàn tí mo ti parun fún ìdájọ.

6Idà OLÚWA kún fún ẹ̀jẹ̀ a mú un ṣanra fún ọ̀rá, àti fún ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́-agùtàn àti ewurẹ, fún ọ̀rá iwe àgbò— nítorí OLÚWA ni ìrúbọ kan ní Bósírà, àti ìpakúpa ńlá kan ní ilẹ̀ Édómù.

7Àti àwọn àgbáǹréré yóò ba wọn ṣọ̀kalẹ̀ wá, àti àwọn ẹgbọ̀rọ̀ màlúù pẹ̀lú àwọn akọ màlúù, ilé wọn ni a ó fi ẹ̀jẹ̀ rin, a ó si fi ọ̀rá sọ ekuru wọn di Ọlọ́ràá.

7

8Nítorí ọjọ́ ẹ̀san OLÚWA ni, àti ọdún ìsanpadà, nítorí ọ̀ràn Ṣíhónì.

9ⓒ Odò rẹ̀ ni a ó sì sọ di ọ̀dà, àti eruku rẹ̀ di imí-ọjọ́, ilẹ̀ rẹ̀ yóò sì di ọ̀dà tí ń jóná.

10A ki yóò paá ní òru tàbí ní ọ̀sán, èéfín rẹ̀ yóò gòkè láéláé: yóò dahoro láti ìran dé ìran, kò sí ẹnìkan tí yóò là á kọjá láé àti láéláé.

11Ṣùgbọ́n ẹyẹ àṣá, àti àkàlà ni yóò ni ín, àti òun yóò sì na okùn-ìwọ̀n ìparun sóríi rẹ̀, àti òkúta ohun rudurùdu sórí àwọn ọlọ́lá rẹ̀.

12Ní ti àwọn ìjòyè rẹ̀ ẹnìkan kì yóò sí níbẹ̀ ti wọn ó pè wá sí ìjọba, gbogbo àwọn olóríi rẹ̀ yóò sì di asán.

13Ẹ̀gún yóò sì hù jáde nínú àwọn ààfin rẹ̀ wọ̀nyí, ẹ̀gún ọ̀gán nínú ìlú olódi rẹ̀. Yóò jẹ́ ibùgbé àwọn akátá àti àgbàlá fún àwọn òwìwí.

14Àwọn ẹran ijù àti àwọn ọ̀wàwà ni yóò pàdé, àti sátírè kan yóò máa kọ sí èkejìí rẹ̀, iwin yóò máa gbé ibẹ̀ pẹ̀lú, yóò sì rí ibi isinmi fún ara rẹ̀.

15Òwìwí yóò tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ ṣíbẹ̀, yóò yé, yóò sì pa, yóò sì kójọ lábẹ́ òjìji rẹ̀: àwọn gúnnugún yóò péjọ ṣibẹ̀ pẹ̀lú, olúkúlùkù pẹ̀lú ẹnìkejì rẹ̀.

16Ẹ wá a nínú ìwé OLÚWA, ẹ sì kà á: Ọ̀kan nínú wọ̀nyí kì yóò yẹ̀, kò sí ọ̀kan tí yóò fẹ́ ìkejìi rẹ̀ kù: nítorí OLÚWA ti pàṣẹ ẹnu rẹ̀ ló sì fi kó wọn jọ Ẹ̀mí rẹ̀ ló sì fi tò wọ́n jọ.

17Ó ti di ìbò fún wọn, ọwọ́ rẹ̀ sì ti pín in fún wọn nípa títa okùn, wọn ó jogún rẹ̀ láéláé, láti ìran dé ìran ni wọn ó máa gbé inú un rẹ̀.

le>