Ìwé Wòlíì Àìsáyà 35:1-10 BYB2014 - Bible AI

1Aṣálẹ̀ àti ìyàngbẹ ilẹ̀ ni inú rẹ̀ yóò dùn; ihà yóò ṣe àjọyọ̀ yóò sì kún fún ìtànná. Gẹ́gẹ́ bí ewéko kúrókúsì,

2òun yóò bẹ́ná jáde; yóò yọ ayọ̀ ńlá ńlá yóò sì kígbe fún ayọ̀. Ògo Lẹ́bánónì ni a ó fi fún un, ọlá ńlá Kámẹ́lì àti Ṣárónì; wọn yóò rí ògo OLÚWA, àti ọlá ńlá Ọlọ́run wa.

2

3ⓐ Fún ọwọ́ àìlera lókun, mú orúnkún tí ń yẹ̀ lókun:

4Sọ fún àwọn oníbẹ̀rù ọkàn pé “Ẹ ṣe gírí, ẹ má bẹ̀rù; Ọlọ́run yín yóò wá, òun yóò wá pẹ̀lú ìgbẹ̀ṣan; pẹ̀lú ìgbẹ̀ṣan mímọ́ òun yóò wá láti gbà yín là.”

4

5ⓑ Nígbà náà ni a ó la ojú àwọn afọ́jú àti etí àwọn odi kì yóò dákẹ́.

6Nígbà náà ni àwọn arọ yóò máa fò bí àgbọ̀nrín, àti ahọ́n odi yóò ké fún ayọ̀. Odò yóò tú jáde nínú ihà àti àwọn odò nínú aṣálẹ̀.

7Yanrìn tí ń jóná yóò di adágún ilẹ̀ tí ń pòǹgbẹ yóò di orísun omi. Òpópó ibi tí àwọn ajáko sùn tẹ́lẹ̀rí koríko àti koríko odò àti ewéko mìíràn yóò hù níbẹ̀.

7

8Àti opópónà kan yóò wà níbẹ̀: a ó sì máa pè é ní ọ̀nà Ìwà-Mímọ́. Àwọn aláìmọ́ kì yóò tọ ọ̀nà náà; yóò sì wà fún àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà náà àwọn ìkà búburú kì yóò gba ibẹ̀ kọjá.

9Kì yóò sí kìnnìún níbẹ̀, tàbí kí ẹranko búburú kí ó dìde lóríi rẹ̀; a kì yóò rí wọn níbẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn ẹni ìràpadà nìkan ni yóò rìn níbẹ̀,

10àwọn ẹni ìràpadà OLÚWA yóò padà wá. Wọn yóò wọ Ṣíhónì wá pẹ̀lú orin; ayọ̀ ayérayé ni yóò dé wọn ní orí. Ìdùnnú àti ayọ̀ ni yóò borí i wọn, ìkorò àti ìtìjú yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ wọn.

le>