Ìwé Wòlíì Àìsáyà 4:1-6 BYB2014 - Bible AI

1Ní ọjọ́ náà, obìnrin méje yóò dì mọ́ ọkunrin kan yóò sì wí pé, “Àwa ó má a jẹ oúnjẹ ara wa a ó sì pèsè aṣọ ara wa; sáà jẹ́ kí a má a fi orúkọ rẹ̀ pè wá. Mú ẹgan wá kúrò!”

2ⓐ Ní ọjọ́ náà, ẹ̀ka OLÚWA yóò ní ẹwà àti ogo, èso ilẹ̀ náà yóò sì jẹ́ ìgbéraga àti ògo àwọn ti ó sálà ní Ísírẹ́lì.

3Àwọn tí ó ṣẹ́kù ní Síhónì, àwọn tí o kù ní Jérúsálẹ́mù, ni a ó pè ní mímọ́, orúkọ àwọn ẹni tí a kọ mọ́ àwọn alààyè ní Jérúsálẹ́mù.

4OLÚWA yóò wẹ ẹgbin àwọn obinrin Síhónì kúrò yóò sì fọ gbogbo àbàwọ́n ẹ̀jẹ̀ kúrò ní Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú ẹ̀mí ìdájọ́ àti ẹ̀mí ìná.

5Lẹ́yìn náà, OLÚWA yóò dá sorí òkè Síhónì àti sóríi gbogbo àwọn tí ó péjọ pọ̀ ṣíbẹ̀, kúrúkúrú èéfín ní ọ̀ṣán àti ìtànsán ọ̀wọ́ iná ní òru, lórí gbogbo ògo yìí ni ààbò yóò wà.

6Èyí ni yóò jẹ́ ààbò àti òjìji kúrò lọ́wọ́ ooru ọ̀sán, àti ààbò òun ibi ìsádi kúrò lọ́wọ́ ìjì àti òjò.

>