1Ṣùgbọ́n ní ìsinsìn yìí, ohun tí OLÚWA wí nìyìíẹni tí ó dá ọ, Ìwọ Jákọ́bùẹni tí ó mọ ọ́, Ìwọ Ísírẹ́lì:“Má bẹ̀rù, nítorí Èmi ti dá ọ nídè;Èmi ti pè ọ́ ní orúkọtèmi ni ìwọ ṣe.
2Nígbà tí ìwọ bá ń la omi kọjá,Èmi yóò wà pẹ̀lúu rẹ;àti nígbà tí ìwọ bá ń la odò kọjáwọn kì yóò bò ọ́ mọ́lẹ̀.Nígbà tí ìwọ bá la iná kọjá,kò ní jó ọ;ahọ́n iná kò ní jó ọ lára.
3Nítorí Èmi ni OLÚWA Ọlọ́run rẹ,Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì Olùgbàlà rẹ;Èmi fi Éjíbítì ṣe ìràpadà rẹ,Kúṣì àti Ṣébà dípò rẹ.
4Nítorí pé o ṣe iyebíye àti ọ̀wọ́n níwájú mi,àti nítorí pé mo fẹ́ràn rẹ,Èmi yóò fi ènìyàn rọ́pò fún ọ,àti ènìyàn dípò ẹ̀míì rẹ.
5Má bẹ̀rù nítorí èmi wà pẹ̀lúù rẹ;Èmi yóò mú àwọn ọmọ rẹ láti ìlà oòrùn wáèmi ó sì kó ọ jọ láti ìwọ̀ oòrùn.
6Èmi yóò sọ fún àríwá pé, ‘Fi wọ́n sílẹ̀!’àti fún gúṣù, ‘Má ṣe dá wọn dúró.’Mú àwọn ọmọkùnrin mi láti ọ̀nà jínjìn wáàti àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin mi láti ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé—
7ẹnikẹ́ni tí a ń pe orúkọ mi mọ́,tí mo dá fún ògo mi,tí mo mọ̀ àti tí mo ṣe.”
7
8Sin àwọn tí ó ní ojú ṣùgbọ́n tí wọ́n fọ́jú jáde,tí wọ́n ní etí ṣùgbọ́n tí wọn dití.
9Gbogbo orílẹ̀ èdè kóra wọn jọàwọn ènìyàn sì kóra wọn papọ̀.Ta ni nínú wọn tó sọ àṣọtẹ́lẹ̀ yìítí ó sì kéde fún wa àwọn nǹkan ti tẹ́lẹ̀?Jẹ́ kí wọ́n mú àwọn ẹlẹ́rìí wọn wọlé wáláti fi hàn pé wọ́n tọ̀nàtó bẹ́ẹ̀ tí àwọn mìíràn yóò gbọ́, tíwọn yóò sọ pé, “Òtítọ́ ni.”
10“Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,” ni OLÚWA wí,“Àti ìránṣẹ́ mi tí èmi ti yàn,tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin yóò fi mọ̀ àti tí ẹ̀yin ó fi gbà ḿi gbọ́tí yóò sì yé e yín pé èmi ni ẹni náà.Ṣáájú mi kò sí ọlọ́run tí a dá,tàbí a ó wa rí òmìíràn lẹ́yìn mi.
11Èmi, àní Èmi, Èmi ni OLÚWA,yàtọ̀ sí èmi, kò sí olùgbàlà mìíràn.
12Èmi ti fihàn, mo gbàlà mo sì ti kédeÈmi, kì í sì í ṣe àwọn àjèjì òrìṣà láàrin yín.Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,” ni OLÚWA wí,“Pé Èmi ni Ọlọ́run.
13Bẹ́ẹ̀ ni, àti láti ayérayé Èmi ni ẹni náà.Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè gbà kúrò lọ́wọ́ mi.Nígbà tí mo bá ṣe nǹkan, ta ni ó lè yí i padà?”
14Èyí ni ohun tí OLÚWA wíolùràpadà rẹ, Ẹni Mímọ́ ti Ísírẹ́lì;“Nítorí rẹ Èmi yóò ránṣẹ́ sí Bábílónìláti mú wọn sọ̀kalẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí ìsáǹsá,gbogbo ará Bábílónìnínú ọkọ̀ ojú omi nínú èyí tí wọ́n fi ń ṣe ìgbéraga.
15Èmi ni OLÚWA, Ẹni Mímọ́ rẹ,Ẹlẹ́dàá Ísírẹ́lì, ọba rẹ.”
15
16Èyí ni ohun tí OLÚWA wíẸni náà tí ó la ọ̀nà nínú òkun,ipa-ọ̀nà láàrin alagbalúgbú omi,
17ẹni tí ó wọ́ àwọn kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin jáde,àwọn jagunjagun àti ohun ìjà papọ̀,wọ́n sì ṣùn ṣíbẹ̀, láìní lè dìde mọ́,wọ́n kú pirá bí òwú fìtílà:
18“Gbàgbé àwọn ohun àtẹ̀yìnwá;má ṣe gbé nínú ohun àtijọ́.
19Wò ó, Èmi ń ṣe ohun tuntun!Nísinsìn yìí ó ti yọ ṣókè; àbí o kò rí i bí?Èmi ń ṣe ọ̀nà kan nínú aṣálẹ̀àti odò nínú ilẹ̀ ṣíṣá.
20Àwọn ẹhànnà ẹranko bọ̀wọ̀ fún mi,àwọn ajáko àti àwọn òwìwí,nítorí pé mo pèṣè omi nínú aṣálẹ̀àti odò nínú ilẹ̀ ṣíṣá,láti fi ohun-mímu fún àwọn ènìyàn mi, àyànfẹ́ mi,
21àwọn ènìyàn tí mo dá fún ara mikí wọn kí ó lè kéde ìyìn mi.
21
22“Ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀ ìwọ kò tí ì ké pè mí,Ìwọ Jákọ́bù,àárẹ̀ kò tí ì mú ọ nítoríì miÌwọ Ísírẹ́lì.
23Ìwọ kò tí ì mú àgùntàn wá fún mi fún ẹbọ ọrẹ sísan,tàbí kí o bọ̀wọ̀ fún mi pẹ̀lú ẹbọ rẹ.Èmi kò tí ì wàhálà rẹ pẹ̀lú ọrẹ oníhórótàbí kí n dààmú rẹ pẹ̀lú ìbéèrè fún tùràrí.
24Ìwọ kò tí ì ra kálámọ́ọ́sì olóòórùndídùn fún mi,tàbí kí o da ọ̀rá-ẹbọ rẹ bò mí.Ṣùgbọ́n ẹ ti wàhálà mi pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ yínẹ sì ti dààmú mi pẹ̀lú àìṣedédé yín.
24
25“Èmi, àní Èmi, Èmi ni ẹni tí ó wẹ àwọnàìṣedédé rẹ nù, nítorí èmi fún ara mi,tí n kò sì rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ mọ́.
26Bojú wo ẹ̀yìn rẹ fún mi,jẹ́ kí a jọ ṣe àríyànjiyàn ọ̀rọ̀ náà papọ̀;ro ẹjọ́ láti fihàn pé o kò lẹ́ṣẹ̀ lọ́rùn.
27Baba yín àkọ́kọ́ dẹ́ṣẹ̀;àwọn agbẹnusọ yín ṣọ̀tẹ̀ sí mi.
28Nítorí náà, èmi yóò dójú ti àwọn ẹni àyẹ́síinú tẹ́ḿpìlìi yín,bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò mú ìparun bá Jákọ́bùàti ìtìjú bá Ísírẹ́lì.