Ìwé Wòlíì Àìsáyà 46:1-13 BYB2014 - Bible AI

1Bẹ́lì tẹríi rẹ̀ ba, Nébò bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀; àwọn ère wọn ni àwọn ẹranko rù. Àwọn ère tí wọ́n ń rù káàkiri ti di àjàgà sí wọn lọ́rùn, ẹrù fún àwọn tí àárẹ̀ mú.

2Wọ́n bẹ̀rẹ̀ wọ́n sì foríbalẹ̀ papọ̀; wọn kò lè gba ẹrù náà, àwọn pẹ̀lú ni a kó lọ ní ìgbèkùn.

2

3“Tẹ́tí sími ìwọ ilé Jákọ́bù, Gbogbo ẹ̀yin tí ó ṣẹ́kù nínú ilé Ísírẹ́lì, Ìwọ tí mo ti gbérò láti ìgbà tí o ti wà nínú oyún, tí mo sì ti ń pọ̀n láti ìgbà tí a ti bí ọ.

4Pẹ̀lúpẹ̀lú sí àwọn arúgbó àti ewú oríi yín Èmi ni ẹni náà, Èmi ni ẹni tí yóò gbé ọ ró. Èmi ti mọ ọ́, èmi yóò sì gbé ọ; Èmi yóò dì ọ́ mú èmi ó sì gbà ọ́ sílẹ̀.

4

5“Ta ni ìwọ yóò fi mí wé tàbí ta ni èmi yóò bá dọ́gba? Ta ni ìwọ yóò fi ṣe àkàwé mi tí àwa yóò jọ farawéra?

6Ọ̀pọ̀ da wúrà sílẹ̀ nínú àpò wọn wọ́n sì wọn fàdákà lórí òṣùwọ̀n; wọ́n bẹ alágbẹ̀dẹ lọ́wẹ̀ láti fi wọ́n ṣe òrìṣà, wọn sì tẹríba láti sìn ín.

7Wọ́n gbé e lé èjìká wọn, wọ́n rù wọ́n, wọ́n sì gbé e sí àye rẹ̀ níbẹ̀ ni ó sì dúró sí. Láti ibẹ̀ náà kò le è paradà Bí ènìyàn tilẹ̀ pariwo lé e lórí, òun kò le è dáhùn; òun kò lè gbà á nínú ìyọnu rẹ̀.

7

8“Rántí èyí, fi í sí ọkàn rẹ, fi sí ọkàn rẹ, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀.

9Rántí àwọn nǹkan àtẹ̀yìnwá, àwọn ti àtijọ́tijọ́; Èmi ni Ọlọ́run, kò sì sí ẹlọ̀mìíràn; Èmi ni Ọlọ́run, kò sí ẹlòmìíràn bí ì mi.

10Mo fi òpin hàn láti ìbẹ̀rẹ̀ wá, láti àtètèkọ́ṣe, ohun tí ó sì ń bọ̀ wá. Mo wí pé: Ète mi yóò dúró, àti pé èmi yóò ṣe ohun tí ó wù mí.

11Láti ìlà-oòrùn wá ni mo ti pe ẹyẹ ajẹran wá; láti ọ̀nà jíjìn réré, ọkùnrin kan tí yóò mú ète mi ṣẹ. Ohun tí mo ti sọ, òun ni èmi yóò múṣẹ; èyí tí mo ti gbérò, òun ni èmi yóò ṣe.

12Tẹ́tí sí mi, ìwọ ọlọ́kàn-dídi, ìwọ tí ó jìnnà sí òdodo.

13Èmi ń mú òdodo mi bọ̀ nítòsí, kò tilẹ̀ jìnnà rárá; àti ìgbàlà mi ni a kì yóò dádúró. Èmi yóò fún Ṣíhónì ní ìgbàlà ògo mi fún Ísírẹ́lì.

le>