Ìwé Wòlíì Àìsáyà 47:1-15 BYB2014 - Bible AI

1ⓐ “Ṣọ̀kalẹ̀, jókòó nínú eruku, wúndíá ọmọbìnrin Bábílónì; jókòó ní ilẹ̀ẹ́lẹ̀ láìsí ìtẹ́, ọmọbìnrin àwọn ará Bábílónì. A kì yóò pè ọ́ ní aláìlókun àti ẹlẹgẹ́ mọ́.

2Mú òkúta-ọlọ kí o sì lọ ìyẹ̀fun; mú ìbòjú ù rẹ kúrò. Ká yẹ̀rì rẹ sókè, kí o hó ẹṣẹ̀ rẹ sílẹ̀, kí o sì la inú odò lọ.

3Ìhòòhò rẹ ni a ó fihàn síta àti ìtìjú rẹ ni a ó sí sílẹ̀. Èmi yóò sì gba ẹ̀ṣan; Èmi kì yóò sì dá ẹnìkan sí.”

3

4Olùràpadà wa OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀ òun ni Ẹni-Mímọ́ Ísírẹ́lì.

4

5“Jókòó ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́, lọ sínú òkùnkùn, ọmọbìnrin àwọn ará Bábílónì; a kì yóò pè ọ́ ní ọbabìnrin àwọn ilẹ̀-ọba mọ́.

6Inú bí mi sí àwọn ènìyàn mi tí mo sì ba ogún mi jẹ́; Mo fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́, Ìwọ kò sì síjú àánú wò wọ́n. Lórí àwọn arúgbó pẹ̀lú ní o gbé àjàgà tí ó wúwo lé.

7Ìwọ wí pé, ‘Èmi yóò tẹ̀ṣíwájú títí láé— ọba-bìnrin ayérayé!’ Ṣùgbọ́n ìwọ kò kíyèsí nǹkan wọ̀nyí tàbí kí o ronú nípa ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀.

7

8ⓑ “Nísinsìn yìí, tẹ́tísílẹ̀, ìwọ oníwọ̀ra ẹ̀dá tí o kẹ̀tẹ̀ǹfẹ̀ nínú ààbò rẹ tí o sì ń sọ fún ara rẹ pé, ‘Èmi ni, kò sì sí ẹlòmìíràn lẹ́yìn mi. Èmi kì yóò di opó tàbí kí n pàdánù àwọn ọmọ.’

9ⓒ Méjèèjì yìí ni yóò wá sóríì rẹ láìpẹ́ jọjọ, ní ọjọ́ kan náà: pípàdánù ọmọ àti dídi opó. Wọn yóò wá sóríì rẹ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ìṣe oṣó rẹ àti àwọn èpè rẹ tí kì í ṣélẹ̀.

10Ìwọ ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìwà ìkà rẹ ó sì ti wí pé, ‘kò sí ẹni tí ó rí mi?’ Ọgbọ́n àti òye rẹ ti sì ọ́ lọ́nà nígbà tí o wí fún ara rẹ pé, ‘Èmi ni, kò sí ẹlòmìíràn lẹ́yìn mi.’

11Ìparun yóò dé bá ọ bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì yóò mọ ọ̀nà láti ré e kúrò. Àjálù kan yóò ṣubú lù ọ́ tí o kì yóò le è fi ètùtù ré kúrò; òfò kan tí o kò le ròtì ni yóò wá lójijì sí oríì rẹ.

11

12“Tẹ̀ṣíwájú nígbà náà, pẹ̀lú àfọ̀ṣẹ rẹ àti pẹ̀lú ìwà oṣó rẹ gbogbo, tí o ti ń ṣiṣẹ́ fún láti ìgbà èwe rẹ wá. Bóyá o le è ṣàṣeyọrí, bóyá o le è dá rúgúdù sílẹ̀.

13Gbogbo ìmọ̀ràn tí o ti gbà ni ó ti sọ ọ́ di akúrẹtẹ̀! Jẹ́ kí àwọn awòràwọ̀ rẹ bọ́ síwájú, Àwọn awòràwọ̀ tí wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀ láti oṣù dé oṣù, jẹ́ kí wọ́n gbà ọ́ lọ́wọ́ ohun tí ó ń bọ̀ wá bá ọ.

14Lóòótọ́ wọ́n dàbí pòpó; iná ni yóò jó wọn dànù. Wọn kò kúkú lè gba ara wọn là lọ́wọ́ agbára iná náà. Kò sí èédú láti mú ara ẹnikẹ́ni gbóná níhìnín kò sí iná tí ènìyàn le jókòó tì.

15Gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe fún ọ nìyìí gbogbo èyí ní o tí síṣẹ́ pẹ̀lú u rẹ̀ tí o sì ti ń rù kiri láti ìgbà èwe. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ń lọ nínú àṣìṣe rẹ̀; kò sí ẹyọ ẹnìkan tí ó lè gbà ọ́.

le>