Ìwé Wòlíì Àìsáyà 48:1-22 BYB2014 - Bible AI

1“Tẹ́tí sí èyí, Ìwọ ilée Jákọ́bù, ìwọ tí a ń pè pẹ̀lú orúkọ Ísírẹ́lì tí o sì wá láti ẹ̀ka Júdà, ìwọ tí ò ń búra ní orúkọ OLÚWA tí o sì ń pe Ọlọ́run Ísírẹ́lì ṣùgbọ́n kì í ṣe ní òtítọ́ àti òdodo

2Ìwọ tí ò ń pe ara rẹ ní ọmọ ìlú mímọ́ n nì tí o sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run Ísírẹ́lì— OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀:

3Èmi sọ àṣọtẹ́lẹ̀ àwọn nǹkan ti tẹ́lẹ̀ lọ́jọ́ tó ti pẹ́, ẹnu mi ló ti kéde wọn, mo sì sọ wọ́n di mímọ̀; Lẹ́yìn náà lójijì mo gbé ìgbéṣẹ̀, wọ́n sì wá sí ìmúṣẹ.

4Nítorí mo mọ bí ẹ ti jẹ́ olórí kunkun tó; àwọn iṣan ọrùn un yín irin ni wọ́n; iwájúu yín idẹ ni

5Nítorí náà mo ti sọ nǹkan wọ̀nyí fún ọ ní ọjọ́ tí ó ti pẹ́; kí wọn ó tó ṣẹlẹ̀ mo ti kéde wọn fún un yín tó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ kò fi lè sọ pé, ‘Àwọn ère mi ló ṣe wọ́n; àwọn ère igi àti òrìṣà irin ló fọwọ́ sí i.’

6Ìwọ ti gbọ́ àwọn nǹkan wọ̀nyí; wo gbogbo wọn Ǹjẹ́ o kò ní gbà wọ́n bí?

6“Láti ìsinsìnyìí lọ, Èmi yóò máa sọ fún ọ nípa nǹkan tuntun, àwọn nǹkan tí ó farasin tí ìwọ kò mọ̀.

7A dá wọn ní àkókò yìí kì í ṣe láti ìgbà pípẹ́ ìwọ kò tí ì gbọ́ nípa wọn títí di òní. Nítorí náà, ìwọ kò lè sọ pé, ‘Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀ nípa wọn.’

8Ìwọ a ha ti gbọ́ tàbí ó ti yé ọ bí láti ìgbà àtijọ́ etí kò ti di yíyà. Ǹjẹ́ mo mọ̀ bí o ti jẹ́ alárékérekè tó; a ń pè ọ́ ní ọlọ̀tẹ̀ láti ìgbà ìbí rẹ.

9Nítorí orúkọ ara mi, mo dáwọ́ ìbínú mi dúró; nítorí ìyìn ara mi, mo fà á ṣẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ, kí a má ba à ké ọ kúrò.

10Wò ó, èmi ti tún ọ ṣe, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe bí i fàdákà; Èmi ti dán ọ wò nínú ìléru ìpọ́njú.

11Nítorí orúkọ mi, nítorí orúkọ mi, mo ṣe èyí Báwo ni mo ṣe lè jẹ́ kí a ba orúkọ mi jẹ́. Èmi kì yóò fi ògo mi fún ẹlòmìíràn.

12ⓐ “Tẹ́tí sí mi, Ìwọ Jákọ́bù Ísírẹ́lì ẹni tí mo pè: Èmi ni ẹni náà; Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìgbẹ̀yìn.

13Ọwọ́ mi pàápàá ni ó fi àwọn ìpìlẹ̀ ayé ṣọlẹ̀, àti ọwọ́ ọ̀tún mi ni ó tẹ àwọn ọ̀run; nígbà tí mo pè wọ́n, gbogbo wọn dìde ṣókè papọ̀.

13

14“Ẹ gbárajọ pọ̀ gbogbo yín kí ẹ sì dẹtí: Èwo nínú àwọn ère òrìṣà rẹ ló ti sọ nǹkan wọ̀nyí? Àkójọpọ̀ àwọn àyànfẹ́ OLÚWA ni yóò gbé ète yìí jáde sí Bábílónì; apá rẹ̀ ni yóò dojú kọ àwọn aráa Bábílónì.

15Èmi, àní Èmi ló ti sọ̀rọ̀; bẹ́ẹ̀ ni, mo ti pè é. Èmi yóò mú un wá, òun yóò sì ṣe àṣeyọrí nínú ìrìnàjò rẹ̀.

16“Ẹ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi kí ẹ sì dẹtí sí èyí: “Láti ìgbà ìkéde àkọ́kọ́ èmi kò sọ̀rọ̀ ní ìkọ̀kọ̀; ní àṣìkò tí ó sì ṣẹlẹ̀, Èmi wà níbẹ̀.” Àti ní àkókò yìí, OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ni ó ti rán mi, pẹ̀lú ẹ̀mii rẹ̀.

17Èyí ni ohun tí OLÚWA wí Olùdáǹdè rẹ, Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì: “Èmi ni OLÚWA Ọlọ́run rẹ, tí ó kọ́ ọ ní ohun tí ó dára fún ọ, tí ó tọ́ ọ ṣọ́nà tí ó yẹ kí o máa rìn.

18Bí ó bá ṣe pé ìwọ bá ti tẹ́tísílẹ̀ sí àṣẹ mi, àlàáfíà rẹ kì bá ti dàbí ì ti odò, àti òdodo rẹ bí ìgbì òkun.

19Àwọn ọmọ rẹ ìbá ti dàbí i yanrìn, àwọn ọmọ yín bí i horo ọkà tí a kò lè kà tán; orúkọ wọn ni a kì yóò ké kúrò tàbí kí a pa wọ́n run níwájú mi.”

19

20Fi Bábílónì sílẹ̀, sá fún àwọn ará Bábílónì, ṣe ìfilọ̀ èyí pẹ̀lú ariwo ayọ̀ kí o sì kéde rẹ̀. Rán an jáde lọ sí òpin ilẹ̀ ayé; wí pé, “OLÚWA ti dá ìránṣẹ́ rẹ̀ Jákọ́bù nídè.”

21Òrùngbẹ kò gbẹ wọ́n nígbà tí ó kó wọn kọjá nínú ihà; ó jẹ́ kí omi ó sàn fún wọn láti inú àpáta; ó fọ́ àpáta omi sì tú jáde.

21

22“Kò sí àlàáfíà,” ni OLÚWA wí, “Fún àwọn ìkà.”

le>