Ìwé Wòlíì Àìsáyà 49:1-26 BYB2014 - Bible AI

1ⓐ Tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin erékùṣù: gbọ́ èyí, ẹ̀yin orílẹ̀ èdè jínjìn-nà réré: kí a tó bí mi OLÚWA ti pè mí; láti ìgbà bíbí mi ni ó ti dá orúkọ mi.

2Ó ṣe ẹnu mi bí idà tí a pọ́n, ní abẹ́ òjìji ọwọ́ rẹ̀ ni ó ti pamí mọ́: ó ṣe mí ní ọfà tí a ti dán, ó sì fi mí pamọ́ sínú àpó rẹ̀.

3Ó sọ fún mi pé, “Ìránṣẹ́ mi ni ìwọ í ṣe, Ísírẹ́lì nínú ẹni tí n ó ti fi ògo mi hàn.”

4ⓑ Ṣùgbọ́n èmi ṣọ pé, “Mo ti ṣe wàhálà lórí asán; mo ti lo gbogbo ipá mi lórí asán àti ìmúlẹ̀ mófo. Síbẹ̀ síbẹ̀ ohun tí ó tọ́ sími sì wà lọ́wọ́ OLÚWA, èrè mi sì ń bẹ pẹ̀lú Ọlọ́run mi.”

4

5Nísinsìn yìí OLÚWA wí pé ẹni tí ó mọ̀ mí láti inú wá láti jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ láti mú Jákọ́bù padà tọ̀ mí wá àti láti kó Ísírẹ́lì jọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀, nítorí pé a bọ̀wọ̀ fún mi ní ojú OLÚWA Ọlọ́run mi sì ti jẹ́ agbára mi

6ⓒ Òun wí pé: “Ó jẹ́ ohun kékeré fún ọ láti jẹ́ ìránṣẹ́ mi láti mú ẹ̀yà Jákọ́bù padà bọ̀ sípò àti láti mú àwọn ti Ísírẹ́lì tí mo ti pamọ́. Èmi yóò sì fi ọ́ ṣe ìmọ́lẹ̀ fún àwọn aláìkọlà, kí ìwọ kí ó lè mú ìgbàlà mi wá sí òpin ilẹ̀ ayé.”

6

7Ohun tí OLÚWA wí nìyìí Olùdáǹdè àti Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì— sí ẹni náà tí a gàn tí a sì kóríra lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀ èdè, sí ìránṣẹ́ àwọn aláṣẹ: “Àwọn ọba yóò rí ọ wọn yóò sì dìde sókè, àwọn ọmọ ọba yóò ríi wọn yóò sì wólẹ̀, nítorí OLÚWA ẹni tí í ṣe olótìítọ́, Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì tí ó ti yàn ọ́.”

8ⓓ Ohun tí OLÚWA wí nìyìí: “Ní àkókò ojú rere mi, èmi yóò dá ọ lóhùn, àti ní ọjọ́ ìgbàlà, èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́; Èmi yóò pa ọ́ mọ́, n ó sì ṣe ọ́ láti jẹ́ májẹ̀mú fún àwọn ènìyàn, láti mú ilẹ̀ padà bọ̀ sípò àti láti ṣe àtúnpín ogún rẹ̀ tí ó ti dahoro,

9Láti sọ fún àwọn ìgbèkùn pé, ‘Ẹ jáde wá’ àti fún àwọn tí ó wà nínú òkùnkùn pé, ‘Ẹ gba òmìnira!’

9“Wọn yóò máa jẹ ní ẹ̀bá ọ̀nà àti koríko tútù lórí òkè aláìléwéko.

10ⓔ Ebi kì yóò pa wọ́n bẹ́ẹ̀ ni òrùngbẹ kì yóò gbẹ wọ́n, tàbí kí ooru inú aṣálẹ̀ tàbí òòrùn kí ó pa wọ́n. Ẹni tí ó ṣàánú fún wọn ni yóò máa tọ́ wọn, tí yóò sì mú wọn lọ sí ibi oríṣun omi.

11Èmi yóò sọ gbogbo àwọn oke-ńlá mi di ojú-ọ̀nà àti gbogbo òpópónà mi ni a ó gbé ṣókè.

12Kíyèsí i, wọn yóò wá láti ọ̀nà jínjìn àwọn díẹ̀ láti àríwá àti àwọn díẹ̀ láti ìwọ̀ oòrùn, àwọn díẹ̀ láti ẹkùn Áṣíwánì.”

12

13ⓕ Ẹ hó fún ayọ̀, Ẹ̀yin ọ̀run; yọ̀, ìwọ ilẹ̀-ayé; bú sórin, ẹ̀yin òkè-ńlá! Nítorí OLÚWA tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú yóò sì ṣàánú fún àwọn ẹni tí a ń pọ́n lójú.

13

14Ṣùgbọ́n Ṣíhónì sọ pé, “OLÚWA ti kọ̀ mí sílẹ̀, OLÚWA ti gbàgbé è mi.”

14

15“Ǹjẹ́ abiyamọ ha le gbàgbé ọmọ ọmú rẹ̀ kí ó má sì ṣàánú fún ọmọ rẹ̀ tí ó ti bí? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun le gbàgbé Èmi kì yóò gbàgbé rẹ!

16Kíyèsí i, mo ti kọ ọ́ sí àtẹ́lẹwọ́ mi ògiri rẹ wà níwájú mi nígbà gbogbo.

17Àwọn ọmọ rẹ ti kánjú padà, àti àwọn tí ó sọ ọ́ dahoro ti padà lẹ́yìn rẹ.

18Gbójú rẹ ṣókè kí o sì wò yíká; gbogbo àwọn ọmọkùnrin rẹ kórajọ wọ́n sì wá sọ́dọ̀ rẹ. Níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láàyè,” ni OLÚWA wí, “Ìwọ yóò wọ gbogbo wọ́n gẹ́gẹ́ bí ohun ọ̀ṣọ́; ìwọ yóò wọ̀ wọ́n gẹ́gẹ́ bí ìyàwó.

18

19“Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a tí run ọ́, a sì sọ ọ́ di ahoro tí gbogbo ilẹ̀ rẹ sì di ìgbòrò, ní ìsinsìn yìí, ìwọ yóò kéré jù fún àwọn ènìyàn rẹ, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ti ó jẹ ó rùn ni yóò wà ni ọ̀nà jínjìn réré.

20Àwọn ọmọ tí a bí ní àkókò ọ̀fọ̀ rẹ yóò sọ ní etígbọ̀ọ́ rẹ, ‘Ibi yìí ti kéré jù fún wa; ẹ fún wa láyè sí i tí a ó máa gbé.’

21Nígbà náà ni ìwọ yóò sọ ní ọkàn rẹ pé, ‘ta ló bí àwọn yìí fún mi? Mo ti ṣọ̀fọ̀ mo sì yàgàn; A sọ mi di àtìpó a sì kọ̀ mí sílẹ̀. Ta ló wo àwọn yìí dàgbà? A fi èmi nìkan sílẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí níbo ni wọ́n ti wá?’ ”

22Ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí níyìí: “Kíyèsí i, Èmi yóò késí àwọn aláìkọlà Èmi yóò gbé àṣíá mi ṣókè sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn; Wọn yóò kó àwọn ọmọkùnrin yín wá ní apá wọn wọn yóò sì gbé àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin ní èjìká wọn.

23Àwọn ọba ni yóò jẹ́ alágbàtọ́-baba fún ọ, àwọn ayaba wọn ni yóò sì jẹ́ ìyá-alágbàtọ́. Wọn yóò foríbalẹ̀ ní iwájú rẹ̀ pẹ̀lú ojú wọn dídàbolẹ̀; wọn yóò máa lá èrùpẹ̀ lẹ́bàá ẹṣẹ̀ rẹ. Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé Èmi ni OLÚWA; gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìrètí nínú mi ni a kì yóò jákulẹ̀.”

23

24Ǹjẹ́ a le gba ìkógun lọ́wọ́ jagunjagun, tàbí kí á gba ìgbèkùn lọ́wọ́ akíkanjú?

25Ṣùgbọ́n ohun tí OLÚWA wí níyìí: “Bẹ́ẹ̀ ni, a ó gba àwọn ìgbékùn lọ́wọ́ àwọn jagunjagun, àti ìkógun lọ́wọ́ àwọn akíkanjú; Ẹni tí ó bá ọ jà ni èmi ó bá jà, àti àwọn ọmọ rẹ ni èmi ó gbàlà.

26Èmi yóò mú kí àwọn aninilára rẹ̀ jẹ ẹran ara wọn; wọn yóò mu ẹ̀jẹ̀ ara wọn yó bí ẹnii mu wáìnì. Nígbà náà ni gbogbo ọmọnìyàn yóò mọ̀ pé Èmi, OLÚWA, èmi ni Olùgbàlà rẹ, Olùdáǹdè rẹ, Alágbára kanṣoṣo ti Jákọ́bù.”

le>