Ìwé Wòlíì Àìsáyà 5:1-30 BYB2014 - Bible AI

1ⓐ Èmi yóò kọrin fún ẹni tí mo fẹ́ràn orin kan nípa ọgbà-àjàrà rẹ̀; Olùfẹ́ẹ̀ mi ní ọgbà-àjàrà kan ní ẹ̀gbẹ́ òkè ẹlẹ́tù lójú.

2Ó tu ilẹ̀ rẹ̀, ó ṣa òkúta ibẹ̀ kúrò ó sì gbin àyànfẹ́ àjàrà síi. Ó kọ́ ilé-ìṣọ́ sí inú un rẹ̀ ó sì ṣe ìfúntí kan ṣíbẹ̀ pẹ̀lú. Lẹ́yìn náà, ó ń retí èso àjàrà dáradára, ṣùgbọn èṣo búburú ni ó ti ibẹ̀ wá.

2

3“Ní ìsinsin yìí ẹ̀yín olùgbé Jérúsálẹ́mù àti ẹ̀yin ènìyàn Júdà ẹ ṣe ìdájọ́ láàrin èmi àti ọgbà àjàrà mi.

4Kín ni ó kù tí n ò bá tún ṣe sí ọgbà àjàrà mi. Ju èyí tí mo ti ṣe lọ? Nígbà tí mo ń wá èso dáradára, èéṣe tí ó fi ṣo kíkan?

5Ní ìsinsìn yìí, èmi yóò sọ fún ọ ohun tí n ó ṣe sí ọgbà-àjàrà mi: Èmi yóò gé igi inú un rẹ̀ kúrò, a ó sì pa á run, Èmi yóò wó ògiri rẹ̀ lulẹ̀ yóò sì di ìtẹ̀mọ́lẹ̀.

6Èmi yóò sì sọ ọ́ di ahoro láì kọ ọ́ láì rò ó, ẹ̀wọ̀n àti ẹ̀gún ni yóò hù níbẹ̀. Èmi yóò sì pàṣẹ fún kùrukùru láti má ṣe rọ̀jò sóríi rẹ̀.”

6

7Ọgbà-àjàrà OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ni ilé Ísírẹ́lì àwọn ọkùnrin Júdà sì ni àyànfẹ́ ọgbà rẹ̀. Ó retí ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ṣùgbọn, ìtàjẹ̀sílẹ̀ ni ó rí, Òun ń retí òdodo ṣùgbọ́n ó gbọ ẹkún ìpayínkeke.

8Ègbé ni fún àwọn tí ń kọ́lé mọ́lé tí ó sì ń ra ilẹ̀ mọ́lẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ààyè kò ṣẹ́kù tí ó sì nìkan gbé lórí ilẹ̀.

9OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ti sọ ọ́ sími létí “Ó dájú pé àwọn ilé ńlá ńlá yóò di ahoro, àwọn ilé dára dára yóò wà láìní olùgbé.

10Ọgbà-àjàrà sarè oko mẹwàá yóò mú ìkòkò wáìnì kan wá, nígbà tí òṣùwọ̀n hómérì kan yóò mú agbọ̀n irúgbin kan wá.”

10

11Ègbé ni fún àwọn tí wọ́n dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ láti lépa ọtí líle, tí wọ́n sì mu ún títí alẹ́ fi lẹ́ títí wọ́n fi gbinájẹ pẹ̀lú wáìnì.

12Wọ́n ní hápù àti láà níbi àṣè wọn, tamborínìn òun fèrè àti wáìnì, ṣùgbọ́n wọn kò ka iṣẹ́ OLÚWA sí, kò sí ìbọ̀wọ̀ fún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.

13Nítorí náà àwọn ènìyàn mi yóò lọ sí ìgbèkùn nítorí òye kò sí fún wọn, ebi ni yóò pa àwọn bọ̀rọ̀kìnní wọn kú; ẹgbàágbèje wọn ni òrùgbẹ yóò sì gbẹ.

14Nítorí náà isà òkú ti ń dátọ́mì gidigidi, ó sì ti ya ẹnu rẹ̀ sílẹ̀ gbagada, nínú rẹ̀ ni àwọn gbajúmọ̀ àti mẹ̀kúnnù yóò sọ̀kalẹ̀ sí pẹ̀lú ọlá àti ògo wọn.

15Báyìí, ènìyàn yóò di ìrẹ̀sílẹ̀ àti ọmọnìyàn ni a sọ di onírẹ̀lẹ̀ ojú agbéraga ni a sì rẹ̀ sílẹ̀.

16Ṣùgbọ́n OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ni a ó gbéga nípa ẹ̀tọ́ rẹ̀, Ọlọ́run ẹni mímọ́ yóò sì fi ara rẹ̀ hàn ní mímọ́ nípa òdodo rẹ̀.

17Nígbà náà ni àwọn àgùntàn yóò máa jẹ́ ko ní ibùgbé e wọn, àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn yóò máa jẹ nínú ahoro àwọn ọlọ́rọ̀.

17

18Ègbé ni fún àwọn tí ń fi okùn, àti àwọn tí o dàbí ẹni pé wọ́n ń fí okùn kẹ́kẹ́ ẹ̀sìn fa ìkà,

19sí àwọn tí ó sọ pé, “Jẹ́ kí Ọlọ́run ṣe kíákíá, jẹ́ kí ó yára ṣiṣẹ́ rẹ̀ kí a lè ríi, jẹ́ kí ó súnmọ́ bí jẹ́ kí ètò ẹni mímọ́ Ísírẹ́lì kí ó dé, kí àwa kí ó le mọ̀ ọ́n.”

19

20Ègbé ni fún àwọn tí ń pe ibi ní rere, àti rere ní ibi, tí ń fi òkùnkùn ṣe ìmọ́lẹ̀ àti ìmọ́lẹ̀ ṣe òkunkun, tí ń fi ìkorò ṣe adùn àti adùn ṣe ìkorò.

20

21Ègbé ni fún àwọn tí ó gbọ́n lójú ara wọn tí wọ́n já fáfá lójú ara wọn.

21

22Ègbé ni fún àwọn akọni nínú wáìnì mímu àti àwọn akíkanjú nínú àdàlú ọtí,

23tí wọ́n dá ẹlẹ́bi sílẹ̀ nítorí àbẹ̀tẹ́lẹ̀, tí wọn sì du aláre ní ẹ̀tọ́.

24Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí ahọ́n iná ṣe ń jó àkékù koríko run àti bí koríko ṣe relẹ̀ wẹ̀sì nínú iná, bẹ́ẹ̀ ni egbò wọn yóò jẹrà tí òdodo wọn yóò sì fẹ́ lọ bí eruku: nítorí pé wọ́n ti kọ òfin OLÚWA àwọn ọmọ-ogun sílẹ̀ wọ́n sì gan ọ̀rọ̀ Ẹni mímọ́ Ísírẹ́lì.

25Nítorí náà, ìbínú OLÚWA gbóná mọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀, ó ti gbé ọwọ́ rẹ̀ ṣókè, ó sì lù wọ́n bolẹ̀. Àwọn òkè mì tìtì, àwọn òkú sì dàbí ààtàn lójú òpópó ọ̀nà. Pẹ̀lúu gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò tíí kúrò, ọ̀wọ́ rẹ̀ sì gbé ṣókè síbẹ̀.

25

26Ó gbé ọ̀págun ṣókè sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ó jìnnà-réré, Ó súfèé sí àwọn tí ó wà ní ìpẹ̀kun ilẹ̀. Àwọn rè é, wọ́n ti sáré

27Kò rẹ ẹnìkankan nínú wọn, tàbí kí ó kọṣẹ̀. Ẹnikẹ́ni ò tòògbé tàbí sùn; Ìgbànú ẹnìkankan ò dẹ̀ ní ìbàdí i rẹ̀, okùn sálúbàtà kan ò já.

28Àwọn ọfà wọn múná, gbogbo ọrun wọn sì lò; pátakò àwọn ẹṣin wọn le bí òkúta-akọ àwọn àgbá kẹ̀kẹ̀ wọn sì dàbí ìjì líle.

29Bíbú wọn dàbí tí kìnnìhún, wọ́n bú bí ẹgbọ̀rọ̀ kìnnìhún, wọ́n ń kọ bí wọ́n ti di ẹranànjẹ wọn mú tí wọn sì gbé e lọ láìsí ẹni tí yóò gbà á là.

30Ní ọjọ́ náà, wọn yóò hó lé e lórí gẹ́gẹ́ bí i rírú omi òkun. Bí ènìyàn bá sì wo ilẹ̀, yóò rí òkùnkùn àti ìbànújẹ́; pẹ̀lúpẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ yóò di òkùnkùn pẹ̀lú kùrukùru rẹ̀.

e>