Ìwé Wòlíì Àìsáyà 50:1-11 BYB2014 - Bible AI

1Ohun tí OLÚWA wí níyìí: “Níbo ni ìwé-ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀ ìyá rẹ wà èyí tí mo fi lé e lọ? Tàbí èwo nínú àwọn olùyánilówó mi ni mo tà ọ́ fún? Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ni a fi tà ọ́; nítorí àìṣedéédéé rẹ ni a fi lé ìyá rẹ lọ.

2Nígbà tí mo wá, èéṣe tí a kò fi rí ẹnìkan? Nígbà tí mo pè, èéṣe tí kò fi sí ẹnìkan láti dáhùn? Ọwọ́ mi a kúrú láti gbà ọ́? Èmi kò ha ní agbára láti gbà ọ́ bí? Nípa ìbáwí lásán, Èmi gbẹ omi òkun, Èmi yí àwọn odò sí aṣálẹ̀; àwọn ẹja wọn rà fún àìsí omi wọ́n sì kú fún òùngbẹ.

3Èmi fi òkùnkùn bo sánmọ̀ mo sì fi aṣọ-ọ̀fọ̀ ṣe ìbòrí rẹ̀.”

3

4OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ti fún mi ni ahọ́n tí a fi iṣẹ́ rán, láti mọ àwọn ọ̀rọ̀ tí ó lè gbé àwọn aláàárẹ̀ ró. O jí mi láràárọ̀, o jí etí mi láti gbọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí à ń kọ́.

5OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ti sí mi ní etí, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ṣọ̀tẹ̀ rí; Èmi kò sì padà ṣẹ́yìn.

6Mo sí ẹ̀yìn mi sílẹ̀ fún àwọn tí ó ń nà mí, àti ẹ̀rẹ̀kẹ́ mi fún àwọn tí ń fa irúngbọ̀n mi; Èmi kò fi ojú mi pamọ́ kúrò lọ́wọ́ ẹlẹ́yà àti ìyọsùtì sí.

7Nítorí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ràn mí lọ́wọ́; A kì yóò dójú tìmí. Nítorí náà ni mo ṣe gbé ojú mi ró bí Òkúta akọ èmi sì mọ pé, ojú kò ní tì mí.

8Ẹni tí ó dámiláre wà nítòsí. Ta ni ẹni náà tí yóò fẹ̀ṣùn kàn mí? Jẹ́ kí a kojú ara wa! Ta ni olùfisùn mi? Jẹ́ kí ó kòmí lójú!

9OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ni ó ń ràn mí lọ́wọ́. Ta ni ẹni náà tí yóò dámí lẹ́bi? Gbogbo wọn yóò gbó bí aṣọ; kòkòrò ni yóò sì mú wọn jẹ.

9

10Ta ni nínú yín tí ó bẹ̀rù OLÚWA tí ó sì ń gbọ́ràn sí ìràńṣẹ́ rẹ̀ lẹ́nu? Jẹ́ kí ẹni tí ń rìn ní òkùnkùn tí kò ní ìmọ́lẹ̀, kí ó gbẹ́kẹ̀lé orúkọ OLÚWA kí o sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run rẹ̀.

11Ṣùgbọ́n ní àkókò yìí, gbogbo ẹ̀yin ti ń tanná tí ẹ sì ń pèṣè iná ìléwọ́ fún ara yín, ẹ lọ, kí ẹ sì máa rìn nínú ìmọ́lẹ̀ iná yín àti ti ìtùfú tí ẹ ti kánná lù. Ohun tí ẹ ó gbà lọ́wọ́ mi nìyìí: Ẹ̀yin ó dùbúlẹ̀ nínú ìpọ́njú.

le>