Ìwé Wòlíì Àìsáyà 52:1-15 BYB2014 - Bible AI

1ⓐ Jí, jí, Ìwọ Ṣíhónì, wọ ara rẹ ní agbára. Gbé aṣọ ògo rẹ wọ̀, Ìwọ Jérúsálẹ́mù, ìlú mímọ́ n nì. Àwọn aláìkọlà àti aláìmọ́ kì yóò wọ inú un rẹ mọ́.

2Gbọn eruku rẹ kúrò; dìde ṣókè, kí o sì gúnwà, Ìwọ Jérúsálẹ́mù. Bọ́ ẹ̀wọ̀n tí ń bẹ lọ́rùn rẹ kúrò, Ìwọ ọ̀dọ́mọbìnrin ìgbékùn Ṣíhónì.

3Nítorí èyí ni ohun tí OLÚWA wí; “Ọ̀fẹ́ ni a tà ọ́, láìsanwó ni a ó sì rà ọ́ padà.”

4Nítorí èyí ni ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí. “Ní ìgbà àkọ́kọ́ àwọn ènìyàn mi ṣọ̀kalẹ̀ lọ sí Éjíbítì láti gbé; láìpẹ́ ni Áṣíríà pọ́n wọn lójú.

5ⓑ “Àti ní àkókò yìí, kí ni mo ní níbí?” ni OLÚWA wí. “Nítorí a ti kó àwọn ènìyàn mi lọ lọ́fẹ̀ẹ́, àwọn tí ó sì ń jọba lé wọn fi wọ́n ṣẹlẹ́yà,” ni OLÚWA wí. “Àti ní ọjọọjọ́ orúkọ mi ni a ṣọ̀rọ̀ òdì sí nígbà gbogbo.

6Nítorí náà àwọn ènìyàn mi yóò mọ orúkọ mi; nítorí ní ọjọ́ náà, wọn yóò mọ̀ pé Èmi ni ó ti sọ àṣọtẹ́lẹ̀ rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni, Èmi ni.”

6

7ⓒ Báwo ni ó ṣe dára tó lórí òkè ẹṣẹ̀ àwọn tí ó mú ìyìn rere ayọ̀ wá, tí wọ́n kéde àlàáfíà, tí ó mú ìyìn rere wá, tí ó kéde ìgbàlà, tí ó sọ fún Ṣíhónì pé, “Ọlọ́run rẹ ń jọba!”

8Tẹ́tísílẹ̀! Àwọn olùṣọ́ rẹ gbé ohùn wọn ṣókè wọ́n kígbe papọ̀ fún ayọ̀. Nígbà tí OLÚWA padà sí Ṣíhónì, wọn yóò rí i pẹ̀lú ojúu wọn.

9Ẹ bú sí orin ayọ̀ papọ̀, ẹ̀yin ahoro Jérúsálẹ́mù, nítorí OLÚWA ti tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú, ó sì ti ra Jérúsálẹ́mù padà.

10ⓓ  OLÚWA yóò sí apá mímọ́ rẹ̀ sílẹ̀ ní ojú gbogbo orílẹ̀ èdè, àti gbogbo òpin ilẹ̀ ayé yóò rí ìgbàlà Ọlọ́run wa.

10

11ⓔ Ẹ túká, ẹ túká, ẹ jáde kúrò níhìnínyìí! Ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́ kan! Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀ kí ẹ sì di mímọ́, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ohun èlò OLÚWA.

12Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kì yóò yára kúrò tàbí kí ẹ ṣáré lọ; nítorí OLÚWA ni yóò ṣíwájúu yín lọ, Ọlọ́run Ísírẹ́lì ni yóò sì ṣe ààbò lẹ́yìn ín yín.

13Kíyèsí i, ìránṣẹ́ mi yóò hùwà ọlọgbọ́n; òun ni a ó gbé ṣókè tí a ó sì gbéga a ó sì gbé e lékè gidigidi.

14Gẹ́gẹ́ bí a ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí wọ́n ń bọlá fún un— ìwò ojú rẹ ni a ti bà jẹ́ kọjá ti ẹnìkẹ́ni àti ìrísí rẹ̀ ní a ti bàjẹ́ kọjá ohun tí ènìyàn ń fẹ́

15ⓕ bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe bomirin àwọn orílẹ̀ èdè ká, àwọn ọba yóò sì pa ẹnu wọn mọ́ nítoríi rẹ̀. Nítorí ohun tí a kò sọ fún wọn, wọn yóò rí i, àti ohun tí wọn kò tí ì gbọ́, ni yóò sì yé wọn.

le>