1Ohun tí OLÚWA wí nìyìí: “Ẹ pa ìdájọ́ mọ́ ẹ sì ṣe ohun tí ó tọ̀nà, nítorí ìgbàlà mi súnmọ́ tòsí àti òdodo mi ni a ó fi hàn láìpẹ́ jọjọ.
2Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó ṣe èyí, ọkùnrin náà tí ó dì í mú ṣinṣin, tí ó pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ láì bàá jẹ́, tí ó sì pa ọwọ́ rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi ṣíṣe.”
4Nítorí pé ohun tí OLÚWA wí nìyìí: “Sí àwọn ìwẹ̀fà yìí tí ó pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́, tí wọ́n yan ohun tí ó dùn mọ́ mi tí wọ́n sì di májẹ̀mú mi mú ṣinṣin
5fún wọn ni Èmi yóò fún nínú tẹ́ḿpìlì àti àgbàlá rẹ̀ ìrántí kan àti orúkọ kan tí ó sànju àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin Èmi yóò fún wọn ní orúkọ ayérayé tí a kì yóò ké kúrò.
6Àti àwọn àjèjì tí ó ṣo ara wọn mọ́ OLÚWA láti sìn ín, láti fẹ́ orúkọ OLÚWA àti láti foríbalẹ̀ fún un gbogbo àwọn tí ń pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ láì bà á jẹ́ àti tí wọ́n sì di májẹ̀mú mi mú ṣinṣin—
7ⓐ àwọn wọ̀nyí ni èmi yóò mú wá òkè mímọ́ mi èmi ó sì fún wọn ní ayọ̀ nínú ilé àdúrà mi. Ọrẹ síṣun àti ẹbọ wọn ni a ó tẹ́wọ́gbà lóríi pẹpẹ mi; nítorí a ó máa pe ilé mi ní ilé àdúrà fún gbogbo orílẹ̀ èdè.”
8OLÚWA àwọn ọmọ-ogun sọ wí pé— ẹni tí ó kó àwọn àtìpó Ísírẹ́lì jọ: “Èmi yóò kó àwọn mìíràn jọ pẹ̀lúu wọn yàtọ̀ sí àwọn tí a ti kó jọ.”
9Ẹ wá, gbogbo ẹ̀yin ẹranko inú un pápá, ẹ wá jẹ àwọn ẹranko inú igbó run!
10Àwọn olùṣọ́ Ísírẹ́lì fọ́jú, gbogbo wọn ṣe aláìní ìmọ̀; Gbogbo wọn jẹ́ adití ajá, wọn kò lè gbó; wọ́n sùn sílẹ̀ wọ́n ń lálàá, wọ́n fẹ́ràn láti máa sùn.
11Wọ́n jẹ́ àwọn ajá tí ó kúndùn púpọ̀; wọn kì í ní ànító. Wọ́n jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn tí kò ní òye; olúkúlùkù ń yà sọ́nà ara rẹ̀, ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn sì wá ère tirẹ̀.
12“Wá,” ni igbe ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn, “fún mi ní ọtí wáìnì! Jẹ́ kí a mu ọtí bíà wa lámu yó ọ̀la yóò sì dàbí òní, tàbí kí ó dára jù bẹ́ẹ̀ lọ.”